Fight against corruption: Ọ̀rọ̀ Satguru Maharaj ji sí àwọn olóṣèlú Nàìjíríà lórí ìwà àjẹbánu

Satguru Maharaj ji ati Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahamad

Oludasilẹ ijọ One Love Family, Satguru Maharaj ji ti ja gudugbẹ ọrọ lulẹ lori ọrọ igbogun ti iwa ajẹbanu lorilẹede Naijiria.

Guru Maharaj ji woye pe asiko ti to fawọn oloṣelu lati maa ṣe ibura lọna ẹsin abalaye nigba ti wọn ba n ṣe ifilọlẹ ijọba wọn.

O ni bibura pẹlu Ogun, Sango ati Ifa lo le jẹ ki iwa ajẹbanu to gbode kan ni Naijiria di ohun igbagbe.

Guru Maharaj ji sọrọ yii nibi apero kan to da lori awọn iṣẹlẹ to n ṣakoba fun gbogbo agbaye ni lọọlọ yii lọjọ Abamẹta.

''Awọn eeyan n bura pẹlu Bibeli ati Quoran, ṣugbọn wọn n kowo ilu jẹ, ohun kan ko si ṣẹlẹ si wọn.

Iwa ọdaran yii si ti ṣe akoba nla fun ọpọ idile ati ileeṣẹ.

Amọ, to ba jẹ pe Ogun tabi Sango ni wọn fi n bura ni, ọpọ eeyan ni ko ni maa kowo ilu jẹ,'' Guru Maharaj ji lo woye bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Ẹ̀yin olórin ẹ̀mí tó ń bóra, lo èékáná gígùn, oò yàtọ̀ sí aṣẹ́wó hòtẹ́ẹ̀lì tí wọ́n ń gbé bíi súùtì Pepper Menti - Bola Are

Olori ijọ One Love Family ni awọn eeyan ti fi orisun silẹ nibi ti gbogbo nkan ti bẹrẹ ati ibi ti otitọ ati ododo wa.

O rọ ijọba lati gbe ọrọ ibura pẹlu Ogun, Sango ati Ifa wo, o ni ọna kan gboogi tawọn ''baba wa'' gbe kalẹ niyii lati maa wa ojutu si ohunkohun to ba ruju.

Guru Maharaj ji fikun ọrọ rẹ pe ibura lọna ẹsin ibilẹ yoo jẹ ki awọn olori maa ṣe ijọba daradara nitori ibẹru ibinu Ogun tabi Sango yoo wa lọkan wọn.

O ni ''a nilo nkan ti yoo maa ka wa lọwọ kọ lori iwa ibajẹ lawujọ.''