Funmi Martins: Mide-Funmi Martins sọ̀rọ̀ jáde lórí ọ̀rọ̀ Damilare tí wọ́n ní Shina Peters lò bí i

Mide Martins, Shina Peters ati Oloogbe Funmi Martins

Oríṣun àwòrán, Mide-Funmi Martins

Gbajugbaja oṣere fiimu Yoruba, Mide Martins to jẹ ọmọ bibi gbajugbaja oṣere to ti di oloogbe, Funmi Martins ti sọrọ sita lori ọrọ kan to gbalẹ kan lori ayelujara nipa ọrọ ọmọ ti awọn eeyan n sọ pe o wa laarin oloogbe ọhun ati gbajugbaja olorin Juju, Sir Shina Peters.

Mide to ti dakẹ lati ọjọ yii plu bi iroyin ọhun ṣe n fo kaakiri ni oun kan fẹ sọ kekere nipa rẹ ni lati iha oun.

Ọ̀rọ̀ to ṣẹlẹ gangan ni pe laipẹ ati di isinsiyii, ori ayelujara n gbona giri giri lori ọrọ gbajugbaja akọrin Juju, Sir Shina Peters ti wọn fẹsun kan pe ko nanii ọmọkunrin kan ti oṣere tiata tẹlẹ to ti di oloogbe bayii Funmi Martins bi fun un.

Amọ iwadii tuntun taa tun ri nipa iku oloogbe Gunmi Martins ree:

Àkọlé fídíò, Ọkọ mi bá àwọn ọmọ wa sọ̀rọ̀ lágo kan kó tó wọ bàálù tó já, àmọ háà! - Ìyàwó Olasunkanmi Olawunmi

Mide to ṣe bi ẹni n woye ohun to n lọ tẹlẹ kọkọ tọrọ aforiji lọwọ gbogbo awọn to lero pe oun ti ṣẹ tabi doju ti lori ọrọ naa.

"Mi o fẹ sọ ohunkohun tẹlẹ nipa ọrọ yii lati igba to ti bẹrẹ nitori mo gbagbọ pe ọrọ aarin mọlẹbi ni to yẹ ka yanju ni alafia laarin ara wa ju ki wọn maa gba a bi ẹni n gba igba ti lori ayelujara lọ".

Mide Funmi Martins ni ẹni to ba mọ oun daadaa maa mọ pe alaṣiri ni oun, oun ko si fẹran lati maa gbe nkan rẹpẹtẹ tabi ṣafihan ayẹyẹ lori ayelujara to ba ti nii ṣe pẹlu ẹbi oun

"Bii ti ayẹyẹ iranti ti mo maa n ṣe fun mama mi oloogbe lọdọọdun ni ibọwọ fun wọn".

Mide ni "ni ọdun mọkandilogun sẹyin ti mama mi faye silẹ, gbogbo aye mi lo tuka to polukurumusu ti mo si di ẹni adanikan gbe, ronu, huwa, sọrọ lai si atilẹyin nikẹni".

O ni bi oun ṣe ṣe e ti oun ru u la ko ṣẹyin oreọfẹ Ọlọrun nikanṣoṣo.

Àkọlé fídíò, Gẹ́gẹ́ bí àṣà, mo ti mọ̀ tipẹ́ pé mo máa jẹ ọba Akinghare II - Oba Oloyede

"Damilare n gbe pẹlu iya-iyaa mi nigba naa niluu Abeokuta, mo si n ṣe gbogbo nkan ti mo le ṣe lati tọju rẹ afi to di dun diẹ sẹyin ti iya - iya mi naa dagbere faye ti wọn si gbe Damilare lọ si ọdọ ẹgbọn mama wa lati lọ gbe nibẹ".

Oju opo Gistloverupdate to fi si ọrọ naa sori ayelujara ṣalaye pe olorin Juju Sina Peters ko beere ọmọkunrin yii, Damilare lati igba ti mama rẹ Funmi ti jade laye.

Mide ni oun ti bere titi titi lọpẹ igba pe ki wọn fun oun ni Damilare lati maa tọ ki mama agba to ku ṣugbọn wọn ko gba.

"Ẹjẹ mi ni Damilare, mi o si lee pa a ti amọ ohun to pọ ni ẹ ko m nipa ọrọ yii".

Mide ni oun tọrọ aforiji pe oun ko ni le kẹnu bọ ọrọ naa lẹkunrẹrẹ tori ọrọ mọlẹbi ni.

"Mi o ki n ṣe alaburu ẹda, bo tilẹ jẹ wipe mi o ni i tan amọ iwọnba ti mo ni, mo n fi gbogbo ọkan mi fi silẹ.

Ẹwẹ, Mide Martins ni ẹbẹ kan loun fẹ bẹ pe "ṣe ẹ le fun mi ni aburo mi? Mo ẹleri lati tọju rẹ niwọnba ti mo lagbara ki Ọlọrun si ran mi lọwọ".