Kí ló dé táwọn pásítọ̀ gbé àsọtẹ́lẹ̀ jáde tàbí ń bèèrè òkú Ifeanyi, ọmọ Davido?

Oríṣun àwòrán, davido/Prophet Samuel King Ministries
Nigba ti iroyin iku Ifeanyi, ọmọ gbajumọ olorin takasufe, Davido jade sita lowurọ ọjọ Iṣẹgun, kaakiri agbaye ni awọn eeyan, paapaajulọ, awọn ololufẹ akọrin naa ti gbarata, ti wọn si banujẹ lori rẹ.
Amọṣa ohun miran to tun gbode kan ni iroyin pe awọn woli kan ti ri asọtẹlẹ nipa iku ọmọdekunrin naa, ti ori ayelujara si n gbona nipa isẹlẹ naa.
Lara awọn asọtẹlẹ yii ni wọn sọ pe o ti ẹnu woli kan ti orukọ rẹ n jẹ Samuel King jade.
Woli Samuel King yii ni wọn sọ pe o gbe e jade loju opo Facebook rẹ ni ọjọ keje oṣu kini ọdun 2022 nigba naa pe dugbẹdugbẹ kan n bọ ni idile Davido.
Ki ni aṣọtẹlẹ Woli King gbe sita?

Oríṣun àwòrán, Prophet Samuel King Ministries/Facebook
Ninu asọtẹlẹ naa, Wolii Samuel King sọ pe ki gbajumọ olorin naa gbadura gidigidi lati dena ọfa iku, paapaajulọ lori ọmọ rẹ ọkunrin.
“Ẹ GBADURA FUN DAVID ADELEKE ti ọpọ mọ si Davido. Ninu iran ti mo ri, ọdun 2022 kun fun ọpọ anfani, ami ẹyẹ ati ogo fun un!
Ọdun yii ni ọdun ti ohun rere yoo sun un bọ julọ titi wọ inu ọdun 2023. Ṣugbọn ẹ jẹ ki a gbadura lodi si ọfa iku PAAPAAJULỌ si ọmọ rẹ ọkunrin!
Mọlẹbi Davido kan naa fidi rẹ mulẹ pe awọn ti ri asọtẹlẹ saaju nipa iku ọmọ naa amọ awọn ko ka a si
Woli yii ti wa sọrọ jade lẹyin ikede iku ọmọ naa pe o tun ku ni ibọn nro o. afi ki oun ri Davido tabi mọlẹbi rẹ lati sọ apa keji isọtẹlẹ naa fun un.
“Awọn nnkan miran ti yoo tun jade labẹ iran yii ṣi wa ṣugbọn o farasin, to si nilo ki a fi adura gbe e kalẹ pẹlu David Adeleke ati idile rẹ”
Eyi ko tan sibẹ o.
Ọkan lara awọn mọlẹbi Davido pẹlu ti ọpọ mọ si ‘Senator’, naa ti pariwo sita ni kete ti iroyin iku ọmọdekunrin naa jade.
Oun naa fidi rẹ mulẹ pe ikilọ si waye nipa isọtẹlẹ si awọn ṣugbọn o ni awọn kọ eti ọgbọin si ọrọ naa.

Oríṣun àwòrán, Peculiar Emmanuel/Facebook
“Ẹ maṣe sin oku Ifeanyi ọmọ Davido, ọmọ ologo ni”
Bi gbogbo eyi ṣe n ja ranyin-ranyin, pasitọ miran tun ti jade ninu fidio kan to n kiri ka ori ayelujara bayii.
Pasitọ naa lo ni pe ki Davido mase sin ọmọ naa nitori ninu iwoye rẹ, ọmọ ologo ni.
Pasitọ Christian Shola fi ọrọ ranṣẹ si gbajumọ akọrin naa ati iya ọmọ rẹ, Chioma pe ki wọn maa gbe ọmọ naa bọ ni ijọ oun, ki wọn si maa wo ohun ti yoo ṣẹlẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, Ọlọrun yoo ṣiṣẹ iyanu lori Ifeanyi bi wọn ba gbe e wa laarin wakati mọkanlelogun.
Ninu ọrọ rẹ: Ẹ MAṢE SIN OKU ỌMỌDEKUNRIN NAA BAYII, ỌMỌ OLOGO NI.
''A fẹ́ ṣe àyẹ̀wò òkú ọmọ Davido, Ifeanyi Adeleke, àmọ́...''

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM
Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti sọrọ lori ibi ti ọrọ de duro lori iku ọmọkunrin Davido, Ifeanyi Adeleke.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lasiko to n ba BBC sọrọ ni erongba wọn ni lati ṣe iwadii iku ọmọ naa nipa ayẹwo sayẹnsi, iyẹn autopsy.
Ọjọ Aje ni ọmọ ọdun mẹta naa jẹ Ọlọrun ni ipe lẹyin ti wọn ba oku rẹ ninu omi swimming pool to wa ninu ile wọn ni Banana Island ni ilu Eko.
‘’Erongba wa ni lati ṣe ayẹwo iku ọmọ Davido’’
Hundeyin ni ohun ti awọn ma n ṣe lasiko iwadii iku ni lati se ayẹwo lọna imọ sayẹnsi ohun to pa ẹni naa.
O ni amọ awọn ẹbi miran ma n kọ jalẹ fun awọn ọlọpaa pe awọn ko fẹ iru ayẹwo bẹẹ.
‘’O wa lara iwadii ti a ṣe pe ki a mọ iru iku to pa ọmọ Davido.’’
Amọ a ko le e see ti ẹbi ba sọ wi pe awọn ko fẹ.
Nibayii, ko si ẹni to ti sọ pe awọn ko lọwọ si sise iwadii oku ọmọ naa, nitori naa a ni ero lati se, gẹgẹ bi ara iṣẹ wa.’’
''Awọn meji lo ku si panpẹ wa ninu awọn mẹjọ ti a fi panpẹ mu lori iṣẹlẹ iku ọmọ Davido''

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fi awọn mẹfa silẹ ninu awọn mẹjọ to wa ni ahamọ ọlọpaa lori iṣẹlẹ iku ọmọ naa.
Ọlọpaa nigba to n sọrọ fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni meji ninu awọn araale Davido ṣi wa ni ahamọ wọn.
‘’Ọkan ninu awọn meji naa ni nanny, eyiun olutọju ọmọ to ri si omi naa.’’
Amọ awọn mejeeji ti wọn wa ni ahamọ wa ni wọn n ran wa lọwọ lori iwadii iṣẹlẹ iku naa.’’
‘’Awọn mẹjo ni a pe fun ifọrọwanilẹnuwo, amọ a ri pe awọn meji ti ọrọ kan gbọngbọn nikan ni a ko fi silẹ lati lọ si ile wọn.’’
Nanny to yẹ ko maa bojutọ ọmọ naa wa ni ara wọn, ti a si n fi ọrọ wa lẹnu wo lọwọ lori bi ọmọ naa ṣe rin jade kuro ninu ile lọ si swimming pool.
Njẹ ọlọpaa ti gbegi dina Swimming pool ọhun?
Ileeṣẹ ọlọpaa ninu ọrọ wọn ni iwadii awọn ko niise pẹlu boya awọn gbe igi di swimming pool ọhun abi bẹẹkọ.
O ni iwadii n tẹsiwaju lori iṣelẹ naa amọ awọn ko gbegidi swimming pool ile Davido ti wọn ti ri ọmọ naa.
Iroyin ni ọmọ naa ti ri si inu omi naa fun igba diẹ ki awọn eniyan to ri ni isalẹ omi.
















