Doctors on Strike: Coro wà Coro ò sí o, èmi á lọ́ sókè òkún bí mo bá ríṣẹ́ - dókítà

Nọọsi kan da ọra bora

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn dokita Naijiria ti figbe ta pe ki ijba apapọ ma wulọ r awn rara lati ma ko l si oke oku lati lọ maa ṣiṣẹ.

Dokita kan ti ko fẹ da orukọ toripe o n ba ijọba ibilẹ ṣiṣẹ ni Naijiria s fun BBC Yoruba pe idi ti ọpọlọpọ dokita Naijiria ma fi n lọ soke okun ni wipe nkan ti ijba n ṣe ku diẹ kaato.

Laipẹ yii ni minisita fun eto ilera, Osagie Ehanire kil fun awn dokita Naijiria nigba to n sọ̀rọ̀ nibi ipade igbimọ amuṣẹya ti ijọba lori ọrọ Covid-19 pe ki wọn tun ero wọn ro.

O sọ eyi nitori o ni bi wọn ba lọ si ilu London, wọn ko lee ri owo ajẹmọnu ohun toju n ri lẹnu iṣẹ kankan gba lọhun tori naa wọn ko nilo lati lọ sọhun rara.

Dokita oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ ti a pe sọ pe tori gbogbo nkan ni koko ti awọn dokita fi maa n sa lọ soke okun latori owo oṣu titi dori gbogbo owo ajẹmọnu to yẹ ki wọn maa san fun wọn.

"Ko si nkan ati ṣiṣẹ ni awọn ileewosan wa, a kawe o, a pari agboye o, ṣugbọn ko si nkan ati ṣiṣẹ lawọn ileewosan wa ati pe owo ti ijọba n san kere jọjọtaa ba fi wo gbogbo ọdun ti dokita lo nileewe, lo jẹ ki awn eeyan maa sọ pe ti awọn ba ri ibi to daa, wọn a lọ".

Àkọlé fídíò, Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Bakan naa, dokita ni kii ṣe pe ijọba Naijiria ko lee san ju bayii lọ ṣugbọn wọn ko kan fi ọrọ eto ilera ṣe pataki ni. O fi kun un wi pe koda, owo ajẹmọnu ti ijọba Naijiria n sọ yii, ọdọ awọn dokita ijọba apapọ nikan lo n de, bi yoo ba kan awọn oṣiṣẹ ipinlẹ lọwọ rara, o ku sọwọ gomina wọn.

Nigba taa bi dokita ọhun boya o ti ṣe tan bayi bayi ninu asiko arun Coronavirus yii, o dahun pe lọwọ lọwọ, oun n ṣe awọn nkankan lọwọ ṣugbọn "bi arun Coronavirus wa o tabi ko si, mo ti ṣe tan lati lọ tori lọhun wọn pese gbogbo eto abo fun dokita ju ọdọ wa nibi yii lọ to bẹẹ ti arun naa ko le ran wọn".

Ni ti dokita Adewale to n ṣiṣẹ ni ileewosan aladani kan ni Ado Ekiti, ipinlẹ Ekiti, o ni bi oun ba ri anfani ati lọ ṣiṣẹ loke okun, oun yoo ko ẹru oun kia.

"Bi wọn ba fun emi niṣẹ ni UK, maa lọ o. Owo ajẹmọnu ti wọn n san ni Naijiria ko difa rara tori iye ti wọn n san fawn dokita ni UK koda bi ko ba si owo ajẹmọnu ohun toju n ri nibẹ ṣi pọ ju iye ti Naijiria n san lọ".

O ṣalaye pe kii ṣe tori owo nikan lawn dokita fi n sa lọ soke okun ṣugbn ai si irinṣ lawọn ileewosan ijọba gan n da ni lagara tori eyi awn alaisan a kan maa ku iku ti ko yẹ ki wọn ku ni".

Dokita Wale ni oun gbagbọ pe eeyan le ṣe oriire lorilẹede rẹ ṣugbọn kii ṣe keeyan kan lọ ibiṣẹ laarọ ko pada sile ni iṣoro ṣugbọn ki inu eeyan tun dun si iṣẹ teeyan nṣe ati agbegbe iṣẹ naa".

O ni owo oṣu dokita kan ni London lee san owo oṣu dokita Naijiria mẹrin si mẹfa.

Dajudaju, ko ba ti wu awọn dokita Naijiria to lati duro sile ni orilede wọn ṣugbn wọn ni ijọba ko wu awọn lori.