Mo sun ìlú Ibarapa mọ́jú lẹ́yìn tí wọ́n pa Dr Aborode - Makinde

Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyi_amakinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti sọrọ lori iku ọmọwe Fatai Aborode ti awọn janduku kan ṣekupa nipinlẹ Oyo.

Nigba to n sọrọ eto kan nileeṣẹ igbohunsafẹfẹ abẹlẹ kan niluu Ibadan, Makinde ni iku ọmọwe naa lọwọ oṣelu ninu.

Makinde sọ pe oloogbe ọhun jẹ ẹnikan to sun mọ ohun nitori naa oun ko le fi ọwọ yẹpẹrẹ mu iku rẹ.

O ṣalaye pe oun sun mọju nigba ti oun ṣabẹwo si ilu Ibarapa nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, ki oun le mo bi ọrọ naa ṣe jẹ ni pato.

Gomina ọhun ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe ọpọ eeyan lo n sọ pe awọn Fulani lo ṣekupa arakunrin ọhun, ṣugbọn nigba ti oun foju gaanni baba oloogbe naa, o sọ fun oun kedere pe ọrọ iku rẹ lọwọ oṣelu ninu.

Makinde

Oríṣun àwòrán, seyi_amakinde

Makinde ni baba oloogbe ọhun ṣalaye fun oun pe alupupu lo gbe lọ ọmọwe Aborode lọ si oko lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹ, bo tilẹ jẹ pe Aborode ko pada wale mọ, ṣugbọn ko si ijamba kankan to ṣẹlẹ si ẹni to fi alupupu gbe lọ sinu oko.

Àkọlé fídíò, Femi Falana, Endsars: Awolowo kò fáààyè gba kí èèyàn máa yàgò fún Màálù nígboro

O ni oun ti paṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa lati gbe iwadii to tọ dide lati mọ irufẹ iku gan to pa oloogbe naa.

Gomina Makinde fi kun pe ki awọn ara ilu maa gbiyanju lati sẹ iwadii ohun gbogbo ti wọnm ba gbọ ki wọn to maa sọrọ nitori awọn kọlọrọsi to maa n ti ọwọ oṣelu bọ irufẹ iṣẹlẹ bayii.

Makinde pari ọrọ rẹ pe kii ṣe awọn Fulanbi nikan lo n da ilu ru, awọn ọmọ ilẹ Yoruba naa wa nibẹ pẹlu.

Lẹyin naa lo kilọ fun gbogbo awọn to maa n gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri ki wọn ṣọra wọn.

Àkọlé fídíò, UNSUB App: Ṣé ó mọ́ ẹni tí wọ́n ti fipá bá lòpọ̀ rí tó ń fẹ́ ìdájọ́ òdodo?-Olajide Abiose