Mide-Funmi Martins: Kí ló dé táwọn èèyàn ń ṣ'épè fún Mide Martins torí àbúrò rẹ̀ àmọ́ tí kò fèsì? - ESABOD

Oríṣun àwòrán, Mide Martins, Esabod
Gbajugbaja sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀ orí ayélujára, Esther Aboderìn tí ọ̀pọ̀ mọ si Esabod ti fi epe kabiti kabiti ránṣẹ́ sì àwọn tó ń wá egun ọ̀rọ̀ lè gbajugbaja Òṣeré Mide Martins.
Mide Martins lo jẹ ọmọ olóògbé Funmi Martins lórí ọrọ pé kò tọju àbúrò rẹ̀, Damilare to wá ní ìkòkò nígbà tí ìyà rẹ faye silẹ.
Kii kúkú ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí ọrọ yìí yóò jáde rèé torí ni igba to sẹlẹ keyin, àwọn èèyàn dá sii.
Tó bẹ́ẹ̀ tí bàbá ọmọ náà gangan ti òun náà jẹ ìlumọọka olorin Afro-Juju, Sir Shina Peters jáde síta láti sọ pé òun lòun bí ọmọ náà kì gbogbo ayé dárí jì òun.
Kí wá lọ tún kan Mide-Funmi Martins mọ nínú ọ̀rọ̀ yìí?
Ní àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ rii pe Mide kii fèsì rárá àti rárá lórí ayélujára bí àwọn èèyàn bá ti ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọkùnrin àbúrò rẹ̀ yìí.
Àmọ́ṣá, lọpọ ìgbà ni àwọn akọroyin ti fi fídíò iforowanilenuwo wọn pẹlu ọmọ náà àti ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ tó ń gbé lọdọ rẹ sita àmọ́ kò fi bẹẹ si fídíò kankan tí Mide fúnra rẹ ti fèsì.
- Olùwọ́de EndSars mìí tí oyún bàjẹ́ mọ́ lára ni ẹ̀wọ̀n Akure, Bukunmi Ayodele gba òmìnira
- "Ẹ yé fún àwọn ọkọ yín lọ́yàn mu mọ́, àwọn ọmọ ló lọyàn"
- Wo àwòrán ìgbéyàwó ọkùnrin tó gbé obìnrin mẹ́rin níyàwó lọ́jọ́ kan ṣoṣo
- Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta ní Oshogbo,ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò
- Níbo ló kù tí Messi yóò lọ báyìí?
Esabod bẹ̀rẹ̀ si ni wù orúkọ àwọn èèyàn tó ṣepé fún Mide síta ó sì ń dá epe náà padà sórí wọn torí ni tìrẹ kò sohun tó burú tí Mide ṣe.
"Ṣe dandan ni ki Mide tọju ọmọ yìí ni, àbúrò rẹ̀ taa ń sọ yìí tí lè ní ọmọ ọdún méjìdínlógún ".
- Kí ni ìtumọ̀ pé Mide Funmi Martins kò sí níbi tí Damilare àti Shina Peters ti parí ìjà?
- Mo ń ṣe ẹ̀tọ́ mi fún Damilare lọ́dọ̀ màmá àgbà, àmọ́ ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí ló pọ̀ - Mide-Funmi Martins
- Bí àsìkò ikú òṣèré Funmi, ìyá Mide Funmi Martins ṣe roo lágbo òṣèré nígbà náà nìyìí
- Mo tún ibojì Funmi Martins ṣe torí ojú ń tì mí nípa ipò ìtìjú tó wà - Ashabi Olorisha
Ó ní osere bìnrin Adunni Olorisa kan ń ṣe ìlara lásán ni.
O ní àrùn ọpọlọ lo n dá a láàmú to jẹ pe kii se ìgbà àkọ́kọ́ to bá àwọn osere ja niyii. Ó bú ẹnu atẹ lu bí Adunni ṣe ń ṣepe fún Mide.
Iroyin sọ pé Adunni gbé fídíò kan jáde níbi tó ti ń pe fún kí àwọn eleyinju àánú máa dá owó láti ran ọmọ náà lọwọ to tún wà ń dá orúkọ Mide Martins pelu ohun tó ṣe.
"Kódà kii se dandan kí òbí rẹ tọju rẹ, mi ò ní kii ṣe ojúṣe wọn ò àmọ́ ẹni tí irú rẹ bá sẹlẹ si ko tesiwaju ninu igbe ayé rẹ ".
Esabod ni ọmọ tí wọn ń sọ yìí tí tójú bọ pé ó leè lọ wà isẹ ṣe.
Àti pé níwọ̀n ìgbà tí Sir Shima Peters tí gba pe oun ni bàbá rẹ̀ tó ṣí ṣèlérí fún gbogbo ayé pé òun yóò tọju rẹ, o ni ki lo ṣe tí wọn tún wà ń fún ogún mọ Mide Martins.
Esabod ni wọn tún ń kó ọkọ Mide Martins pọ gan tí wọn ró èrò kí òun àti Afeez Owó àti Mide ìyàwó rẹ tuka nítorí ọrọ Damilare.
Esabod: "Àìmọye àwọn ọmọ tó wà nilu oyinbo tí kò tójú ìyá àti bàbà wọn, irú wọn náà mọ pe oun ó lè jẹun ọmọ, àmọ́ ẹyin ẹ fi idajọ tó wà láàrin Mide àti ìdílé rẹ silẹ".
Ó figbe tá pé kí wọn fi Mide lọrun silẹ lórí ọrọ yìí.
"Ẹ rántí pé Mide náà ti ní ìdílé tirẹ kí wọn fii silẹ".
Ẹwẹ, àti ori àti àbọ̀ ohun tó tún wú ọ̀rọ̀ yìí síta kò tíì loju gẹgẹ bí kò ṣe sí ẹni tó gbọ́ bóyá owó kankan jáde lára ohun tí wọ́n ń gbèrò láti kó jọ fún iranlọwọ ọmọ náà.
- Láyé! Mi ò lè wo BBNaija! Ìdí tí mo fi gbá ètò náà ní "blocking" tí ẹnikẹ́ni ò gbudọ̀ wò ó nílé mi rèé'
- Wo ohun tí Babangida sọ nípa àwọn ajìjàgbara Yoruba Nation
- Wàhálà àti ìkùnsínú láàrin ọmọ ẹgbẹ́ PDP, kí ni ọ̀nà àbáyọ?
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọ ààrẹ Naijiria tẹ́lẹ̀, Umar Musa Yar'Adua sí ẹ̀wọ̀n nítorí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- Yéèpà, òfin ìtakété síra ẹni forí ṣánpọ́n lásìkò ọdún Osun Osogbo

















