Mide Funmi Martins: Wo ohun tí a mọ̀ nípa ikú oṣèré Funmi Martins tí ọ̀rọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú Shina Peters wú síta

Oríṣun àwòrán, Mydemartins
Oku ọmọde ni ọpọlọpọ awọn ololufẹ fiimu Yoruba ka a si nigba ti gbajugbaja oṣere Funmi Martins dagbere faye pẹlu awn iroyin to yi i ka nigba naa.
Ọmọde, ọmọ ọdun mẹtalelogun ṣi ni Mide ọmọ rẹ, bẹẹ si ni iroyin sọ pe ko ju oṣu meji lọ to ṣẹṣẹ bi abigbẹyin rẹ Damilare fun gbajugbaja olorin Juju, Sir Shina Peters.
Kí ló ṣekú pa gbajúgbajà òṣèré Funmi Martins ìyá Mide-Martins lẹ́ni ọdún 38?
O ti pe ọdun mọkandinlogun ti gbajugbaja oṣere Funmi Martins jade laye ni ẹni ọdun mejidinlogoji.
Eyi ni awọn ohun ti a mọ nipa iku rẹ to jẹ ibanujẹ fun awọn ololufẹ rẹ nigba naa lọhun titi di asiko yii.
Ko si ẹni to lee sọ wi pe Funmi Martins yoo ku ni kekere nitori o jẹ obinrin to ja fafa to sitẹra mọ iṣẹ rẹ nigba aye re.
- Kí ni ìtumọ̀ pé Mide Funmi Martins kò sí níbi tí Damilare àti Shina Peters ti parí ìjà?
- Lọ́jọ́ tí wọ́n fẹ́ bí Damilare, ǹkan fẹ́ wọ́lẹ̀, kò sí bàbá nílé àmọ́ ... - "Uncle" Damilare Funmi Martins
- Mo ń ṣe ẹ̀tọ́ mi fún Damilare lọ́dọ̀ màmá àgbà, àmọ́ ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí ló pọ̀ - Mide-Funmi Martins
- Shina Peters dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn abiyamọ ayé lórí ọ̀rọ̀ ọmọ tí Funmi Martins bí kó tó papòdà
- Gbajúgbajà akọrin jùjú, Shina Peters jẹ oyè Bíṣọ́ọ̀bù Ìjọ Cherubim àti Seraphim
- Ó ti tó àsìkò kí Nollywood fòpin sí èré ilé babaláwo lílọ - Clarion Chukwura
- Glaucoma lè fọ́ gbogbo ènìyàn lójú tán níbí - Dókìtà Nàìjírìà
- Òní ni ìsìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja
Fiimu akọkọ to ti kopa jẹ elede oyinbo "Nemesis" lọdun 1993. Lara awọn fiimu mii to ti kopa ni Eto Mi, Pelumi, Eru Eleru ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Fiimu Yoruba to ti kọkọ jade latọwọ eekan oṣere, Adebayo Salami ti ọpọ mọ si Oga Bello.
Ẹwa Funmi Martins ko ṣee foju fo laarin awọn ololufẹ rẹ koda to fi mọ awọn akẹgbẹ rẹ ti wọn a maa wa lati kopa ninu ere wọn.
Iroyin sọ pe oṣere to ko ọpọlọpọ eeyan mọra lo jẹ nigba aye rẹ. Lasiko iku rẹ kan naa ni agbo oṣere Naijiria tun padanu gbajugbaja to mọ iṣẹ bii tirẹ mii, Adebimpe Adekola ti wọn mọ si Ireti lọdun 2002 kan naa.
Ọdun arelu lọdun naa jẹ lagbo oṣere gẹgẹ bi wọn ṣe padanu ọpọ akẹgbẹ wọn sọwọ iku.
Ki o to di wi pe o papoda, Funmi Martins si n kopa ninu fiimu rẹ to fẹ gbe jade, "Aduro Ti Oluwa".
Bakan naa ni awọn eniyan ri i pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ ni ita gbangba ko to di wi pe o jẹ Olorun nipe.
Tani Funmi Martins?

Oríṣun àwòrán, Mide Martins
Funmi Martin jẹ ilumọọka ninu awọn to n ṣe ere Yoruba ni nkan bi ọdun mọkandinlogun ṣẹyin.
Oṣu Kẹsan, ọdun 1963 ni wọn bi ni ilu Ilesa, nipinlẹ Osun gẹgẹ bi Funmi Oguntomi, to si dagba ni ilu Ibadan ati ilu Eko.
Ki o to bẹrẹ iṣẹ oṣere ni o ti n ṣiṣẹ arinrinoge, lẹyin naa lo bẹrẹ iṣẹ oṣere ni ọdun 1993.
Ohun lo bi gbajugbaja oṣere to ti di ilumọọka laarin awọn akẹgbẹ rẹ lonii, Mide Martins toun naa fi orukọ iya rẹ sinu orukọ lẹyin iku rẹ ki wọn lee tete mọ ọ ninu ere "Mide-Funmi Martins".

Oríṣun àwòrán, Mydemartins
Lẹyin rẹ lo bi abigbẹyin rẹ ti o jẹ eso ere ifẹ laarin oun ati gbajugbaja olorin Shina Peters.
Iroyin kan sọ pe
Ere akọkọ to kopa ninu rẹ ni 'Nemesis' ti Fidelis Duker ṣe adari fun.
Awọn fiimu miran to kopa ninu rẹ ni 'Ẹtọ mi, Pẹlumi, Ija Ọmọde, Ẹru Ẹlẹru ati awọn fiimu agbelewo miran.
Ki lo pa gbajugbaja oṣere Funmi Martins, iya Mide-Martins?

Oríṣun àwòrán, Mide/Funmi Martins
Ni Ọjọ Karun, Oṣu Karun un , ọdun 2002 ni oṣerebinrin Funmi Martins naa bẹrẹ si ni ṣe aarẹ ni ile rẹ ni agbegbe Iju Ishaga.
Iroyin ni Funmi sọ wi pe ara oun ko ya, ti wọn si gbe e lọ si ileewosan ni Iju nipinl Ogun.
Lẹyin akoko diẹ ni ara rẹ balẹ, ti wọn si ni o fun ọmọ rẹ jojolo ni ọyan mu.
Amọ ni Ọjọ Keji, Ọjọ Kẹfa, Oṣu Karun un, ọdun 2002 ni Funmi ku iku ojiji ni ileewosan Oshuntuyi ni ipinlẹ Eko.
Ọmọ ọ̣dun mejidinlogoji ni Funmi Martins ni asiko naa.
Gẹgẹ bi awọn dokita ṣe sọ, iku ojiji rẹ ko ṣẹyin aisan ọkan ( cardiac arrest) to dede gbẹmi rẹ.
Amọ iroyin nipe awọn akẹgbẹ rẹ ati awọn ọrẹ rẹ Gbagbo wi pe iku rẹ kii ṣe oju lasan, ati wi pe ejo iku rẹ ni ọwọ ninu, amọ ako le fi idi rẹ mulẹ.



















