Dino Melaye àti Peter Obi gbéná wojú ara wọn níbí ìtàkurọ̀sọ àwọn olùdíjé sípò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, Others
Oriṣiriṣi awuyewuye lo ti n waye lẹyin ti oludije fun ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Bola Ahmed Tinubu ko kopa nibi itakurọsọ kan to waye ni ọjọ Aiku.
Oludije lati inu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar naa ko yọju sibẹ.
Ajọ kan to n polongo ijọba awaarawa ati idagbasoke, Centre for Democracy and Development (CDD), pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ iroyin Arise News lo ṣeto itakurọsọ ita gbangba ọhun lati mu ki awọn oludije fun ipo aarẹ ninu eto idibo gbogboogbo Naijiria ti yoo waye lọdun 2023.
Awọn oludije to kopa nibẹ ni Peter Obi ti ẹgbẹ osẹlu Labour, Rabiu Kwankwaso ti ẹgbẹ New Nigerian People’s Party (NNPP) ati Kola Abiola, ti ẹgbẹ osẹlu People’s Redemption Party (PRP).
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ko si ofin to pa a ni dandan fun awọn oludije lati kopa nibi iru ipade bẹẹ, ni awọn kan n sọ pe iwa afojudi ni awọn oludije ti ko kopa hì si awọn ọmọ Naijiria.
Botilẹ jẹ pe igbakeji Atiku, Gomina Ifeanyi Okowa ṣoju rẹ nibẹ, awọn olukopa kan nibi eto naa tako Okowa.
Niṣe ni wọn mu ariwo bọ ẹnu pe oludije sipo aarẹ nikan ni awọn fẹ ko ba wọn sọrọ.
Melaye ati Obi tahun si ara wọn
Lara nkan to tun waye nibi ipade ita gbangba naa ni bi oludije ẹgbẹ oṣelu Labour ati ọmọ ẹgbẹ osẹlu PDP kan, Sẹnetọ Dino Melaye ṣe tahun si ara wọn.
Eyi waye lasiko ti Melaye sọ ọrọ pe awọn alatilẹyin Obi nikan lo ti gba akoso asiko ibeere nini itakurọsọ naa.
Ọkunrin kan lo dide lati beere ibeere lọwọ awọn oludije, amọ niṣe ni Dino Melaye sọrọ ni ede Pidgin pe “o ga o, awọn eniyan Obi”.
Bi Sẹnetọ Melaye ṣe sọ ọrọ yii, ni Peter Obi dahun pẹlu ibinu, to si na ìka si i pe oun ko ni gba igbakugba bẹẹ lọwọ rẹ.
“Ma ṣe bẹẹ mọ Dino, oriṣiriṣi iwọsi ni mo ti gba lati ọdọ rẹ. Kini nkan ti o fẹ? Kilode to ma n pe orukọ ni ni gbogbo igba?”
Peter Obi ṣalaye pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu ANPP ni ẹni to dide lati beere ibeere, amọ ti Dino pe e ni “awọn eeyan Obi”.
Iṣẹlẹ yii tun wa lara nkan to n fa ariyanjiyan lori ayelujara bayii.








