Hijrah: Gómínà ìpínlẹ̀ Kano àti Oyo fi ọjọ́ ajé àti Iṣẹgun sílẹ̀ fún ìṣìnmi ọdún Hijrah

Ipinlẹ Kano ati Oyo naa ti mú ọjọ ọtọọtọ fun awọn ara lati simi sile fun ayẹyẹ ọdun Hijrah.
Gomina ipinlẹ Kano Abdullahi Umar Ganduje ya ọjọ aje, ọjọ kẹsan osu kẹjọ gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ ni ipinlẹ naa.
Ganduje rọ awọn ara ilu lati gba adura fun orilede Naijiria lati gbaa lọwọ iṣoro eto abo to mẹhẹ.
- 'Pẹ̀lú ìbànújẹ́ lá fi sìn ọkọ, ẹ̀gbọ́n àti alájọṣiṣẹ́pọ̀ Dauda, ọlọ́pàá tó bá ìdigunjalè Iree lọ'
- Ìgbà díẹ̀ ló kù kí Secondus parí sáà rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a fi ara dà á títí yóò fi lọ PDP
- Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta ní Oshogbo,ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò
- ESABOD gbé ìjà Mide Martins rù sórí ara rẹ̀ ó ń fi èpè ránṣẹ́ sí Adunni Olorisa àtàwọn míì
Gẹgẹ bi atẹjade ti kọmisọna ọrọ to n lọ ni ipinlẹ naa fọwọsi Malam Muhammed Garba ṣalaye pe isinmi naa ni lati ṣe ayajọ ọdun tuntu ninu Islam 1443 AH.
Ganduje ki awọn musulumi ku orire ọdun tuntun ti o si pe fun idupẹ ati idakẹrọrọ.
Bakan naa lo rọ awọn eniyan ipinlẹ naa lati ran ijọba lọwọ ki wọn si gbiyanju lati ran ara wọn lọwọ fun igbeaye rere.
Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Oyo ti ni ki awọn ara ilu simi si ile wọn lọjọ Isegun ni ọjọ kẹwaa, osu kẹjọ lati ṣe ayẹyẹ ọdun Islam tuntun
Akọwe ijọba Olubamiwo Adeosun lo fi atéjade naa sita lọjọ Eti
Gẹgẹ bi o ṣe sọ Makinde rọ awọn Musulumi lati lo asiko naa fun adura, isọkan, alafia ati idagbasoke orilede Naijiria.













