Sheik Ahmad Gumi: Ẹ wo èsì tó fún iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn kòbákùngbé

Gbajugbaja ẹlẹsin Musulumi ati apẹtusaawọ, Sheik Ahmad Gumi ti fesi si ọrọ ti ileeṣẹ ọmọogun Naijiria fi lede lati ki i nilọ.
Sheik Ahmad Gumi lo fi lede wipe ọrọ ẹsin ati ẹlẹyamẹya ti n da rogbodiyan silẹ laarin awọn ọmọogun Naijiria.
Lẹyin to sọ ọrọ naa ni Ileeṣẹ Ọmọogun Naijiria wa fun un lesi wipe ko ṣe diẹdiẹ pẹlu awọn ọrọ to n sọ laisi eri to daju.
Amọ, ninu iforowanilẹnuwo ti ileeṣẹ BBC ṣe pẹlu Gumi lo ti ni awọn ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ko gbọ ohun ye daradara ni, ati wipe oun ko sọ ọrọ odi si wọn.
Gumi ni ọrọ ẹlẹsinjẹsin ti oun n sọ waye laarin ọdun 2010 si 2015 ti kii si ṣe ni isinyii mọ.
''Awọn to n ṣe akoso ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni igbayen ni mo n ba sọrọ kii ṣe ni isinyii''
Bakan naa ni onimọ nipa ẹsin Islam naa ni oun ni ajọsepọ to dan mọran pẹlu ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ti ko si ede aiyede laarin wọn.
Sheik Gumi tun bu ẹnu atẹ lu awọn ileeṣẹ oniroyin ti wọn n gbe iroyin ẹlẹjẹ, ni ko jẹ ki ọrọ awọn eniyan ye ara wọn.
Ọmọogun Naijiria tẹlẹri ni Sheik Gumi ko to di wi pe o jagun fẹyinti gẹgẹ bi dokita ni ikọ ọmọogun.
Amọ, Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ni ko si iwa ẹlẹyamẹya tabi ẹlẹsinmẹsin ni ileeṣẹ ̣omọogun Naijiria nitori naa ki Gumi ṣọ ara ṣe pẹlu ọrọ ẹnu rẹ.
Sheik Gumi lo di ilumọọka lẹyin ti o dunadura pẹlu awọn agbebọn to ji awọn ọmọ ileewe gbe ni agbegbe Ariwa orilẹede Naijiria.
Àwọn jàndùkú ajínigbé kìí sáábà sekú pààyàn, owó ni wọ́n ń fẹ́- Sheikh Gumi
Onimọ nipa ẹsin musulumi Sheikh Ahmad Gumi ti sọ pe awọn agbebọn ajinigbe ki saaba yinbọn pa eeyan.
Sheikh Gumi ṣalaye pe owo lo jẹ ki wọn maa ji awọn eeyan gbe kii ṣe nkan mii.
Sheikh Gumi tun sọ pe awọn janduku ajinigbe yii le fi awọn eeyan ti wọn ba jigbe pamọ si akata wọn titi ti wọn yoo fi ri owo gba lori wọn.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dr Ahmad Abubakar Mahmud Gumi
- Aráàlú gbarata pe Makinde fẹ ṣanwó màálù tí wọ́n pa àti owó ìtọ́jú àwọn tó farapa
- Kò tíì sí ọ̀rọ̀ ìyàwó báyìí o, kí n tó lè sọ̀rọ̀ pé mo fẹ́ gbé ìyàwó, màá ...- Oba Oloyede Akinghare II
- Mo ń ṣe ẹ̀tọ́ mi fún Damilare lọ́dọ̀ màmá àgbà, àmọ́ ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí ló pọ̀ - Mide-Funmi Martins
- Fifi òfin de dída máàlù kiri kò lè dẹ́kun àawọ̀ láàrin àwọn àgbẹ̀ àti darandaran àyàfi... - Fayemi
- Wo obìrin méjì tó ń fi ìbásùn inú yìyín "Snow" ṣara rindin kí ọlọpàá tó ká wọn
- Ọ̀rọ̀ aàbò ní Nàìjíríà ti di kí olórí dorí ẹ mú- Femi Falana
Bakan naa ni onimọ nipa ẹsin musulumi sọ pe awọn janduku ajinigbe yii gan an maa n lepa alaafia.
Sheikh ni awọn ajinigbe ṣetan lati gbe ibọn wọn silẹ ti ijọba ba le ni ifọrọwerọ pẹlu wọn.
O fikun ọrọ rẹ pe ija ẹlẹya mẹya lawọn ajinigbe Fulani ọhun ja.
Sheikh Gumi ni inu awọn Fulani darandaran ko dun si awọn eeyan yoku to wa ni igboro.
''Nitorinaa, bi ilu ṣe ri lo mu ki awọn eeyan di janduku ajinigbe, kii ṣe ohun ti wọn fẹ finu fẹdọ ṣe,'' Sheikh lo sọ bẹẹ.
O tun ṣalaye pe janduku ajinigbe yii ko wa lati ilẹ okeere, ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn.
''Ohun ti mo mọ ni pe lilo awọn ologun kii ṣe ojutu si ọrọ awọn janduku agbebọn yii, ifikunlukun pẹlu wọn lo le ṣee,'' Sheikh ṣalaye.
Sheikh tun fikun ọrọ rẹ pe awọn agbebọn ajinigbe yii kii ṣe Boko Haram.
Amọ o kilọ pe ijọba ni lati wa nkan ṣe si ọrọ wọn ki Boko Haram maa le wọ ọrọ naa.
















