Àwọn agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ọtí, èèyàn márùndínlógún jáde láyé
South Africa: Àwọn agbébọn yìnbọn pa èèyàn 15 nílé ọtí Soweto

Oríṣun àwòrán, AFP VIA GETTY IMAGES
O to eeyan mẹdogun to ṣagbako iku òjijì lẹyin tí wọn yin wọn ni ibọn nile ọtí kan ní Soweto, lorilẹ-ede South Africa.
Ileeṣẹ Ọlọpaa ni awọn agbebọn lo wa nidi ikọlu naa lẹyin tí wọn ya wọ ila oorun Orlando ni idaji ọjọ Aiku ti wọn si doju ìbọn ko awọn ọdọ.
Lẹyin ikọlu naa ni awọn agbebon naa salẹ, ti ileeṣẹ ọlọpaa ko si le sọ idi ti ikọlu naa fi waye.
Akoroyin BBC, Nomsa Maseko fi idi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan lo wa ni ẹsẹ kan aiye ẹsẹ kan ọrun ni ile iwosan.
Ọpọ awọn to farapa ni ọjọ ori wọn jẹlati ọmọ ọdun mokandilogun si ọmọ ọdun marundilogoji.
“A n tẹ awọn oku mọlẹ lati ṣawari awọn mọlẹboi wa”
Ntombikayise Meji, olugbe agbegbe naa ṣalaye pe ṣe ni awọn n gun ori awọn oku naa lasiko ti wọn n wa awọn mọlẹbi awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ.
"Awọn oku wa lori ara wọn pẹlu ọpọlọpọ ẹjẹ ni ayika nígbà tí a ń wa awọn molebi wa."
"Ani lati gun àwọn oku naa lati ṣawari awọn molebi wa."
Ọga ilesse olopaa, Lt-Gen Elias Mawela, sọ fun BBC pe ikọlu naa ni o jẹ ikọlu si àwọn alaiṣẹ.
Ó ni iwadi ti bẹrẹ lati fi òfin mu awọn agbebọn to wa nidi ikọlu ọhun.
Thaban Moloi, ọkan lara awọn olugbe Soweto bu ẹnu atẹ lu bi ileeṣẹ ọlọpaa ṣe kọ lati tete de ibi ikọlu ọhun nigba to waye.
O ni "O buru gan ó, awọn eniyan ko mọ ohun tí wọn fẹ ṣe. Àgbàlagbà ati Ọmọdé ni wọn n da omije loju.












