Sir Shina Peters: Gbajúgbajà akọrin jùjú, Afro Juju Shina Peters jẹ oyè Bíṣọ́ọ̀bù Ìjọ Cherubim àti Seraphim

Shina Peters

Oríṣun àwòrán, Shina Peters/ Instagram

Gbajugbaja olorin Afro-Juju, Sir Shina Peters ti da Bisọọbu Ijọ Cherubim ati Seraphim.

Akọrin to lamilaaka naa lawujọ ni wọn ṣe ayẹyẹ bisọọbu ijọ Cherubim ati Seraphim fun ni agbegbe Iju ni ipinlẹ Eko.

Akọrin ọun lo fi fidio lede ati aworan ni oju opo Instagram rẹ ni Ọjọ Isinmi pẹlu akọlẹ pe ''bisọọbu to yatọ ni oun ati wi pe Ọlọrun ni agba gbogbo nkan ''.

Bakan naa ni oju opo Facebook rẹ ni akọrin naa ti kọ si bẹ pẹ'' Ọlọrun lo ni gbogbo ogo. Olorun ni ma a sin titi de opin''

Nibayii, ẹbi ati ara pẹlu awọn ọrẹ ni wọn ti n kii ku oriire loju opo ikansiraẹni rẹ, ti wọn si n dupẹ lọwọ Olorun wi pe o ti kọ esu silẹ ati iṣẹ ọwọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Laipẹ yii ni o gbe awo orin ti o ṣe pẹlu Teni, to si pe akle rẹ ni ''Jo'', eleyii ti wọn gbe jade ni Oṣu Kejila, ọdun 2020.

SSP gẹgẹ bi orukọ ti awọn eniyan ma n pe e ni o gbe awo orin rẹ akọkọ jade ni ọdun 1989 pẹlu awo orin (Afro-Juju Series 1).

Orin rẹ 'Shinamania' to gbe jade ni ọdun 1991 naa gba ami ẹyẹ mẹta nitori o ta kaakiri jale-jako ni, to si ni ṣe awo orin mẹtala lati igba to ti bẹrẹ orin kikọ.

Àkọlé fídíò, Mckinley Erves di ẹni tọ ń ríran rí aàwọ̀ nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