"Ẹ jẹ́ ká pa ẹgbẹ́ ọ̀tún tì ká pa tí òsì tì ká gbájúmọ̀ Accord! Ìdì tí wọ́n fi ń jà láti fẹ̀yìn mi janlẹ̀ rèé" - Akin Ogunbiyi
"Ẹ jẹ́ ká pa ẹgbẹ́ ọ̀tún tì ká pa tí òsì tì ká gbájúmọ̀ Accord! Ìdì tí wọ́n fi ń jà láti fẹ̀yìn mi janlẹ̀ rèé" - Akin Ogunbiyi
Osun election 2020: Ètò ẹ̀yàwó náà làwọn tó wà n'íjọba tún ní fún yín tí wọ́n bá wọlé lẹ́ẹ

Ọmọwe Akinade Ogunbiyi to jẹ oludije fun ipo gomina labẹ Asia ẹgbẹ oṣelu Accord Party nipinlẹ Osun ṣalaye idi to ṣe ti inu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party bọ si Accord lati dije du ipo gomina.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba, Akin Ogunbiyi ṣapejuwe ẹgbẹ oṣelu to wa nisisiyi gẹgẹ bi eyi to dara lodi si ibi to ti n bọ.
Bakan naa o sọ idi to fi fẹ di gomina ipinlẹ Osun.
Ogunbiyi ni ipinlẹ Osun wa lara awọn to rẹyin ju ninu ọrọ aje.
O ni ko si nkankan ti awọn to wa lori alefa lọwọlọwọ naani ju ki wọn maa ya owo lọ.
Ṣugbọn o ni ti wọn ba n wa ẹni to ni ọpọlọ to ni iriri ati imọ ijinlẹ lati tukọ ipinlẹ Oṣun, ohun ni.






