Mo bèrè lọ́jọ́ Debate pé níbo ni Helicopter wà, ọ̀rọ̀ tí Oyetola sọ, mo wá fẹ́ fún un lèsì báyìí - Ademola Adeleke

Àkọlé fídíò, Osun Election 2022: Tí mo bá dákẹ́ tí ìyà ń j àwọn èèyàn mi, ẹ̀ṣẹ̀ nìyẹn lọ́dọ̀ Ọlọ́hun

Oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Sẹnetọ Ademola Adeleke ba BBC Yoruba sọrọ lati fesi lori awọn ọrọ ti gomina to wa lori oye lọwọlọwọ bayii, gomina Gboyega Oyetola sọ pe oun n ṣe nibi ipade itakurọsọ eyi ti BBC Yoruba gbekalẹ laarin awọn oludije ni ọsẹ diẹ sẹyin.

"Oyetola to sọ pe oun n san owo oṣu, o pa awọn gbese ti wọn jẹ tẹlẹ ti, igbega lẹnu iṣẹ to ni oun fun awọn oṣiṣẹ, o kan gbe iwe le wọn lọwọ lasan ni, wọn o tii gba igbega".

Oyetola ati Adeleke

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Adeleke ni oun loun wọle idibo ọdun 2018 ti ile ẹjọ si sọ bẹẹ amọ awọn fi gbogbo rẹ silẹ fun Ọlọrun.

"Mi o wa le ri awọn eeyan mi ki wọn maa jiya ki n si tun dakẹ". Ademola ni boun ṣe sọ lọjọ ipade itakurọsọ, oun tun n tun un sọ pe "ẹyin eeyan mi, ẹ ku irọju o".