Ìwọ́de Iran ń gba ọ̀nà míì yọ báwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásítí wọ́de lórí akẹẹgbẹ́ wọn tó wà ní àhámọ́

Aworan

Oríṣun àwòrán, HIRANA

Awọn ọmọ fasiti lorilẹede Iran ti kọ iṣẹ silẹ lati fi ẹhọnuhan lori bi ijọba ṣe fi awọn akẹkọọ si panpẹ.

Fidio ati awọn fọtọ to wa lori ẹrọ ayelujara ṣafihan bi awọn akẹkọọ ọkunrin ati obinrin ṣe ko ara jọpọ ni awọn ileẹkọ to wa ni Tehran ati awọn ilu miran.

Awọn ti wọn ri naa gbe paali dani pẹlu akọle pe awọn ko ni lọ si kilaasi afi ti ijọba ba fi awọn akẹkọọ ti o wa ni ahamọ ijọba silẹ.

Aworan, fidio ṣafihan awọn akẹkọọ to joko silẹ lati fẹhọnuhan

O kere tan awọn akẹkọọ bii ọọdunrun ni wọn ti mọle nigba ti rogbodiyan bẹ silẹ ni nkan bi ọṣẹ mẹfa ṣẹyin.

Ohun to fa ifẹhọnuhan naa ni ki ọdọbinrin kan ṣe ku si ahamọ ọlọpaa lẹyin ti wọn fi panpẹ mu pe ko wọ ijaabu rẹ dara dara.

Eleyii si ti fa rogbodiyan lorilẹede naa, iru eleyii ti ko i tii ṣẹlẹ lati ọdun 1979 ti ayipada ti de si orilẹede naa nitori ẹsin Islam.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Ajọ ajafẹtọ lorilẹede Iran, Human Rights Activists News Agency (HRANA) fi aworan lede nibi ti awọn akẹkọọ ti joko si ilẹ ni awọn ileekọ fasiti ni olu ilu orilẹede naa bii Sharif University of Technology, Al-Zahra University to fi mo Amir Kabir University of Technology.

Fidio awọn to joko ni fasiti Shahid Behesti University naa safihan awọn to joko ti wọn si n kọri fun awọn ọmọ fasiti ti wọn wa ni ahamọ naa.

Bakan naa ni awọn ajafẹtọ obinrin ni fasiti yẹ ko jẹ ileẹkọ fun awọn eniyan lati ni ominiran, wi pe kii ṣe ibi to yẹ ki wọn ti maa fi iya jẹ awọn akẹkọọ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2