sign post ban: Ẹnikẹ́ni tó ń lo pátákó alákọ̀ọ́lé "No parking" ń fi gbaga òfin ṣeré - Ọlọ́pàá Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ko si ẹnikẹni to l'asẹ lati gbe patako ti wọn kọ "No parking si lara" lai jẹ wi pe ọlopaa mọ sii.
Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Ọmọọba Olumuyiwa Adejọbi lo sọ eyi loju opo ayelujara Twitter rẹ.
O ni ko ba ofin mu rara ati rara ni ki eeyan lọ funrararẹ tẹ akọle "No parking" to tumọ si "Maṣe gbe ọkọ sibi yii" le ori patako maa gbe si oju popo lai a si wi pe olopaa fi aṣẹ sii.
- 'Inú ewu ńlá ni gbogbo àgbáyé wà báyìí lórí ọ̀rọ̀ àyípadà ojú ọjọ́'
- Adedoyin àti afurasí yókù ní àwọn kó jẹ̀bi ẹ̀sùn ípànìyàn tí iléẹjọ́ fí kàn wọn
- World Cup 22- Àwọn ọ̀nà àrà láti mú pápá ìṣeré tutù ní ìlú aṣálẹ̀
- Bayo Adelabu ké sí gómìnà Seyi Makinde kọ̀wé fipò sílẹ̀ nítorí ìkùnà ìjọba rẹ̀
- Ọlọ́pàá mú ọkùnrin tó d-áná sun ọmọ ìyàwó rẹ̀ márùn-ún ní Ondo
- D-ino Melaye àti Peter Obi gbéná wojú ara wọn níbí ìtàkurọ̀sọ àwọn olùdíjé sípò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, @Adejobi
Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria naa sọ pe:
Ọmọọba Adejọbi n fesi si ọrọ kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, SP Ọkasanmi sọ si ipe ti awọn ọmọ Naijiria kan fi ranṣẹ si oju opo Twitter rẹ ni pe n ṣe lawọn eeyan kan n gbe patako " No parking" kaakiri gbogbo adugbo, lai naani ilana lamẹetọ.

Oríṣun àwòrán, @Adejobi
Igbeṣẹ wo nileeṣẹ ọlọpaa fẹ gbe bayii?
Ọkasanmi seleri ati wo ọrọ naa loju opo Twitter rẹ ni alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Olumuyiwa Adejọbi fi gba a lẹnu rẹ pe ko ma tilẹ laagun jina.

Oríṣun àwòrán, @Others
Ko si ẹnikẹni to lẹtọ si eyi lai jẹ pe oga ọlọpaa ijọba ibilẹ naa, ti ẹkun naa, tabi kọmiṣọna ọlọpaa fun un laṣẹ lati ṣe bẹẹ.
O wa fi kun un pe ẹnikẹni ti wọn ba ba to n ṣe bẹẹ yoo pẹ ni gbaga ofin.
Nigba ti awọn eeyan kan tilẹ tun fesi lori Twitter pe ọpọ awọn ile ijọsin lo n lo o, CSP Adejọbi ni o yẹ ki ọga ọlọpaa DPO awọn agbegbe bẹẹ tete gbe igbesẹ lori rẹ ki eredi ti wọn fi gbe e silẹ ma baa ja si asan.
Ọmọọba Adejọbi tun rọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara lati tete ṣe ayẹwo gbogbo to ba yẹ lori rẹ ki o to di pe awọn eeyan tun sọ ọ di taja-teran gẹgẹ bi ti fere Sire .













