Snow sex: Otútù kò dí àwọn olólùfẹ méjì lọwọ, ìbásùn nínú yìyín ni wọn fi ń ṣara rindin kí ọlọpàá tó ká wọn

Oríṣun àwòrán, PA
Gbogbo ofin isede ati itakete siraẹni ko ma ba awọn ololufẹ meji kan ko si di wọn lọwọ jijẹ igbadun ara wọn lasiko ti ariwo pọ wipe yinyin n pa awọn eniyan lawọn ilu ti otutu ti mu jọjọ.
Ṣe ni oju ka awọn mejeji mọ ti wọn n ni ibalopọ ninu ọkọ ni nkan bii ago meji oru to tutu mini mini ju ti wọn ti ri lati nkan bii ọdun mẹrindinlọgbọn sẹyin ni ilu Dartmoor.
Wọn ni ki awọn fi ṣaami ayajọ ọjọ ololufẹ "valentine" ti àwọn eeyan ti bẹrẹ si ni sọ̀rọ̀ rẹ ki ọjọ naa tilẹ to de rara ki wọn si fi ibalopọ to dara ninu otutu fi sanjọ fun ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bo tilẹ jẹ pe ipo ti otutu lile ọhun wa ni 3C nita gbangba, ololufẹ meji naa ti awọn eeyan kọkọ ro pe obinrin meji ni wọn ni iroyin sọ pe wọn wa ọkọ wa lọtọọtọ lati ile wọn ni Plymouth lati jọ fara yira lowurọ kutu Ọjọbọ.
Gẹgẹ bi iwe iroyin Metro Uk ṣe sọ ọ,ko pẹẹ rẹ ni oju awọn ọlọpaa gaani wọn ti inu wọn ko si dun si ohun ti wọn n ṣe ni wọn ba le wọn lọ sile.
- Bí ẹranko igbó ṣe bu ìdí obìnrin kan tó ń bẹ̀rẹ̀ yàgbẹ́ jẹ
- Ìjì òtútù pa èèyàn 21 ní Amẹ́ríkà, ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ míràn ń dojúkọ ìṣoro àìsíná ẹ̀lẹ́ńtíríkì
- Ìkìlọ̀! America yóò tutù ju bó ti yẹ lọ
- Ìjọba sọ̀rọ̀ lórí ìròyin tó ní Benin Republic fẹ́ di ìpínlẹ̀ kẹtàdínlógójì ní Nàìjíríà
- Wo ẹ̀bùn owó tabua tí gbajúgbajà oníṣòwò kan fún bàbá "Lórí Irọ́"
- 'Àṣẹ ni! Gbogbo àgbàlagbà gbúdọ̀ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 ṣáájú 31 July'
Awọn ọlọpaa Tavistock fi sita loju opo Twitter wọn ni nkan bii ago meji oru kọja iṣẹju mẹtadinlogun pe iru iwa bẹẹ ko ba ofin Covid - 19 mu. Wọn ni:
"Ṣiṣe agbere labẹ awọn irawọ loru, lorii yinyin, da bii pe ṣiṣe iranu ninu fiimu oniyẹyẹ amọ kii ṣe igbesẹ to dara to si lodi si ofin ijinasiraẹni".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ba rọ wọn pe ki wọn maa tẹle ofin lati dinwọ aranka arun Covid 19.
Awọn ara agbegbe naa sọ pe ibudokọ kan to wa lẹgbẹẹ Yelverton kii ṣe ajojii fun iru iwa bayii bẹẹ si ni awan ọlọpaa naa ti wa ṣe e ni ọranyan lati maa dọdẹ ibẹ ki wọn lee mu awọn arufin.
Eyi si lo ṣẹlẹ si awan ololufẹ meji naa ti awọn ọlọpaa gbamu ti wọn si paṣẹ ki wọn maa lọ ile kiakia ti awọn naa ko si ba wọn ja iyan. Ẹwẹ, ero to n jade ni pe awọn obinrin naa yoo foju winaa sisan faani pe wọn ru ofin isede ti ijọba UK kede lagbegbe.
Ọpọlọpọ lo fesi si ọrọ ti awọn ọlọpaa fi sita lori ayelujara. Awọn mii n ki ololufẹ meji naa ku oriire igboya ti wan fi koju yinyin to n paayan. Ẹlomii ni "ninu afẹfẹ yii? ẹ jẹwọ ẹni tẹẹ jẹ ni gẹgẹ bii ara ilẹ Britain". Amọ awọn mii to tako nkan ti wọn ṣe ni o ku diẹ kaa to - "Ita ti tutu ju fun faaji yẹn".
Eeyan ni "ki ni aburu ninu ohun ti wọn n ṣe? Wọn ko ṣaa jade ninu ọkọ wọn torinaa ko si arun ti wọn n tan kalẹ ati pe oru ọganjọ ni, aago meji torinaa kii ṣe loju araalu. Daju daju o ni nkan mii tawọn ọlọpaa n wa".
















