Sasa market fight: Nǹkan mẹ́ta tí àwọn gómìnà àti Ọba Aládé fẹnukò lé lórí níbi ìpàdé ètò ààbò tó wáyé n'Ibadan

Awọn gomina atawọn ọba ilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, @seyimakinde

Awọn gomina iwọ-oorun gusu ti pa ohun pọ ti wọn si jọ pinu labẹ akoso ajọ to n mojuto ọrọ aje ni Naijiria pe awọn ni awọn gbudọ maa ṣakoso igbo ati aginju awọn jakejado Naijiria.

Awọn gomina iwọ-oorun gusu ati awọn Ọba Alade ṣe ipade pọ ni ilu Ibadan l'ọjọ Abamẹta lati jiroro lori eto aabo, bẹẹ si ni wọn fi ohun ṣọkan lori awọn nnkan pataki mẹta ọtọọtọ.

Gomina Rotimi Akeredolu ti ipinlẹ Ondo, to tun jẹ alaga awọn gomina Iwọ-oorun guusu ṣe alaye pe, botilẹ jẹ pe olori awọn oṣiṣẹ fun aarẹ Muhammadu Buhari, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari, ọga agba ajọ ọlọpaa, Mohammed Adamu ati adari agba ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ orilẹede yii lo ṣe atiwaye ipade naa, awọn mẹtẹẹta ko ni anfani lati wa si ilu Ibadan lati Abuja nitori bi oju ọjọ ṣe ri.

O tẹsiwaju pe lẹyin ọrẹyin ni awọn gomina ati awọn Ọba Alade pinnu lati ṣe agbeyẹwo ipo ti eto aabo de duro ni agbegbe yii.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

Atẹjade ti wọn fi lede lati ọwọ akọwe iroyin fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Taiwo Adisa tọka pe gomina Rotimi Akeredolu lo ka awọn nnkan mẹta ti wọn fi ohun ṣọkan le lọri nibi ipade naa.

Awọn nnkan mẹta naa ni;

1. Pe naa fọwọ si ipinnu igbimọ to n ṣe amojuto ọrọ aje orilẹede yii, National Economic Council (NEC), lori amojuto awọn inu igbo ti ẹranko ti n jẹ.

2. Wi pe aabo to nipọn gbọdọ wa ni awọn ẹnu ibode to wọ orilẹede yii.

3. Ati pe ayẹwo to peye yoo wa lori igbesẹ awọn to n ṣiṣẹ darandaran nita gbangba, bẹẹ si ni awọn ileeṣẹ iroyin yoo ṣe iranlọwọ fun orilẹede yii nipa didẹkun iroyin ofege.

Àkọlé fídíò, Ṣé o nífẹ̀ẹ́ láti kọ èdè ẹ̀yà Nàìjíríà míì ní kíákíá?

Nibi ipade naa to waye ninu gbọngan nla igbalejo to n bẹ ni ofisi gomina ni Agodi, Ibadan, ni a ti ri awọn gomina marun un ọtọọtọ pẹlu olugbalejo wọn tii ṣe gomina Ṣeyi Makinde, gomina Akeredolu ti Ondo, Kayode Fayemi ti Ekiti, Gboyega Oyetola ti Osun ati Dapo Abiodun ti ipinlẹ Ogun.

Bakan naa ni igbakeji ọga agba ajọ ọlọpaa ni ẹkun Iwọ-oorun gusu, David Folawiyo ati awọn ọga agba ileeṣẹ ologun nipinlẹ Ọyọ ba wọn pejupesẹ sibi ipade naa.

Awọn alaga igbimọ lọbalọba ni gbogbo ipinlẹ Iwọ-oorun gusu ati awọn Ọba Alade naa ko gbẹyin.

Àkọlé fídíò, Lori iro: Ká ni àwọn Òbí mi gbà fún mí, èmi àti Sunny Ade á jọ máa 'Compete- Baba Lórí ir

Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ nibi ipade ọhun, Akeredolu ṣe alaye pe ipade naa waye lojuna ati wa ọna abayọ si iṣoro eto aabo to n ba agbegbe yii finra.

Lara awọn Ọba Alade to kopa nibi ipade naa ni Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi III; Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Enitan Ogunwusi; Akarigbo ti Remo, Ọba Babatunde Ajayi; Olugbo Ile Ugbo, Ọba Fredrick Akinruntan; Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji, Aje Ogungunnjso 1; ati Olugbọn ti Orile Igbọn, Ọba Francis Olusola Alao.

Kọmisana ajọ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, Ngozi Onadeko, ati awọn adari ẹṣọ aabo mii naa darapọ mọ wọn nbi ipade naa.

Ki lo ti ṣẹle sẹyin?

Gómìnà márùn ún, Ọba Alade mẹ́fa ti gúnlẹ sí Ibadan fún ìpàdé lórí ètò ààbò

Ibadan

Awọn Ọba Alade mẹfa ọtọọtọ lati ẹkun Iwọ-oorun gusu orilẹede yii ti gunlẹ si olu ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ to n bẹ lagbegbe Agodi nilu Ibadan, saaju apẹro lori eto aabo ti yoo waye lonii ọjọ Abamẹta.

Yatọ si awọn Ọba Alade yii, awọn gomina marun un ọtọọtọ lati awọn ipinlẹ mii naa ti darapọ mọ gomina Ṣeyi Makinde nibi ipade naa.

Awọn alejo naa wa lara ọgọrọ awọn alẹnulọrọ ti yoo kopa nibi ipade eto aabo ti yoo waye nibi gbọngan nla igbalejo to n bẹ ni ọfisi gomina Ṣeyi Makinde.

Lara awọn eeyan ti yoo pejupesẹ sibi ipade naa ni olori awọn oṣiṣẹ fun aarẹ Muhammadu Buhari, Ibrahim Gambari.

Awọn Ọba Alade to ti wa nikalẹ lasiko ti a ko iroyin yii jọ ni, Ọọni Ile Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi; Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi; Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Adetunji; Akarigbo ti Remọ, Ọba Babatunde Ajayi, Olugbo ilẹ Ugbo, Oba Fredrick Akinruntan ati Olugbọn ti Orile-Igbọn, Ọba Francis.

Ibadan

Lara awọn gomina to ti wa nikalẹ ni, Gboyega Oyetola (Osun), Arakunrin Rotimi Akeredolu (Ondo), Kayode Fayemi (Ekiti) ati Dapo Abiodun (Ogun).

Àkọlé fídíò, UNSUB App: Ṣé ó mọ́ ẹni tí wọ́n ti fipá bá lòpọ̀ rí tó ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo?-Olajide Abiose

Awọn alejo to yara de ibi ipade naa n reti adari agba ileeṣe ọtẹlẹmuyẹ, Yussuf Mogaji Bichi ati gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko.

Igbimọ lọbalọba nipinlẹ Ọyọ ati awọn aṣoju ijọba naa ko gbẹyin nibi ipade ọhun.

Ohun ti a le fi idi rẹ mulẹ ni pe ipade naa ko se lẹyin awọn rogbodiyan to waye lẹnu ọjọ mẹta yii ni ẹkun Iwọ-oorun gusu, paapa julọ ija ẹlẹyamẹya to waye laarin Yoruba ati Hausa ninu ọjọ Ṣaṣa nilu Ibadan lọsẹ to kọja, ninu eleyii ti ọpọlọpọ ẹmi ati dukiya ti ṣofo.