Osun Money Ritual: Wò ó bí Babaláwo ṣe gé apá, ẹsẹ̀, orí àti ọ̀kan oníbàárà rẹ̀ fi ṣe òògùn owó

Awọn afurasi afini se oogun owo

Oríṣun àwòrán, Osun State Police

Yoruba ni ẹni to ba n wa iwakuwa, yoo ri irikuri.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun ọkunrin kan, ti wọn pe orukọ rẹ ni Ayoade Moses Fasesan to n gbe nilu Ikirun, to tọ Babalawo kan lọ lati se oogun owo nitori sanmọni to lọ tiirin fun.

Babalawo naa, Faseun Afolabi, ẹni ogoji ọdun, lo wa sọ fun Ayo pe oun ko se oogun owo fun ẹnikẹni ri amọ ti Ayo sọ pe dandan, o gbọdọ se fun oun ni.

Idi ree ti Faseun se tọ agba awo miran, tii se ọrẹ rẹ lọ lati ran lọwọ se oogun owo fun Ayo, amọ oun to ro lọhun, kọ lo ba.

Babalawo keji naa, Fadare Afolabi, ẹni ọdun mejidinlogoji, lo wa gba Faseun nimọran pe ko jẹ ki awọn lo Ayo, lati fi se oogun owo fun ara awọn.

Lọjọ ti Ayo de lati se oogun owo yii, Fadare ati ọkunrin kan ti wọn pe ni Taiwo ti wa nikalẹ, ti wọn si fun Ayo lọrun pa.

Àkọlé fídíò, Khadijat Oluboyo: Ilé ẹjọ́ sọ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ sí gbaga

Faseun, lasiko to n ka boro boro fun awọn ọlọpaa nipinlẹ Osun ni oun gan ni oun fa Ayo ni ẹsẹ mejeeji, ti Taye fi fun ni ọrun pa.

Awọn afurasi naa, tileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun foju wọn han faraye tun salaye pe awọn ge ẹya ara Ayo, ti wọn si ta lati gba owo, nigba ti wọn lo awsn miran fun oogun owo.

Faseun ni "Ọwọ Ayo mejeeji ati ọkan rẹ ni wsn fun mi. Mo ta ọwọ kan ni ẹgbẹrun lọna ogun naira nigba ti mo fi ọwọ keji ati ọkan rẹ tọrọ."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba toun naa n jẹwọ ẹsẹ rẹ, babalawo keji, Fadare ni ori oloogbe naa ati ẹsẹ rẹ mejeeji ni oun fi peelo oogun owo fun ara oun."

Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Osun, Olawale Olokode lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ, tun kede orukọ awọn afurasi yoku ti wọn tun ko lori isẹlẹ naa.

Lara wọn ni Adeleke Kabiru, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, Oloyede Moruff, ẹni ọdun mọkandinlogoji, Oseni Mukaila ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Badmus Sairu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji.

Olokode ni "ọjọ Kẹrinlelogun osu Karun ọdun 2021 ni iya Ayo ke gbajare tọ awọn ọlọpa lọ pe oun ko ri ọmọ oun mọ.

Àkọlé fídíò, LASU Ritual: Àwọn akẹẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ LASU tí wọn fi ṣowó sọ̀rọ̀ lórí ìgbé ayé olóògbé

Iya Ayo ni studio lo dagbere pe oun n lọ amọ ti ko pada wale mọ, idi si ree ti awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fi bẹrẹ iwadii lori isẹlẹ naa.

Lasiko iwadii ọhun ni ọwọ tẹ babalawo akọkọ, Faseun Afolabi, ẹni to kọkọ sẹ pe oun ko mọ ibi ti Ayo wa amọ lẹyino rẹyin, o pada ka boroboro.

Idi si ree ti ọwọ fi tẹ awọn afurasi yoku bi o tilẹ jẹ pe Taiwo, to fun Ayo lọrun pa ti na papa bora."

Kọmisana ọlọpaa ni afurasi akọkọ yii lo mu awọn ọtẹlẹmuyẹ lọ sibi ti wọn sin oku Ayo si ladugbo Fidibomi nilu Ikirun, ti wọn si hu oku naa jade fun ayẹwo.

O ni wọn ti gbe oku oloogbe naa lọ si ibudo igbokusi tile iwosan ẹkọsẹ isegun Uniosun, ti iya Ayo si fi asọ ara oloogbe naa da mọ pe ọmọ oun ni.

Àkọlé fídíò, Baba Khadijat Oluboyo jẹ́rìí ọmọ rẹ̀