Nigeria school abduction, kidnapping: Wo iye ìgbà tí àwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé lọ

Oríṣun àwòrán, AFP
Wo ìgbà mẹ́rin táwọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbé nílé ìwé wọn ní Nàìjíríà
Awọn agbebọn ṣadeedee yabo ileewe girama ilu Kagara nipinlẹ Niger lọjọ Iṣẹgun nibi ti wọn ti ji ọpọ akẹkọọ ati olùkọ lọ.
Ọga ileewe naa, Danasabe Ubaidu sọ fun BBC pe ẹgbẹta akẹkọọ lo wa nile iwe nigba ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Gomina ipinlẹ Niger, Abubakar Bello ṣalaye pe akẹkọọ mẹ́tàdínlọgbọn ati oṣiṣẹ ileewe ọhun mẹta to fi mọ idile mejila lori ti ko yọ bayii.
Kò sí ẹni tó tii mọ awọn ajinigbe yii, amọ ipinlẹ Niger wa lara awọn ipinlẹ ti ijinigbe ti n ṣẹlẹ julọ ni Naijiria.
- Ṣé lóòtọ́ ni omidan yìí ya wèrè ní kété tí ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní òun fẹ́ fi ṣaya?
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
- Kí ló mú kí géńdé Olorun fi àfọ́kù ìgò gé ǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ ní Kano?
- Ọwọ́ pálábá Abubakar, mọ́káliíkì ségi níbi tó ti fẹ́ jí ọkọ̀ gbé l'Abuja
- Wo oríṣi oúnjẹ márùn ún tí kò wọ́pọ̀ ṣùgbọ́n tí àwọn kan fẹ́ràn púpọ̀ ní Nàìjíríà
Wọnyii ni awọn ileewe ti awọn agbebọn ti ji àwọn akẹkọọ lọ ní Naijiria:
1. Ijinigbe awọn akẹkọọbinrin ileẹ̀kọ́ Chibok.
Ni ọjọ kẹrinla oṣu kẹrin ọdun 2014 ni Boko Haram yabo ileewe girama awọn obinrin niluu Chibok nipinlẹ Bornu nibi ti wọn ji akẹkọọbinrin 276 lọ.
Iroyin iṣẹlẹ ijinigbe naa tan kaakiri gbogbo agbaye lẹyin ti Boko Haram wọ ilu Chibok loru ti wọn si da ibọn bolẹ ki wọn to ko awọn akẹkọọ naa sinu ọkọ lọ.

Oríṣun àwòrán, EPA
Iṣẹlẹ yii lo mu ki ọpọ bẹrẹ sí ni tako ijọba Aarẹ orileede Naijiria nigba naa, Goodluck Jonathan kaakiri agbaye.
Lẹyin naa oriṣiiriṣii akọle bi #BringBackOurGirls, #BringBackOurDaughter gbori ayelujara kan.
Lootọọ ni ọpọ ninu wọn gb'ominira nigba ti Aare Muhammadu Buhari gori oye, ṣugbọn awọn toku si wa lakata Boko Haram di oni.
2. Iṣẹlẹ ijinigbe awọn akẹkọọbinrin ileẹ̀kọ́ Dapchi:
Loṣu keji, ọdun 2018 ni awọn afurasi Boko Haram kọlu ileẹ̀kọ́ girama awọn obinrin to niluu Dapchi nipinlẹ Yobe nibi ti wọn ji aadọfa (110)akẹkọọbinrin lọ.

Iṣẹlẹ yii waye lẹyin ọdun mẹrin ti ijinigbe awọn Akẹkọọbinrin Chibok ṣẹlẹ.
Gomina ipinlẹ Yobe, Ibrahim Gaidam ni awọn ologun to ṣi oju ọna silu Dapchi lo okunfa iṣẹlẹ ọhun.
Mẹrinlelọgọrun ninu wọn lo gba itusilẹ loṣu kẹta ọdun 2018, nigba ti marun un ninu wọn ku lọjọ ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ gan an.

Oríṣun àwòrán, Reuters
3. Ijinigbe awọn akẹkọọkunrin ileẹ̀kọ́ girama ilu Kankara:
Loṣu kejila ọdun 2020 lawọn agbebọn kọlu ileewe girama awọn ọkunrin to wa ni Kankara nipinlẹ Katsina nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ to le lọọdunrun lọ.
Ninu igbo ni wọn ko awọn ọhun lọ nipinlẹ Zamfara.
Olori Boko Haram, Abubakar Shekau kọkọ ṣọ pe awọn ọm'ogun oun lo wa nidi iṣẹlẹ naa ki ijọba ipinlẹ Katsina to ni awọn ajinigbe lo gbe awọn akẹkọọ ọhún lọ.
Lẹyin ọjọ diẹ ni ojile lọdunrun akẹkọọ ninu wọn gbà ominira lẹyin ti gomina Ipinlẹ Katsina sọ pe ẹgbẹ Miyetti Allah ti dá sí ọrọ naa.
- Kí ló mú kí géńdé Olorun fi àfọ́kù ìgò gé ǹkan ọmọkùnrin rẹ̀ ní Kano?
- Akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá mú ìbọn ìléwọ́ lọ ilé ìwé láti yìín lu olùkọ́ tó ní kó gé irun orí rẹ̀
- Ọwọ́ pálábá Abubakar, mọ́káliíkì ségi níbi tó ti fẹ́ jí ọkọ̀ gbé l'Abuja
- Ẹ̀yin ọmọ Yoruba, ẹ dáàbò bo ara yín lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú tó ń kọlù yín - Sunday Igboho
4. Ijinigbe awọn Akẹkọọ ileẹ̀kọ́ girama Kagara:
Oru ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindilogun, oṣu keji, ọdun 2021 yii ni awọn agbebọn yabo ileewe girama awọn ọkunrin niluu Kagara nipinlẹ Niger nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ at'awọn olukọ kan pẹlu ẹbi wọn lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
A ko ti ohun kan nipa ibi ti awọn ajinigbe ko awọn akẹkọọ ọhún lọ.
Bakan naa, awọn ajinigbe naa ko tii sọ iye ti wọn fẹ lati da awọn eeyan ti wọn jigbe silẹ.
- "Èèyàn mọ́kànlá ni a yìnbọn pa níbi ìdigunjalè Offa"
- Mo pàdánù owó tó lé ní N20m lọ́jà Shasha, mi ò padà síbẹ́ mọ́- Alhaji Nyako
- Ṣé lóòtó ni ilé-iṣẹ́ ológun gbé hẹlikópítà ìjagun lọ si Orlu ní ìpínlẹ̀ Imo?
- Irọ́ ni o, mí o fẹ̀ Lateef Adedemeji- Oyin Elebuibọn pẹ̀lú omijé ojú
- Ìjọba ti ileẹ̀kọ́ pà lẹ́yìn tí àwọn jàndùkú ṣèkọlù sí Osogbo, ìpínlẹ̀ Osun
- Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ aṣọ́bodè (Customs) tẹ́lẹ̀ tó kú tí wọ́n fẹ̀sùn kíkó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ bílíọ̀nù jẹ kan

















