'Àgbà ló ń ṣe Fasoranti, tó bá yá yóò ronúpìwàdà'

Adebanjo ati Fasoranti

Oríṣun àwòrán, OTHERS

"Agba lo n ṣe Alagba Faṣọranti, to ba ya yoo ronupiwada."

Eyi lọrọ ti ọkan lara awọn agba to n ja du ipo adari ẹgbẹ Afẹnifẹre, Alagba Ayọ Adebanjọ sọ nipa ede aiyede to n waye laarin awọn agbaagba mejeeji yii eyi to ti mu ki ọpọ maa gboju soke pe ki lo n ṣẹlẹ.

Wahala to n suyọ laarin ẹgbẹ afẹnifẹre lorii tani ẹgbẹ duro ti ninu awọn oludije fun ipo aarẹ eyi to n ṣebi ẹni ti pin ẹgbẹ naa si meji bayii n fojojumọ fẹju tantan ni.

Awọn agbaagba meji ninu ẹgbẹ naa yapa si ara wọn lori ẹni ti wọn n gbe ti lẹyin: Ayọ Adebanjọ ni Peter Obi, ti Labour loun n tẹle, nigba ti Rueben Faṣọranti n sọ pe Tinubu ni oun n tẹle.

Baba Fasọranti naa sọrọ lẹyin ipade oun atawọn agbaagba ilẹ Yoruba lati awọn ipinlẹ bii Ọyọ ogun, Ondo, Ekiti, Ọṣun, Eko, Kogi ati Kwara pe oun ṣi ni Olori ẹgbẹ naa ati pe oun ti yọ Adebanjọ kuro nipo adele ti oun fi si.

Agba lo n ṣe Alagba Faṣọranti, to ba ya yoo ronupiwada - Ayo Adebanjo

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Baba Ayọ Adebanjọ sọ pe ala ti ko lee ṣẹ ni baba Faṣọranti n rawọle nitori pe ko ni aṣẹ bẹẹ lati yọ oun nipo ati pe ohun gbogbo to ba sọ, o sọ ọ si apo ara rẹ ni, ko lee fi idi mulẹ.

Ko si nnkankan to da afẹnifẹre duro. O dabi ẹnipe agba lo n ṣe Ọgbẹni Faṣọranti. Mo mọ pe wọn a ba a sọrọ, ko si nnkan to ṣe e. Ẹyin ni oun ti fi iṣẹ silẹ pe oun ti fi iṣẹ le mi lọwọ. Wọn kan fẹ da ariyanjiyan silẹ ni, mi o dẹ ni ba wọn fọwọ sii.

“mi o ka ọrọ wọnyẹn si o. Agba lo n ṣe e, to ba ya a ronupiwada, a o ma ba iṣẹ wa lọ.

Ki ni awọn agbaagba ilẹ Yoruba n sọ bayii?

Awade lo n ṣe Adebanjọ ati Fasọranti- Yẹmi Farounbi

Ninu ọrọ tirẹ, eekan agbohunsafẹfẹ, Oloye Yẹmi Farounbi ṣalaye pe ohun to tabuku ba ilẹ Yoruba patapata gbaa ni ohun ti wọn n ṣe yii ati pe ko yẹ ko jẹ awọn agbaagba to yẹ ki wọn maa ko awọn ọmọde lọba fun ibawi lo n ṣe ohun ibawi.

Oloye Yẹmi Farounbi ṣalaye pe ati isalẹ lọrọ Afẹnifẹre ti wọ wa, eso rẹ laye n ri loke ni. O ni akọkọ ni pe ẹgbẹ Afẹnifẹre gbọdọ kọkọ ṣe atunto ara rẹ kuro ni iduro rẹ gẹgẹ bi ẹgbẹ to dirọ mọ igun oṣelu kan ki o bọ si ẹgbẹ to jẹ aburada fun gbogbo ọmọ Yoruba laifi ti ẹsin tabi oṣelu ṣe bi awọn akẹgbẹ rẹ biiOhaneze ni ẹya igbo ati Arewa Consultative Forum, ACF fun awọn ẹya apa oke ọya Naijiria.

