Àlàyé rèé lórí ohun tó wáyé láàrin èmi àtàwọn DSS lọ́jọ́ tí wọn ká mí mọ́lé lóru mọ́jú - Sunday Igboho

Tí mo bá padà dé láìpẹ́, n kò fẹ́ rí agbébọn kankan nilẹ Yoruba – Igboho

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti sọ pe oun yoo pada si Najiria laipẹ.

Igboho ni oun si gbagbọ pe ọpọ awọn ololufẹ oun ni yoo ki oun kaabọ ti oun ba pada de.

Igboho lo sọ ọrọ naa niluu Cotonu lasiko to gba oye ọmọwe, eyii ti ile ẹkọ Triune Biblical University fi da lọla.

O ni inu oun dun pe awọn ọmọ Yoruba gbaruku ti oun lasiko idojukọ ti oun ni.

O ni ni paapaa julọ, lasiko ti ijọba Naijiria gbiyanju lati fi panpẹ mu oun loru ganjọ.

"Awọn DSS to wa sile mi loru mọ pe awọn ba mi nile, wọn si ri mi soju, a ri ara wa.”

Lasiko to n ṣalaye ohun to ṣẹlẹ lọjọ ti DSS kọlu ile rẹ, Igboho ni “Ọlọrun lo yọ mi ninu ile lọjọ yẹn, nitori awọn to wa sile mi mọ pe awọn ba mi nile, wọn si ri mi soju, a ri ara wa.”

“Ọlọrun sọ fun mi pe ki n ma bẹru eeyan amọ ki n bẹru oun Ọlọrun... lo jẹ ko gbe mi jade ninu ile ni irọrun.”

“O yẹ ki agbara wọn ka mi lọjọ yẹn, aago kan abọ oru ni wọn de.”

“Nigba to ku bii ọgbọn iṣẹju ki wọn de, ni Ọlọrun ta mi ji, o ni ki n dide pe awọn kan n bọ.

Oorun ko wa kun mi mọ titi ti wọn fi de. Ṣe ẹ ri pe alagbara ni Ọlọrun.”

Àkọlé fídíò, Àwọn olólùfẹ́ Igboho rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba Benin láti túu sílẹ̀,

"Mi o ṣeṣe lasiko ikọlu DSS, ofege iroyin lawn eeyan kan n gbe kiri"

Nigba to n salaye ọrọ kan to ni o fara pa lasiko ti DSS kọlu ile rẹ, Igboho sọ pe oun ko ṣeṣe gẹgẹ tako awọn iroyin kan.

O ni “Ọpọlọpọ ni Ọlọrun fi ọrọ mi ru loju, awọn kan ni nigba ti wọn ka mọle, o bẹ nikun, o kan lẹsẹ, o fo ori ogiri.”

“Ikun mi ko bẹ, nnkankan ko si ṣe ikun mi, bẹẹ si ni ẹsẹ mi ko kan.”

Lẹyin naa lo ṣi aṣọ rẹ soke lati fi ikun rẹ han awọn eeyan to pejọ sibi to ti n sọ ọrọ naa lati fi han pe lootọ oun ko farapa.

O tẹsiwaju pe inu oun dun pe ọrọ ti oun sọ pe Yoruba gbọdọ gba ominira ti n ye awọn eeyan ti ọrọ naa ko ye ṣaaju.

"Mo n pada bọ ni Naijiria laipẹ, n ko si fẹ ri ba agbebọn kankan nilẹ Yoruba

Igboho tẹsiwaju pe bo tilẹ jẹ pe mọja mọsa ni wọn n mọ akinkaju loju ogun, oun ṣi n pada bọ ni Naijiria laipẹ.

O ni oun ko si fẹ ri awọn agbebọn darandaran kankan ti oun ba de.

O ni “Inu mi dun pe Ọlọrun ti fẹ mu Yoruba kuro loko ẹru ijọba Naijiria.”

“Laṣẹ Ọlọrun, emi n bọ nile pada, gbogbo agbara ti Naijiria ba ni ki wọn ko de mi.”

“Mo ni igbagbọ pe ọjọ ti mo ba gbe ẹsẹ mi pe ile ya, gbogbo awọn ọmọ Yoruba to fẹran mi lo maa pade mi lọjọ naa.”

Mo n bọ pẹlu aṣẹ Ọlọrun ati aṣẹ awọn baba mi... lati wa beere fun ẹtọ wa nitori ipakupa ti awọn agbebọn n pa wa nilẹ Yoruba ti to gẹẹ, a ki n ṣe ẹru wọn.”

“Gbogbo agbebọn darandaran to wa n bẹ nilẹ Yoruba, mo n bẹ yin, ẹ dakun, ẹ ma jẹ ki n ba yin nile.”

Igboho pari ọrẹ pe inu oun dun fun oye ọjọgbọn ti Triune Biblical University fi da oun lọla,

Lẹyin naa lo ṣadura fun awọn eeyan to wa nibi ipejọ naa.

Àkọlé fídíò, Hospital staff removes flesf of corpse