Myths about Mestrual period: Ṣé lóòtọ́ọ́ ni wíwọ páàdì lásìkò nǹkan oṣù lè já àbálé obìnrin?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oriṣiiriṣii nkan lawọn eeyan maa n sọ nipa nnkan oṣu obinrin, awọn eeyan kan gbagbọ pe oniruuru eewọ lo rọ mọ nnkan oṣu naa.
Oriṣiiriṣii eewọ nipa nnkan oṣu obinrin lawọn eeyan maa n sọ, ọkan lara rẹ ni pe ti ọkunrin ba ni ibalopọ pẹlu obinrin to n se nnkan oṣu lọwọ, iru ọkunrin bẹẹ yoo ko arun lara ibalopọ.
Bakan naa ni wọn tun gbagbọ pe ti obinrin ba n lo paadi lasiko nkan oṣu, o le poora si inu oju ara rẹ.
- Ọ̀nà àbáyọ márùn ún rèé tí obìnrin àti ọkùnrin bá lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀
- Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀, ni wọn bá figbe ta
- Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta
- Ọ̀nà àbáyọ márùn ún rèé tí obìnrin àti ọkùnrin bá lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀
- Wo oríṣiríṣi ìgbádun ibálòpọ̀ láwọn orílẹ̀èdè mìíràn
- Ẹ̀mi arákùnrin yìí kò gbé e, ó bá aláṣẹ́wò lò dórí ìgbà ìkéje ló bá ré sálákeji
- Wo bí o ṣe lè mọ orúkọ àwọn afípabánilòpọ̀ ní Nàìjíríà
- Bó o bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tó o lè kó lójú ara rẹ
Awọn nkan mii ti wọn tun maa n sọ ni pe irora nnkan oṣu maa n dinku, ti obinrin ba ti lọ sile ọkọ.
Awọn mii tun sọ pe o ko le karun HIV-AIDS lasiko nkan oṣu rẹ.
Ohun miran ni pe ti o ba n ṣe nnkan oṣu, ti o ba jẹ nkan to ni ṣuga daadaa, nkan oṣu rẹ yoo pọ.
Amọ, awọn onimọ iṣegun eleto ilera ti ja ọpọ ahesọ ọrọ ti ẹnikẹni ko le fidi rẹ mulẹ nipa nnkan oṣu obinrin.
Wọn ni ọpọ nkan ti wọn ti n sọ nipa nkan oṣu kaakiri agbaaye fun ọpọ ọdun lo pa ni lẹrin.
Wọn ni awọn kan ṣe ajeji ṣugbọn gbogbo rẹ lo lagbara lati ṣakoba fawọn to n ṣe nkan oṣu, ti wọn ba gba wọn gbọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ohun tó ṣe ìdíwọ́ rèé táwọn alátìlẹ́yìn Sunday Igboho méjìlá kò fi kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n - Agbẹjọ́rò
- Wo ohun tílé aṣòfin fẹ́ ṣe tí Abba Kyari bá jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì lílù
- Buhari ná ₦5trn lórí ètò àbó síbẹ̀ Boko Haram, agbébọn pa 11,420 ọmọ Nàìjíríà - Ìwádìí
- Hushpuppi: Ẹ lọ gbé Abba Kyari wá jàǹtò láti sọ tẹnu rẹ̀ - Ilé ẹjọ́ Amẹrika
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
- Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́nu mẹ́rin ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìwádìí Abba Kyari àti Ramoni Igbalode
- Hushpuppi ló fi àwọn 'messages' orí fóònù rẹ̀ hàn FBI tí wọ́n fi rí àrídájú lórí ìwà gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ tí Abba Kyari hù
- Èèmọ̀ rèé o! Àrá sán pa èèyàn 17 níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó, ọkọ ìyàwó farapa
- Ìdí tí wọ́n fi ń pè mi ní Maradona rèé- Ibrahim Babangida
- Tú ajá rẹ sílẹ̀, kí o fi ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà jura ní ìpínlẹ̀ Oyo
Awọn kan tiẹ ni paadi nkan oṣu le jabale obinrin, eyi ni lilo paadi lasiko nkan osu fi jẹ eewọ lawọn orilẹede agbaye kan.
Awọn dokita onimọ nipa agọ ara obinrin ni otitọ ni pe awọ abale to bo oju ara ọlọmọge le ja tabi ki oju ara fẹ si.
Wọn ni ohun kohun lo le ṣokunfa eyi ni bii ere idaraya ati kẹkẹ gigun amọ awọ oju ara obinrin to ja ko le sọ bo ya obinrin ko tii mọ ọkunrin tabi bẹẹ kọ.
Lori pe ibalopọ lasiko nkan oṣu le pa ọkunrin, ko si ẹri ninu sayẹnsi pe ṣiṣe ibalopọ lasiko nkan oṣu lewu tabi ṣekupa eeyan.
Wọn maa n lọ ọrọ yii mọ awijare pe idọti wa lara nkan oṣu, ati pe, oriṣiiriṣii lo wa nibẹ, amọ ko ri bẹẹ.
Ko si ẹri to fidi rẹ mulẹ ninu iṣegun oyinbo pe eyan gbọdọ dẹkun ibalopọ lasiko nkan oṣu.
Lori wi pe irora nkan oṣu maa n dopin nigba ti obinrin ba ṣe igbeyawo, ko si ohun to jọ bẹẹ.
Awọn obinrin kan ti sọ pe irora nkan oṣu wọn dinku lẹyin ti wọn bimọ ṣugbọn ko ri bẹẹ fun gbogbo eeyan.
Awọn onimọ sayẹnsi nipa ara obinrin sọ pe ara nkan oṣu ni irora rẹ wa.
Maa ṣe ere idaraya lasiko nkan oṣu tori o le ba ile ọmọ jẹ, ko si ẹri to sọ pe ṣisẹ ere idaraya lewu lasaiko nkan oṣu tabi o le ba ile ọmọ jẹ.
Koda, iwadii fihan pe ere idaraya maa n ṣe adinku irora nkan oṣu.
Bo ya o ṣe tabi o ko ṣee, eyi ti o ba fẹ ni, amọ ko si ohun to ni ki o maa ṣe ere idaraya lasiko nkan oṣu ninu eto ilera.




















