Sunday Igboho: Agbẹjọ́rò kéde ọjọ́ tó ṣeéṣe káwọn afurasí tí DSS kó, kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n

Ọpọ eeyan lo ti n foju sọna lati ri awọn eeyan mejila ti awọn agbofinro DSS ko nile Oloye Sunday Igboho ni ọjọ Kinni osu Keje ọdun 2021.
Ọjọru ọsẹ to kọja ni ile ẹjọ giga nilu Abuja si ti gbe asẹ kalẹ pe ki wọn lọ gba oniduro awọn eeyan naa ni ọgba ẹwọn ti wọn wa.
Amọ titi di akoko yii, awọn afurasi ọhun si wa ni ọgba ẹwọn, koda ibẹ ni wọn ti lo opin ssẹ yii, ti ọpọ eeyan si n beere pe ki lo tun n da wọn duro?
Amọ nigba to n salaye idi ti awọn afurasi mejeejila ko se tii kuro ni ọgba ẹwọn naa, agbẹjọro wọn, Pelumi Olajengbesi ni omi lo pọ ju ọka lọ nipa beeli wọn.
Olajengbesi ni awọn gbedeke to rọ mọ igbesẹ gbigba beeli awọn afurasi naa ni awọn ko tii se amusẹ rẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn n saayan lọpọlọpọ lori rẹ.
Amọ o fi ọwọ idaniloju sọya pe ti yoo ba fi di ọjọ Aje ọla, o seese ki awọn eeyan naa kuro ni ọgba ẹwọn, gba ile wọn lọ.
"A ti lero pe pẹlu idajọ ti adajọ gbe kalẹ, oniduro mẹrin pere la nilo lati fa kalẹ fun awsn eeyan naa amọ nigba ta beere alaye daadaa, a gbọ pe oniduro meji la gbọdọ fi silẹ fun ikọọkan wọn.
A ti wa n sa ipa wa lati ri oniduro mẹrinlelogun fun awọn eeyan mejeejila naa, a ko si fẹ pada lọ sile ẹjọ mọ, lati maa bẹbẹ pe ko din iye awọn oniduro naa ku.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo ohun tílé aṣòfin fẹ́ ṣe tí Abaa Kyari bá jẹ̀bi ẹ̀sùn jìbìtì lílù
- A ò gba owó lọ́wọ́ ẹnikéni ṣẹjọ́ Sunday Igboho àti àwọn ọmọ lẹ́yìn rẹ̀
- Ìdí tí wọ́n fi ń pè mi ní Maradona rèé- Ibrahim Babangida
- Mo gbádùn bí wọ́n ṣe ń pè mí ní ''audio governor''- Seyi Makinde
- Gómínà ìpínlẹ̀ Kano àti Oyo fi ọjọ́ ajé àti Iṣẹgun sílẹ̀ fún ìṣìnmi ọdún Hijrah
- 'Pẹ̀lú ìbànújẹ́ lá fi sìn ọkọ, ẹ̀gbọ́n àti alájọṣiṣẹ́pọ̀ Dauda, ọlọ́pàá tó bá ìdigunjalè Iree lọ'
- Obìnrin kan gbé McDonald's lọ ilé-ẹjọ́ torí ìpolówó Buger já a láàwẹ̀
Ọpọlọpọ eeyan ti n fi ifẹ han lati se atilẹyin fun wa lori ohun tawọn eeyan naa n ja fun, ta si n sisẹ pe titi ọjọ Aje, didun ni ọsan yoo so lori ọrọ naa."
Bẹẹ ba gbagbe, adajọ Eguatu to n gbọ ẹjọ naa lo ti gba oniduro awọn eeyan mejeejila pẹlu miliọnu marun naira fun ẹnikọọkan.



















