Sex benefits: Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìbálọ̀pọ̀ pẹ̀lú aya tàbí ọkọ rẹ lè jẹ́ kí o dàbí ọmọdé?

Awọn dokita onimọ nipa ibalopọ tun sọ pe ibalopọ maa n ran tọkọ taya lati gbaradi fun ipenija.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Dokita onimọ sayẹnsi nipa ihuwa ẹda ati ọpọlọ eeyan kan to jẹ ọmọ orilẹede Scotland ti sọ ninu awọn iwadii to ṣe wipe nini ibalopọ gbigbona maa n jẹ ki ara eeyan da bi ara ọmọde.

Dokita David Weeks ati onkọwe nipa sayẹnsi, Jamie James ṣe ifọrọwerọ pẹlu eeyan marundinlọgọrun lorilẹede Scotland ti oju wọn kere ju ọjọ ori wọn lọ.

Dokita Weeks ati onkọwe James fẹnu ko pe ibalopọ ti wọn ti ni sẹyin ni aṣiri bi wọn ṣe kere ju ọjọ ori wọn lọ loju.

Dokita Weeks sọ ninu esi iwadii rẹ pe oju lọkọ laya to ba n ni ibalopọ lẹẹmẹta laarin ọsẹ maa fi bi ọdun mẹwaa kere ju ọjọ ori wọn lọ.

''Igbadun to wa ninu ibalopọ jẹ ọkan gbogi lara ohun to le jẹ ki eeyan kere loju ju ọjọ ori rẹ lọ,'' Dokita Weeks ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Wàhálà ni dídá ọ̀pọ fásítì síll n fà

O ni ọpọ awọn ilumọọka ti oju wọn n dan ju ọjọ ori wọn lọ lo n gbadun ibasun pẹlu ọkọ tabi iyawo wọn.

Dokita Weeks ṣalaye pe ọpọ lọkọ laya lo n jẹ anfaani nla yii to wa ninu ibalopọ.

Ọ̀kùnrin àti obìnrin

''Ibasun ni igbadun to gbojigan julọ, ohun lo si maa n fa wiwa awọn kẹmika kan lasiko ibasun eyi to maa n ṣe ara loore,'' Dokita Weeks lo sọ bẹẹ.

Weeks ni ṣiṣe ere idaraya lo kọkọ ṣe pataki lati jẹ ki eeyan kere ju ọjọ ori rẹ lọ, lẹyin naa lo ku ibasun.

Iwadii Dokita Weeks tun fihan pe awọn ti oju wọn ba ri bi ọmọde maa n ni igboya, ori wọn si maa n pe pere pere.

O sọ ninu iṣẹ iwadii rẹ pe awọn iwa to maa n mu kawọn eeyan tete gbo ni siga mimu, wahala ṣiṣe ati wiwa ninu oorun.

Àkọlé fídíò, Tóò bá fún ọkùnrinn lóúnjẹ́ tóo tẹ́ kiní yẹn sílẹ̀ fún un dáadáa... - Yinka TNT

Amọ, Dokita Weeks sọ pe ibalopọ laarin lọkọ laya lo ni iru anfaani gidi yii ninu.

O ni kii ṣe awọn eeyan to ba n ni ibalopọ pẹlu irufẹ ẹnikẹni ti wọn ba kan ri nita.

Àkọlé fídíò, Mistura Asunmo, Iya 2D:1959 ni mo bẹ̀rẹ̀ eré ṣùgbọ́n ń kò ní ọkọ̀ ẹyọ kan di ìsìnyí