"Ẹ̀fọn àbaàdì tó ń fa ibà ní Asia ti ń yawọ ilẹ̀ Adúláwọ̀"

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn onimọ sayẹnsi ti kede pe awọn ẹya ẹfon to n pín aarun iba lati ilẹ Asia tí balẹ sí ilẹ Adulawọ.
Awọn ẹfọn naa si ni wọn lo n dunkoko mọ ìlera awọn eeyan to n gbe lawọn ilu nlanla.
Iwadi fihan pe ni ilẹ Adulawọ, pupọ lara nnkan to n gbẹmi awọn eeyan ni aarun iba.
Awọn ẹfọn to si wọpọ lawọn agbegbe igberiko si lo n se okunfa ọpọ iku eeyan nilẹ adulawọ
Iwadii naa ni pe awọn ẹfon lo n gbe aarun naa kiri lọ si awọn ilu nla lati awn agbegbe gberiko.
Awọn onimọ sayẹnsi ni ẹya ẹfon yii, ti wọn pe ni ‘Anopheles Stephensi’ lo n sokunfa pupọ lara awọn iba ti wọn ri ni awọn apa ibi kan lorilẹede India ati Iran.
Àwọn onímọ̀ ní tí ẹ̀yà ẹ̀fọn àbaàdì yìí bá wọ Áfíríkà, ẹ̀mí èèyàn 130m wà nínú ewu
Bakan naa ni awọn ẹfọn ọhun npa ọmọ si lati ipasẹ awọn omi ti wọn n pese nilu nla nla.
Awọn onimọ naa wa kede pe ko si oogun ẹfọn kankan to le sekupa awọn ẹwọn abaadi yii.
Wọn ni awọn ẹfon yìí ti ṣe ikọlu si Orilẹede Djibouti ati Ethiopia, to si n gboro si.
Itankalẹ awọn ẹfọn abaadi yii si ni wọn lo n mu ki aayan awọn onisẹ iwadii lati palẹ wọn mọ nilẹ nira si.
Awọn onisẹ iwadi ni ti awọn ẹfọn asekupani yii ba fi le tan ka ilẹ adulawọ, o sese ko ṣe akoba fun ogunlọgọ awọn eeyan ti yoo to miliọnu lọna aadoje.
Elon Musk ti ra Twitter 'lati ṣe ọmọ aráyé lóore'

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọkunrin to lowo julọ ni agbaye, Elon Musk ti san gbogbo biliọnu mẹrinlelogoji Dọla lati fi ra ileeṣẹ ayelujara Twitter.
Awọn ileeṣẹ iroyin ni America ati ẹnikan lara awọn oludokowo nileeṣẹ naa lo kede eyi.
Bakan naa ni Musk funra rẹ kọ ọrọ kan si oju opo Twitter rẹ ni idaji ọjọ kejidinlọgbn, oṣu Kẹwaa, pe “ẹyẹ naa ti gba ominira”, eyi to tumọ si o ti ṣe aṣeyọri ni rira Twitter.
Iroyin tun sọ pe wọn ti da awọn ga agba kan, to fi mọ ọga patapata, Parag Agrawal duro lẹnu iṣẹ.
Aṣeyọri yii yoo mu opin ba ẹjọ ti Twitter gbe lọ sile ẹjọ, lati fi dandan mu Musk ko faramọ awọn ilana kan to fẹ ẹ yẹ̀ silẹ ninu iwe adehun tita Twitter fun.
Twitter ko tii kede iroyin pe Musk ti ra a, amọ oludokowo kan sọ fun BBC pe kara-kara naa ti pari.
Bi Musk ṣe bẹrẹ irinajo rẹ lati ra Twitter
Oṣe Kinni, ọdun 2022 ni Elon Musk bẹrẹ igbesẹ lati ra Twitter, botilẹ jẹ pe o ṣe e ni ọna ti ko mu ifura dani.
O bẹrẹ pẹlu rira ipin idokoowo diẹdiẹ, igba ti yoo si fi di aarin oṣu Kẹta, o ti ni ida marun-un ipin idokowo ileeṣẹ naa.
Oṣu Kẹrin ni wọn kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to ni ipin idokowo Twitter julọ. Ipari oṣu naa si ni wọn fẹnuko pẹlu rẹ lati ra ileeṣẹ naa ni biliọnu mẹrinlelogoji Dọla.
Musk ni oun pinnu lati ra Twitter, ko le jẹ bii agboole fun gbogbo eeyan ni agbaye lati sọrọ bi wọn ṣe fẹ, lai si idalẹbi taabi ofin to mu wọn.
Ni oṣu Keje, Musk kede pe oun ko ra ileeṣẹ naa mọ, nitori awọn akiyesi kan.
Ṣugbọn Twitter sọ pe ofin ti de erongba rẹ lati ra a , ti wọn si pe ẹjọ tako o lati mu ko ra a.
Ibẹrẹ oṣu Kẹwaa ni Ọgbẹni Musk tun kede pe oun yoo bẹr idunadura pada, ti Twitter ba fi le da ẹjọ to pe duro.
Awọn iyatọ ti yoo ba Twitter lẹyin ti Elon Musk ra a
Twitter ko tii sọrọ lori rira yii, ṣugbọn nkan to daju ni pe Musk ni yoo ma a dari rẹ.
Ọpọlọpọ igba ni Musk ti bu ẹnu atẹ lu bi Twitter ṣe ma n ‘pa awọn eeyan lẹnu mọ’ lori ayelujara naa.
Bakan naa ni awọn eeyan kan lagbo oṣelu ilẹ America sọ pe Twitter labẹ iṣakoso awọn oludari rẹ tẹlẹ, ko fun awọn ọmọ ẹgbẹ osẹlu Conservative ni anfaani lati ni ominira ọrọ sisọ loju opo naa.
Amọ pẹlu bi Ọgbẹni Musk ṣe ra bayii, ọpọ eeyan ti Twitter ti fi ofin de lori ayelujara wọn, ni igbagbọ wa pe wọn o pe pada.
Lara iru awọn eeyan naa ni aarẹ America tẹlẹ, Donald Trump.
Ṣugbọn awọn eeyan kan tun fi ẹdun ọkan han pe fifi ominira ọrọ sisọ silẹ le mu ki awọn eeyan ma sọ ọrọ ikorira lai si ofin to de wọn.












