Oyo park: Auxiliary gba ìwé ìyànsípò tuntun gẹ́gẹ́ bí ìjọba ìbílẹ̀ ṣe gba ìṣàkóso àwọn ibùdókọ̀ nípinlẹ̀ Oyo

Awọn alakoso ibudokọ ipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, Oyo Park Management

Nibi ayẹyẹ ranpẹ kan ni Kọmisana fun eto ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Arakunrin Bayo Lawal ti ṣe amojuto bi awọn alaga ijọba ibilẹ ṣe fi iwe igbanisiṣẹ le awọn alakoso ibudokọ naa lọwọ.

Alaga igbimọ to n ri si iṣakoso ibudoko, Arakunrin Mukaila Lamidi, ti ọpọlọpọ eeyan mọ si "Auxiliary" lo lewaju awọn alakoso naa lati lọ tẹwọgba iwe igbanisiṣẹ lọwọ awọn adari tuntun.

Saaju ni adajọ M. A. Adegbola ṣe alaye ọrọ ninu idajọ to ṣe ni ọsẹ to kọja wipe ojuṣe ijọba ibilẹ ni iṣakoso awọn ibudokọ ni ibamu pẹlu iṣọri keje ofin ilẹ wa ti ọdun 1999.

Bakan naa, lopin ọsẹ ti o kọja ni Gomina Ṣeyi Makinde fi ọrọ lede wi pe oun fi ara mọ idajọ naa, gẹgẹ bi o ṣe n fi iṣakoso awọn ibudokọ ṣọwọ si ijọba ibilẹ.

Ninu ọrọ ti o sọ lorukọ awọn alaga ijọba ibilẹ nibi eto naa, adele alaga ijọba ibilẹ Iwọ-oorun gusu Ibadan, Arakunrin Kehinde Akande ṣe alaye wi pe ijọba ibilẹ kọọkan lo ti ba awọn alakoso ibudokọ naa lọrọ.

O tẹsiwaju pe ijọba ibilẹ ti fun awọn oṣiṣẹ naa ni aṣẹ lati maa ṣakoso awọn ibudokọ.

Akande ni tẹlẹri ni awọn oṣiṣẹ naa ti fi aye gba alafia gẹgẹ bi o ṣe n rọ wọn lati tẹsiwaju ninu iṣẹ rere.

Ninu ọrọ tiẹ, alaga igbimọ to ṣakoso ibudokọ, Arakunrin Mukaila Lamidi fi idi ọrọ mulẹ wipe awọn oṣiṣẹ naa ti gba iwe igbanisiṣẹ ni ibamu pẹlu iyansipo wọn lati ọwọ ijọba ibilẹ.

O ni awọn iwe ti ijọba ipinlẹ fi gba wọn tẹlẹri ni wọn ti gba pada bayii ti wọn si ti tẹwọ gba ti ijọba ibilẹ.

Lamidi fi kun ọrọ rẹ pe ko si ohunkohun to jọ ija tabi rogbodiyan laarin igbimọ naa ati ẹgbẹ mii gẹgẹ bi awọn iroyin kan ṣe n ja rainrin nibẹrẹ ọsẹ yii.

Àkọlé fídíò, 50 Year old Ajayi Folashade: Mo ti kọ́kọ́ dán an wò ní 80s àmọ́, ó kàn ṣáà ń wù mi náà ni