Tinubu fí MC Oluomo sínú ìgbìmọ̀ ìpolongo ìdìbò Ààrẹ
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
MC Oluomo: Màá ṣiṣẹ́ kára láti rí pé Tinubu, tó jẹ́ olóore àti alátìlẹyìn mi borí ìbò ààrẹ

Oríṣun àwòrán, kingmcoluomo/Instagram
Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti fi orukọ alaga igbimọ alamojuto gareeji ọkọ nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti ọpọlọpọ mọ si MC Oluomo, sinu igbimọ ipolongo ibo aarẹ lọdun 2023.
MC Oluomo kede ọrọ naa loju opo ayelujara Instagram rẹ lẹyin to tẹwọgba iwe ipe ti akọwe igbimọ, James Falake bu wọlu .
Oluomo ni pẹlu idunu ati ayo ni oun fi gba iwe ipe naa lati jẹ ọkan lara igbimọ ti yoo sisẹ pọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu APC lati ri pe wọn ṣe aṣeyori ninu eto idibo aarẹ lọdun 2023.
“Mo gba lẹta lati jẹ ọkan lara awọn igbimọ to n ṣe agbatẹru ipolongo ibo aarẹ ẹgbẹ oṣelu APC.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
“Pẹlu idunu ati ayọ ni mo fi dupẹ lọwọ awọn alasẹ ati awọn adari ẹgbẹ oṣelu APC fun bi wọn se ka mi yẹ yii.
Mo si n ṣe ileri fun yin pe ma a sisẹ karakara lati ri pe oludije wa, to jẹ oloore ati baba isalẹ mi, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ṣe aṣeyori.
“Mo ti pinu ọkan mi, ma a si sa gbogbo ipa mi ni ọna to ba ofin mu lati mu ileri ẹgbẹ wa si imusẹ.
“Mo wa n rọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC lati fọwọsowọpọ pẹlu gbogbo oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ka le jọ ṣe aṣeyori.”















