Covid vaccine: Gbogbo àgbàlagbà gbúdọ̀ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid ṣáájú òpin oṣù keje ní UK

Ijọba ti paa laṣẹ pe gbogbo agbalagba ni yoo gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 wọn si gbudọ gba a ki opin oṣu keje to de.
Awọn to bọ si abẹ ofin yii pẹlu ọjọ ori wọn to miliọnu mẹtadinlogun lati igba ti orilede UK ti ko abẹrẹ ajẹsara ọhun jade ninu oṣu kejila ọdun 2020.
Nibayii, olootu ijọba orilẹeede naa, Boris Johnson ni oun fẹ ki eto yii maa tẹsiwaju ko si ya kanmọkanmọ.
O ni gbedeke oṣu keje yoo fun awọn to ba kagbako aisan naa lati wa ni idaabo bo laipẹ yoo si tun mu ki wọn lee dẹ okun lọrun awọn ofin isede jakejado orilẹede naa.
Olootu naa yoo ṣe ipade pẹlu awọn agbaagba minisita lori bi wọn ṣe dẹwọọ isede nilẹ Gẹẹsi ko to di pe o kede ilana tuntun lọjọ Aje.
Wọn ni bi awọn to wa ni eti bebe kiko arun naa ba tete gba abẹrẹ, yoo mu adinku ba iku ti o n fa yoo si din wahala ku lọrun ajọ eleto ilere orilẹede naa.
Afojusun ijọba ilẹ UK tẹlẹ ni lati rii pe gbogbo awọn to dagba ti gba a tan ninu oṣu kẹsan. Amọ nibayii, o ti sun wa sẹyin pe gbogbo agba to wa ni ẹni ọdun aadọta lọ soke gbudọ ti gba abẹrẹ ajẹsara yii ni ọjọ kẹẹdogun o'su kẹrin ọdun koda to fi mọ awọn ti ọjọ ori wọn ko to bẹẹ amọ to ni aisan to lee sun wan si bebee kiko arun naa.
Amọ wọn ko tii gbe ofin to le sori ti awọn ti ko tii to aadọta ọdun.
Ọjọgbọn Adam Finn to jẹ ọkan lara igbimọ to wa fun eto abẹrẹ ajẹsara yii sọ fun BBC pe ọgbọn amulo ti igbimọ naa fi ṣọwọ si ijọba gẹgẹ bi imọran ni wan ti n ṣeto kikasẹ rẹ nilẹ lọwọ bayii ati pe ijọba yoo ṣe ipinu wọn lori bi wọn yoo ṣe ṣe ni bii ọjọ mlo si isinsiyii torinaa "mo lero wipe ikede itagbangba kan yoo jade ni bii ọsẹ to n bọ".
Bayii ni wọn ṣe ṣe isọri awọn ti yoo kọkọ gba abẹ́rẹ́ ajẹsara naa:

Ìdí tí àwọn èèyàn kan kò fí le ni àrùn Coronavirus
Bí àwọn onímọ̀ ṣe n gbìyànjú láti wá ojutùú sí àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19, tí ọ̀pọ̀ ń wá òògun tàbi abẹ́rẹ́ ti yóò yanju àrùn náà pátápáta, ní àwọn míràn ń mojú tó èròjà tí kò le jẹ́ kí àwọn míràn ni coronavirus.
Sáájú ni àwọn onímọ̀ sáyẹ́nsì sàkíyèsí pé, ẹni ti ko ni ààrùn covid-19, tabi tó si rùú là, kò ní èròja to n bá kòkòrò wọ ìyájà lára.
Lẹ́yìn náà ni wọn tún ri pé, èlòmíràn tó tún ni èròjà tó n gbògun ti ààrun covid-19 lára, pàdánù rẹ̀ láàrín oṣù mẹ́ta péré.

