August Agboola Brownie: Wò ó bí ogun àgbáyé kejì ṣe sọ ọmọ Yorùbá di akọni nílẹ̀ òyìnbó

Oríṣun àwòrán, Public domain
Laarin ogunlọgọ akọni eeyan ti orilẹ-ede Poland ma n mọ riri wọn fun ipa ti wọn ko lasiko ogun agbaye keji, ọmọ orilẹ-ede Naijiria kan wa lara wọn.
August agboola Browne, to jẹ akọrin Jazz, ti gbe ni Poland fun ọdun mẹtadinlogun, ko to o darapọ mọ ikọ Nazi lọdun 1949 - itan sọ pe oun nikan ni alawọ dudu to ṣe bẹ ẹ lorilẹ-ede naa.
Ko si ju ẹni ogoji ọdun lọ nigba naa.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa
- Sanusi Adebisi Idikan rèé, olówó tó ń san owó orí fún gbogbo ọkunrin ilẹ̀ Ibadan
- Ẹfunsetan Aniwura, obìnrin tó ju ọkùnrin lọ
- Hubert Ogunde rèé, baba àwọn òsèré tíátà
- Kí ló wà ní ìdí igbá tí àwọn olorì Aláàfin máa ń tí lóde Ọ̀yọ̀
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Igbo Olodumare rèé, níbi tí Ìgbín ti tóbi ju Ìjàpá lọ
- Ìdílé márùn-ún tó gbajúmọ̀ fún òwò ẹrú nílẹ̀ Yorùbá
- Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá
Botilẹ jẹ pe ìdá mẹrindinlọgọrun awọn eeyan to n gbe ni olu ilu Poland nigba naa lo kú, tabi di alainilelori nitori ogun ti Germany gbe ti wọn, amọ ori ko Agboola yọ.

Oríṣun àwòrán, WOJCIECH ZAŁUSK
O si gbe ni orilẹ-ede naa lẹyin ti ogun pari ni ọdun mẹrindinlọgọrin titi di ọdun 1956, to ko lọ si Britain pẹlu iyawo rẹ keji.
Ni olu ilu Poland, Warsaw, wọn ri okuta kekere kan mọlẹ lati ma a fi ṣe iranti Brownie.
Ko si akọsilẹ kankan to ṣe e gbamu nipa igbe aye rẹ, yatọ si kekere to wa ninu iwe to kọ lati darapọ mọ ẹgbẹ awọn ajagunfẹhinti lọdun 1949.
Ọgọta ọdun ni iwe naa fi wa ni ipamọ titi di ọdun 2009, ti Zbigniew Osinski lati musiọmu Warsaw, ṣe alabapade rẹ.
Iwe naa si lo ran awọn olukọtan lọwọ lati ṣe akojọpọ bi igbe aye Agboola ṣe e ṣe ko ri.
Akọsilẹ Brownie fihan pe o n pin iwe iroyin fun tita, bakan naa lo tun n ta awọn ohun eelo to n lo ina, to si tun pese ile fun awọn aṣatipo lasiko ogun naa.

Oríṣun àwòrán, OFFICE OF VETERANS AND VICTIMS OF OPPRESSION
Ibẹrẹ igbeaye Agboola Brownie:
Ilu Eko ni wọn bi Agboola Brownie si ni ọjọ kejilelogun, oṣu Keje, ọdun 1895.
Orukọ iya ati baba rẹ ni Wallace ati Jozefina.
Ilẹ Gẹẹsi ni Brownie kọkọ de si, ko to o darapọ mọ ẹgbẹ elere ori itage kan nilẹ yuroopu, eyi lo si sọ di ero ilẹ Poland.
Ilu Krakow to kọkọ gbe nibẹ lo ti fẹ iyawo rẹ akọkọ, Zofia Pykowna, to bi ọmọkunrin meji fun, Ryszard ati Aleksander.
Igbeyawo naa fori ṣanpọn, ṣugbọn lasiko ti ogun naa bẹrẹ, Brownie ṣeto fun awọn ọmọ rẹ ati iya wọn lati lọ ṣe atipo nilẹ England, amọ ko tẹle wọn lọ.
'Eeyan jẹjẹ, ti kii ṣe aṣehan ni Agboola'
Tatiana Brownie, ọmọbinrin ti iyawo keji to fẹ, Olga Miechowicz bi fun, ṣi wa laye.
Ilu London lo gbe dagba, oun si ni ọmọ rẹ kan ṣoṣo to ku laye.
O ti pe ẹni ọdun mejilelọgọta bayii - baba rẹ ku ni ọdun 1976 nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹtadinlogun.
Nkan to ranti nipa baba rẹ ni pe eeyan jẹẹjẹ ni, to fẹran lati ma a da nikan wa, ti ko si sọ nipa irinajo rẹ nilu Eko tabi Poland fun ọmọ rẹ ri.
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
- Ọọ̀ni obìnrin, Lúwòó Gbàgídà rèé, akọni tó ń gun ọkùnrin ní ẹṣin rìn
- Ìtàn ayé Abiola Peller, ọlọ́wọ́ idán tó fi ọ̀bẹ gé ìyàwó rẹ̀ sí méjì
- Irú èpè wo ni Aláàfin Aolẹ ṣẹ́ fún ìran Yorùbá?
- Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin
- Jesu Oyingbo rèé, pásítọ̀ tó láṣẹ ìbálòpọ̀ lóri ọmọ ìjọ obìnrin
Tatiana ko mọ idi pato ti awọn obi rẹ ko fi sọ pupọ nipa igbe aye wọn fun. Ṣugbọn o fura pe o ṣe e ṣe ko jẹ nitori ibanujẹ ati iporuru ọkan ti wọn farada, ati oriṣiriṣi iwa ika ti wọn ri.
Bakan naa lo sọ pe, baba oun ko figba kankan kọ aṣa Poland silẹ, to fi jẹ pe ede Polish nikan ni wọn n sọ ninu ile wọn.
Ọrẹ Brownie kan ti ẹ sọ pe oriṣiriṣi èdè lo gbọ, to si le sọ.

Ọdun 2009 ni iroyin nipa Brownie jade si gbangba lasiko ti ija ẹlẹyamẹya kan waye ni Poland.
Ohun lo si mu ki ọpọ eeyan polongo fun fifi nkankan ṣe iranti rẹ, ti wọn si tun pe e ni akọni fun orilẹ-ede naa.
Aarẹ nigba naa, Lech Kaczynski gbero lati da Agboola lọla nigba to pe ẹni ọdun marundinlaadọrin ti ogun naa pari, ṣugbọn ijamba baalu to mu ẹmi rẹ lọ ba ero naa jẹ.

Ọdun to kọja ni ajọ aladani kan ṣẹṣẹ ṣe okuta iranti fun.
Iṣẹ orin kikọ ni Brownie ṣe nigba to pada si England, to si gbe igbe aye jẹlẹnkẹ fun ogun ọdun to gbẹyin aye rẹ.

















