Èèyàn mẹ́tàlá jóná kọjá mímọ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní Enugu

Oríṣun àwòrán, Ibidunni Blog
Ko din ni eeyan mẹwaa to ti jona guguru bayii leyin ijamba ọkọ kan to waye nipinlẹ Enugu.
Alẹ ọjọ Aiku ni ijamba naa waye loju ọna marosẹ Enugu si Port-Harcourt, nitosi ileewosan fasiti ijọba apapọ to wa ni Ituku-Ozalla.
Iroyin ni ọkọ akero kan to n rinrinajo lati ipinlẹ Imo si Adamawa lo fori sọ ọkọ ajagbe kan, to si gbina lẹyin naa.
Nigba to n fidi iroyin naa mulẹ, adari ajọ to n risi irinna ọkọ loju popo nipinlẹ Enugu, FRSC, Ọgbẹni Joseph Toby sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyii to gba omije loju eeyan.
O fi kun pe awọn ko tii le sọ ni pato iye eeyan to ba ijamba naa lọ lasiko ti a ko iroyin yii jọ.
O ni “Awọn oṣiṣe mii ṣi wa nibi ti ijamba naa ti ṣẹlẹ, ọkọ akero kan lo fori sọ ọkọ mii ki ina to sọ lara rẹ.”
“Nitori naa awọn eeyan mi ti wa nibẹ, bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, a ko le sọ ni pato iye eeyan to ku nibẹ, mi o si fẹ fun yin ni iroyin ẹlẹjẹ.”
Toby ṣalaye saiwaju si pe gbogbo oru lawọn oṣiṣẹ panpana fi wa nibẹ lati pa ina to ṣẹyọ nibẹ.
Adari FRSC naa sọ siwaju si pe o ṣoro lati ṣabẹwo si agbegbe naa laarọ ọjọ Aje nitori ofin igbele awọn ọmọ ẹgbẹ IPOB to wa lode.
Lẹyij naa lo ni awọn yoo kede iye eeyan to ba iṣẹlẹ ọhun loju opo ileeṣẹ awọn lori ayelujara.














