‘’Ọ̀ga mí pàṣẹ kí ń ma bá ó kéré tán ọkùnrin mẹ́wàá sùn lójúmọ́’’- Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá

Aworan

Oríṣun àwòrán, Gabriel Okechukwu

Ọkan lara awọn ọmọdebinrin ti wọn fi n ṣe owo nọọbi ti ṣọ iriri rẹ ati bi o ṣe di ẹni ti wọn fi n ṣe iṣẹ aṣẹwo.

Arabinrin Nancy ti wọn fi orukọ yii bo ni aṣiri, wa ni ara awọn obinrin aadọta ti wọn n ṣe owo nọọbi, ti awọn ẹṣọ alaabo doola ẹmi wọn ni ile itura mẹta ni adugbo Azikwe, Mile 2 Diobu Port Harcourt ni ipinlẹ Rivers.

Awọn ikọ ọlọpaa kogberegbe, ikọ ọmọogun ilẹ, ẹṣọ alaabo ati ajọ to n gbogun ti fifi ẹni ṣe owo ẹru, NAPTIP ni wọn ṣe iwadii ile itura mẹta naa ti wọn si fi panpẹ mu wọn.

‘’O kere tan awọn ọmọde aadọta ni a doola ẹmi wọn’’

Awọn adari ile itura naa ni wọn fi awọn ọmọ ti ọjọ ori wọn ko to mẹrinla ṣe owo nọọbi, ti wọn si ti ile itura naa pa.

Adari eto iroyin ikọ ọmọogun oju omi NNS Pathfinder, Ọgagun Richard Iginla lo fi idi ọrọ naa mulẹ.

Ninu ọrọ rẹ rẹ o ni, ‘’Ẹbun Ọlọrun ni ọmọ jẹ, ti a si gbọdọ sa ipa wa lati da abo bo wọn lọwọ awọn aṣebi.’’

Lẹyin ti ajọ NAPTIP fi ọrọ naa to wa leti ni a lọ sibẹ ni kiakia, ti a si fi panpẹ mu wọn.’’

‘’O kere tan awọn ọmọde aadọta ni a doola ẹmi wọn’’

‘’Iṣẹ ọmọ-ọdọ ni wọn sọ fun wa, owo nọọbi ni wọn wa fi wa ṣe’’

Lasiko ti Nancy n sọ iriri rẹ lo ni aunti oun lo mu oun wa lati abule ni ipinlẹ Anambra pe ki oun wa ran obinrin kan lọwọ ni ile itura rẹ.

O ni ki n se oun nikan ni wọn mu wa amọ pẹlu awọn meji miran, amọ iṣe owo nọọbi ni wọn wa fi wọn ṣe.

 ‘’Nigba ti a de ibẹ ni obinrin naa sọ wi pe nitori owo ribiribi ti oun ti na lati mu wa lati ilu iṣẹ aṣẹwo ni yoo ma ṣe titi yoo fi da owo naa pada.’’

Lẹyin naa ni obinrin naa fi wa si yara kan, to si ni ki a ma ṣe iṣẹ aṣẹwo.

O ni oun kọkọ yari amọ nigba ti obinrin naa ni oun ko ni fun oun ni ounjẹ ni oun gba lati ṣe iṣẹ aṣẹwo naa.

O kere tan ọkunrin mẹwaa ni mo n balopọ, ti ọga mi a si gba owo ti mo ba pa.

Aburo ọga wa ni o ma n ṣe iṣiro iṣẹ ti a ba ṣe lojumọ ti yoo si fun wa ni ida to ba tọ si wa.

‘’Lati sọ awọn ọmọde naa di eniyan tuntun yoo ṣe diẹ nitori ọmọde ṣi ni wọn’’- NAPTIP

Olori Ajọ NAPTIP nipinlẹ Rivers, Abilekọ Nwa-Amaka Ikediashi ni awọn yoo bẹrẹ ilana atunṣe ( rehabilitation) fun awọn ọmọ naa laipẹ.

O ni awọn yoo gbiyanju lati da awọn ọmọ naa pada si awujọ lẹyin ti wọn ba ti gba itọju to peye.

Bakan naa ni wọn fikun un pe iwadii kikun yoo waye loti iṣẹlẹ naa.

Nibayii, awọn to ni ile itura naa to jẹ ọkunrin kan ati obinrin meji ni wọn wa ni panpẹ ọlọpaa.

Igba akọkọ kọ niyii ti wọn n fi awọn ọmọde ṣe owo nọọbi, ti wọn si doola ẹmi awọn ọmọ marundinlogun ni aipẹ yii.