“Nigba ti wọn ba ti n ri ara wọn gẹgẹ bi ẹgbẹ oloṣelu, ko si igba ti iru nnkan bayii ko ni maa ṣẹlẹ. Ohun ti Yoruba nilo bayii ni ẹgbẹ kan ti yoo daabo bo gbogbo Yoruba, ti yoo maa wa ilọsiwaju, igbega Yoruba, laifi ti ẹgbẹ bọọ. Iru ẹgbẹ ti a nilo niyi. A ko ni eyi. Awọn nnkan to n fa iṣoro to wa nilẹ niyẹn.”

Yẹmi Farounbi

Oríṣun àwòrán, other

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa lo fi kun un pe ọrọ ti ara awọn mejeeji ni wọn n du kii ṣe ti gbogbo ọmọ Yoruba lapapọ.

"Loṣelu nnkan to ba jẹ ti gbogbo wa ẹnikan kii sọ pe awade nibẹ. Ati ẹni kini ati ẹnikeji awade ni wọn n ṣe. Ati ẹnikini ati ẹnikeji, ko ẹni to wo kini ọhun pe ki ni yoo mu wa fun ilẹ Yoruba. To ba jẹ pe a maa wo bi o ṣe pe ilẹ Yoruba, o yẹ ka pe gbogbo awọn to ba n dije ni. Wọn a wa ba wa sọrọ, aa mu wọn lohun. Lẹyin igba yẹn, aa wa joko pe eleyi lo pe wa ju niyi. Ṣugbọn bi o ṣe ri yii kaluku n ṣe konko jabele ni ti ko si daa fun ọdun 2023 ti a fẹ dibo ati fun ilẹ Yoruba. Bi mo ṣe n woo yii, ati tu Afẹnifẹre to pada yoo fẹ nira pupọ.”

Alagba Farounbi ni nibi ti ọrọ de duro bayii, o ti han gbangba pe atunto yẹ ko de ba yiyan olori lẹgbẹ Afẹnifẹre lati fun awọn ọdọ lanfani ati dari ẹgbẹ naa nigba ti awọn agba yoo ma wa nikalẹ lati maa tọ wọn sọna bọrọ ba ruju.

O ni nigba to jẹ pe awọn agba to yẹ ka fọrọ lọ tọrọ ba ruju naa lo bọ si gbagede ọja lati ja bayii, afi ka ke sawọn ọbalaye gbogbo nilẹ Yoruba lati pe awọn agba mejeeji lati pari aawọ aarin wọn.

Ko le ṣai ri bayii nitori pe lati ipilẹ ni Afẹnifẹre ti lọrọ Oṣelu ninu - Adajọfẹyinti Ademọla Bakre

Ninu ọrọ tirẹ Adajọfẹyinti Ademọla Bakre to jẹ eekan lẹgbẹ agba ilẹ Yoruba, YCE sọ peohun kii fẹ da si oṣelu nitori naa oun ko ni da si ọrọ Afẹnifẹre nitori pe lati ipilẹ ni wọn ti jẹ ẹgbẹ to suyọ lati inu oṣelu wa, iyẹn ẹgbẹ Action group.

Adari igbimọ agbaagba Yoruba, YCE tẹlẹ naa ni ohun ti ko ṣee maa gbọ ni pe awọn ti a pe ni agba nilẹ Yoruba n ja ita lẹnu awọn akọroyin lo ti jade.

O ni awọn agbaagba mejeeji yii lo nilo lati fi suuru si ọrọ naa.

Ìjà àgbà méjì, Fasoranti àti Adebanjo kọjú oro síra wọn lórí ipò adarí Afenifere

Aigbọra ẹni ye to n waye ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre ti ba ọna miran yọ pẹlu bi awọn eekan ninu ẹgbẹ naa, Reuben Fasọranti ati Ayọ Adebanjọ ṣe di ero ọtọọtọ mu lori ẹni to jẹ adari ẹgbẹ naa.

Saaju asiko yii ni awọn adari mejeeji naa ti ni ero miran lori ẹni ti ipo aarẹ tọ si laarin awọn oludije funpo aarẹ ninu eto idibo ọdun 2023.

