Iná sọ nílé Akin Ogunbiyi tó ń díje du ípò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Osun, ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò

Oríṣun àwòrán, Akin Ogunbiyi Communication team
Ina ti jo ile oludije sipo gomina nipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, Akin Ogunbiyi.
Iroyin ni aarọ kutu ọjọ Isinimi ni ina ọhun dede ṣẹyọ, to si ba ile naa atawọn dukia mii to wa ninu ọhun jẹ ni Ileogbo, to wa ni ijọba ibilẹ Ayedire.
Ile ọhun, to dojukọ ọọfisi ijọba ibilẹ Ayedire ni Ogunbi sọ pe oun ko mọ ohun to ṣokunfa bi ina ṣe sọ nibẹ.
Ko si ẹni to mọ bi ina ṣe ṣẹyọ
Nigba ti BBC Yoruba kan si Ogunbiyi, agbẹnusọ rẹ, Steven Owolabi ṣalayae pe ile ijọsin ni oludije naa wa ki wọn to ke si pe ina ti sọ ninu ile rẹ.
O ni “Lootọ ni ina jo ile naa, amọ a ti yanju gbogbo rẹ.”
“A ko mọ ohun to ṣokunfa ina naa titi di asiko yii, bẹẹ ina ọhun kii ṣe ina kekere.”
“Inu yara rẹ ni ina naa ti bẹrẹ, gbogbo yara naa lo jona, bẹẹ naa ni awọn iwe kan to ṣe pataki ba ina ọhun lọ.”
Owolabi ṣalaye siwaju si pe “Ọna ile ijọsin ló wa ki wọn to ke si pe ile rẹ ti n jona, adupẹ lọwọ Ọlọrun pe kii ṣe oru ọganjọ ni ina ọhun ṣẹyọ, ohun ti a n sọ bayii kọ ni a ba maa sọ... nitori ko si nnkankan to ṣeku ninu yara yẹn.”
O pari ọrọ rẹ pe ko si ẹnikẹni to farapa ninu ijamba ina ọhun.