Oríṣun àwòrán, @iamseunalaofin
Bí gbogbo ayé ṣe wá n ronu lórí àwọn èròjà ara tó le gbógun ti ààrun covid yìí, àwọn oníwàdìí ìmọ̀ sáyẹnsì míràn ti ri pé, èròjà kan wà nínú ara ti o le wúlò.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eroja naa ni wọ́n ń pe ni "White Blood Cell", èròjà yìí ti wà lara sùgbọ́n ti kò sí ẹni to mọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹlẹ́tàn ni ọkùnrin, tó bá rí nkan tó n wa lára obìnrin, yóò yí ìwà padà - Bimpe Oyebade
- Wo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Trump tó mú kí alátakò ilé darapọ̀ mọ́ tìta láti yọ nípò
- A kò le gbà kí ASUU gba ₦30bn nínú ₦40bn tíjọba gbé kalẹ̀ - NASU yarí
- Ẹ̀yin adarí Nàíjíríà, ẹ dẹ́kun àwáwí asán lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ - Ààrẹ àṣòfin àgbà
- Ẹ dákẹ́ àhesọ ọ̀rọ̀, ohun tó pa ẹ̀gbọ́n àti àbúrò Orisabunmi rèé - Mọ̀lẹ́bí gbarata
- Wo àdánù tó wà nínú gbígba ayédèrú áápù fún ìforúkọsílẹ̀ NIN lórí ayélujára
- Àmúlò ẹ̀rọ POS fun òwò ṣíṣe, ṣé ó tọ̀nà nínú Islam àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
- "Ẹ̀yin tẹ̀ ń parọ́ ẹlẹ́yà-mẹ̀yà mọ́ Amotekun Oyo, Seyi Makinde lẹ̀ ń dojú ìjà kọ"
- Kí ló ma n fa Àkúfà nílẹ̀ Yorùbá, àti ọ̀nà àbáyọ?
Kíní a npè ni "T Cell"?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé eroja "T Cell," kò jẹ́ ǹkan tuntun ninu ìmọ̀ sayẹnsì, amọ ó jọ pé, inú rẹ̀ ni ojútùú si ìsòrò àrun coronvairus wa.
T Cell jẹ́ èròjà kan to n dáàbò bo àgọ́ àra, iṣẹ́ to si n ṣe ni láti gbogun ti àwọn eroja àjòjì tó bá wọ inú ara.
Iṣẹ́ rẹ ni ko ṣe àwari àjòjì náà, kí ó si pa. Ó si lé ni trílíọnu iru T Cell yii tó wà nínú ara.
Ẹ̀wẹ̀, "T Cell" le wa ni àyíka ara fun ọ̀pọ̀ ọdún ní agbegbe ti ẹ̀jẹ̀ wa, láti ma a ṣọ́ ààrùn tàbi eroja àjòjì kan tó bá fẹ́ wọ inú ara.
Bákan náà ibẹ ni wọ́n kò àwọn sójà to n dá ààbò bo ara síi, ni kété to bá sì ti ri àjòjì tó bá ara jà rí, kía ni yóò ti kòjú ìjà síi.
Ọ̀pọ̀ ìwádìí lo ti fi ìfdí rẹ̀ múlẹ̀ báyìí pé, àwọn tó ti ni ààrun covid-19, ti wọ́n si ruu la le ni èròjà T Cell, ti yoo si máa foju sọ́nà fún ààrun covid-19 tó bá tún jẹyọ, yála ẹni náà fàmì hàn nígbà àkọ́kọ́ tàbi kò fàmìhàn,

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ìmọ̀ tún ti fi hàn pé, ìgbà míràn àyẹ̀wò lé fi hàn pé, ẹ̀lòmìràn le maa ni èròjà tó le gbògun ti ààrun covid-19, eyiun "Antibodies', sùgbọn tí yóò ni "T Cell".
Èyí ló wá tọ́kan sí pé, àwọn tó ni "T Cell" yìí pọ̀ jú bi àwọn onímọ̀ ṣe lérò lọ.
Ìwádìí fi hàn pé, ìdá ọgójì sí ọgọ́tà àwọn tí kò ni ààrun Coronavirus ló ni "T Cell" lara.
Nítori náà àwọn ti "T Cell bá wà nínú àgọ́ àra wọ́n ko ni ni ààrun coronavirus, tàbí kí wọ́n ni i, ko si ma farahàn tàbí dáwọn dùbúlẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ìròyìn àyọ̀ àti ìbànújẹ́ tó wà níbẹ̀
"Tí a bá wo àwọn tó ni ààrùn Coronavirus sùgbọ́n ti wọ́n kò nílò láti de ilé ìwòsàn, ó túmọ̀ sí pé wọn ni "T Cell" ni" gẹ́gẹ́ bi Heyday ṣe sọ.
Ìròyìn ayọ ni èyí jẹ́, ó sì tún dára fún àwọn tó bá fẹ́ gba abẹ́rẹ́ àjẹsára, nítori pé ó túmọ sí pé wọn le ri "antibodies" ti yóò mu ki "T Cell le sàwári ààrun náà "èyí dára".
Sùgbọ́n fún àwọn to ṣe àisàn tó wà nílé ìwòsàn, èyí túmọ̀ sí pé "T Cell yìí kò ṣiṣẹ́ fún wọ́n, ọ̀pọ̀ T Cell ẹlomíràn sì ló ti fara kásá, èyí sì buru jái, nítori yóò tún pa àwọn sẹ́ẹ̀lì míràn ninu ara.

















