Ẹ ṣe àyẹ̀wò Lasun Yusuf dáadáa, ó ṣeéṣe kó jẹ́ òun ló sèkọlù sí ilé ara rẹ̀ – Oyetola

Aworan Gomina Oyetola ati Lasun Yussuf

Oríṣun àwòrán, Google

Ijọba ipinlẹ Osun ti fesi si ẹsun ti oludije lẹgbẹ oṣelu Labour Party fi kan wọn lori iṣẹlẹ ikọlu si ile rẹ.

Lasun to jẹ igbakeji Abẹnugan Ile Aṣofin Apapọ tẹlẹ, ni awọn agbebọn ṣekọlu si ile rẹ ni oru ọganjọ Ọjọ Aje.

Ninu ọrọ rẹ, Lasun ni pe awọn to fẹ pa oun ni wọn ṣe ikọlu si ile oun.

Bakan naa lo fikun un pe ijọba gomina Oyetola ti ẹgbẹ oṣelu APC lo n dunkoko mọ oun nitori wọn mọ pe wọn ko ni nkan rere lati ṣe fun ilu, ti wọn si ri oun gẹgẹ bi ẹni to kunjuwọn lati ṣe ijọba ni wọn ṣe ṣekọlu si oun.

Ile Họnọrebu Lasun Yusuf

Amọ Akọwe eto iroyin fun gomina Adegboyega Oyetola, Ismail Omipidan lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ko si otitọ kankan ninu ẹsun ti wọn fi kan awọn.

O ni Lasun kan n wa nkan ti ko si nitori ọrọ oṣelu ko niiṣe pẹlu eto aabo rẹ

Nibo ni awọn ẹṣọ agbofinro Lasun wa lasiko ikọlu naa?

Bio tilẹ jẹpe oludije lẹgbẹ oṣelu Labour party naa ni awọn ẹṣọ alaabo oun lo koju awọn agbebọn naa ti wọn ko fi raye wọ ile oun.

Amọ Omipidan ni ko ṣeeṣe ki wọn de ile rẹ nitori awọn ẹṣọ alaabo rẹ pọ biba ju ki ikọlu waye ni ile rẹ.

Bakan naa lo fikun un pe o ṣeeṣe ko je Lasun fun ara re lo gbe iroyin ebu naa jade ki awọn eniyan le kọbi ara si ṣaaju idibo.

O ni ẹgbẹ oṣelu PDP to ti n dunkoko mọ awọn ti pẹ, awọn ko ṣekọlu si wọn nitori naa awọn ko le ṣekọlu si ẹgbẹ oṣelu Labour ti ko tilẹ le figa gbaga pẹlu awọn.

Bakan naa ni ijọba Oyetola sapejuwe ipinlẹ Osun gẹgẹ bi ibi ti alaafia ti n jọba, nitori naa wọn rọ awọn eniyan lati gba alaafia laaye.

Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Keje,ọdun 2022 ni idibo sipo gomina naa yoo waye nipinlẹ Osun.

Wo àwòrán àti àlàyé bí àwọn agbébọn ṣe yabo ilé Họ́nọ́rébù Lasun Yusuf l’Osun

Iroyin to n tẹ wa lọwọ lọwọ ni pe awọn agbebọn yabo ile oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu Labour Party ni ipinlẹ Osun, Họnọrebu Lasun Yusuf.

Akọroyin wa ti wa ni ile oludije naa lati jabọ iroyin bi nkan ṣe ri.

Awọn ara adugbo ti wọn jọ n gbe ibi kan naa ṣalaye pe loru ọganjọ ni awọn n gbọ iro ibọn ni nkan bii ago kan oru kọja.

Ile Họnọrebu Lasun Yusuf
Ile Họnọrebu Lasun Yusuf

Ọgbẹni Lasun Yusuf funrarẹ fi sita loju opo Twitter rẹ lasiko ti ikọlu naa n waye.

Akọroyin wa jabọ pe ni agbegbe Ima ni ilu Ilobu ti ile Họnọrebu Lasun Yusuf wa ni o ti ṣẹlẹ.

A ri ọpọlọpọ oju ibọn lara ogiri ile naa bẹẹ si ni a rii ti wọn ti yinbọn fọ ferese ọkan lara awọn yara naa.

Bakan naa awọn ara adugbo atawọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu rẹ ti kun inu ile rẹ lati bẹẹ wo.

Ile Họnọrebu Lasun Yusuf
Twitter Lasun Yusuf

Oríṣun àwòrán, Lasun Yusuf

Mo n mura lati lọ kirun loru ni mo bẹrẹ si ni gburo ibọn - Lasun Yusuf

Ile Họnọrebu Lasun Yusuf

"Nigba ti a duro fun bii iṣẹju mẹwa ti iro ibọn naa ko dakẹ ni mo ni ki gbogbo awọn to wa ninu ile dọbalẹ".

Họnọrebu Lasun Yusuf ṣalaye fun BBC Yoruba pe nigba ti awọn jade sita laarọ ti ilẹ mọ lawọn ri aduru ọsẹ ti awọn agbebọn naa wa ṣe si ile rẹ.

"Koda titi ti ilẹ fi mọ, ko sẹni to fi oju ba orun mọ".ẹwẹ, oludije ẹgbẹ oṣelu Labour Party fi awọn ẹsun kọọkan kan to si ni pe awọn ọlọpaa ni lara awọn ẹri ọhun dani amọ BBC Yoruba ko le fidi rẹ mulẹ.