Namibia Himba Women: Èéfín iná àti amọ̀ ni àwọn obìnrin yìí fi n ṣe ara lóge

Awọn obinrin Himba

Ara ọtọ ni awọn eniyan ẹ̀yà Himba lorilẹ-ede Namibia, nitori àṣà ati ìṣe wọn to yatọ si ti gbogbo aye.

Ẹya yii jẹ gbajugbaja ni Namibia, ti wọn si ma n pe wọn ni 'red people', eyi to tumọ si awọn eniyan pupa.

Awọn eeyan ẹ̀yà yii to ẹgbẹrun lọna aadọta, bẹ́ẹ̀ si ni awọn kan gbagbọ pe awọn obinrin wọn lo rẹwà julọ ni Africa.

Bo tilẹ jẹ pe awọn obinrin naa kii wẹ, ti wọn kii si fi omi ṣan ọwọ wọn, sibẹ wọn ko burẹwa.

Ọna wo ni wọn n gba ṣe itọju ara wọn, ti wọn o fi ki n run?

Nise ni àwọn obinrin naa ma n fi èéfín ina wẹ lati le tun ara ṣe. Bii ti báwo?

Lojoojumọ, awọn obinrin naa ma n ko eedu to ni ina lara sinu ikoko, wọn o si da oriṣiriṣi ewe ati egbo igi sinu rẹ.

Àkọlé fídíò, Oladuni Giwa-Osagie: Òrùka mẹ́fà ní ọkọ́ mi fi bèèrè láti fẹ́ mi lẹ́ni ọdún 47

Ti eefin ba ti n rú, wọn yoo tẹ ara wọn ba sori ikoko naa. Eefin to ba n jade yoo mu ki wọn o laagun, ti o n fọ ara wọn.

Lati wẹ gbogbo ara, wọn o fi aṣọ nla bo ara wọn, ki eefin ba a le duro si ara rẹ fun oogun.

Yatọ si eyi, ẹẹmeji ni wọn ma n fi ori ati amọ pupa pa ara wọn nitori oorun ati kokoro.

Awọn eniyan Himba gbagbọ pe àwọ̀ pupa jẹ àpẹẹrẹ ilẹ ati ẹ̀jẹ̀.

Aṣọ penpe ti wọn fi awọ ewurẹ ṣe ni awọn obinrin yii ma n wọ, ti wọn si ma n fi amọ pupa kun irun ori wọn.

Idi ti awọn eniyan naa kii se fi omi wẹ nipe, oju ọjọ lágbára pupọ lagbegbe wọn.

Awọn obinrin Himba

Inu aginju ni wọn n gbe, eyi to mu ko nira lati ri omi lo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ko tan sibẹ o. Àwọn obinrin yii tun ma n fi ibalopọ ọ̀fẹ́ ṣe alejo, ti ọpọ wọn si maa n fi ara silẹ lai wọ asọ to bo ọmu wọn.

Lojoojumọ si ni awọn eniyan ẹ̀yà yii n sisẹ karakara lati daabo bo àṣà wọn.