Ninu ọrọ rẹ, Adebanjọ ko fi bo pe ẹyin oludije fẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi, ni oun to si, ti oun si n se atilẹyin fun.

Amọ Reuben Fasoranti n tiẹ kede lasiko ti oludije fẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ṣe abẹwo si ni ilu Akure pe Tinubu ni oun wa lẹyin rẹ lati di ipo aarẹ mu ni Naijiria.

Abẹwo Tinubu sile Fasoranti ni Akure da wahala silẹ ninu ẹgbẹ Afenifere

Lẹyin ipade baba Fasoranti ati Tinubu ni ilu Akure nibi ti awọn eniyan to wọ tẹle wọn ti fi atilẹyin han si Tinubu, ni nkan ko ti rọgbọ mọ ninu ẹgbẹ Afẹnifẹre.

Ninu atẹjade ti akọwe ẹgbẹ Afẹnifere, Abagun Kole Omololu fi lede, o sapejuwe Tinubu gẹgẹ bi ẹni to kunjuwọn lati jẹ aarẹ.

Omololu ni ti Tinubu ba di ipo aarẹ mu, igba ati akoko yoo yipada si rere fun awọn ọmọ Naijiria.

‘’Tinubu fi awọn ohun mere mere to fẹ ṣe fun Naijiria han fun wa lasiko ipade to waye ni ilu Akure.

‘’Nitori naa o da wa loju pe igba rẹ yoo dara fun awọn ọmọ Naijiria.’’

Amọ ipade yii da wahala silẹ ninu ẹgbẹ pẹlu awọn miran ninu ẹgbẹ to n sọ pe baba Fasoranti ti fi ipo silẹ gẹgẹ bi adari, nitori naa ko lee so bi ti ẹgbẹ fi si.

Adari ẹgbẹ Afẹnifẹre ni mi, mo le buwọlu Tinubu – Fasoranti

Lasiko ifọrọwanilẹnuwo ti Baba Fasoranti ṣe pẹlu Impact TV Africa ni baba ti sọ idi ti oun fi buwọlu Tinubu

Fasoranti ni adari ẹgbẹ Afẹnifẹre ni oun ti oun ko si fi ipo naa silẹ.

‘’Mi o fi ipo adari ẹgbẹ silẹ. Awọn eniyan ṣei mi gbọ ni, nitori naa ni mo ni aṣẹ lati sọ pe Tinubu ni ẹgbẹ Afẹnifẹre fẹ dibo fun.

‘’Bakan naa ni o han si gbogbo aye pe awọn araalu fẹran Tinubu nitori nigba to de Akure ni ọjọ ipade naa, ijọ ti ayọ pẹlu duru ni wọn fi pade rẹ.’’

‘’Nitori naa ko tọ si Adebanjọ lati kilọ fun mi pe ki n ma gba Tinubu ni alejo ni ilu Akure. Ko tọ sii lẹnu.’’

Ohun ti mo le sọ ni pe Adebanjo fi ero rẹ han, ẹmi naa si fi ero mi han.’’

Ko pe mi, emi naa ko si pe lori ipade naa, ko si si igba kankan ti a sọrọ lori awọn ọrọ ti a panupọ le lori.

Fasoranti n ṣe ti ẹ ni, emi ni adari Afẹnifẹre, ibi ti mo ba lọ, ni gbogbo ẹgbẹ n lọ - Adebanjo

Amọ ninu esi ti Baba Adebanjọ sọ fun akọroyin Punch, ko si ohun to jọọ pe Baba Fasọranti ni adari ẹgbẹ.

Adebanjo ni Baba Fasọranti ti fi ipo adari silẹ fun oun ti oun si ti di ipo naa mu nitori naa, ko si ọrọ ninu pe ẹni kan ni adari.

‘’A ti fi ero wa han gẹgẹ bi ẹgbẹ, Peter Obi ni a ṣe atilẹyin fun, ko si agba ẹgbẹ kankan to le da ipinnu wa ru.’’

Baba Fasoranti ko ni aṣẹ kankan lati yọ mi kuro ni ipo adari nitori ẹmi ni mo di ipo adari ẹgbẹ mu labẹ ofin.’’