BBNAIJA 2021: Pásítọ̀ kan sọ ohun tó rí tó fi f'òfin de wíwo ètò BBNaija nílé rẹ̀
Pasitọ ọmọ Naijiria kan, Gospel Agochukwu ti sọ idi ti o fi gbé ote lé wiwo eto àgbéléwò ilé Ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n Àgbà (Big Brother Nigeria) nípa dídi ọna mọ ìkànnì tí wọ́n ti ń wòó.
Pasitọ ìjọ Shekinah Arena International Gospel Ministries yìí fi fidio kan soju òpó Instagram rẹ nínú èyí tó ti sọ̀rọ̀ pé eto àgbéléwò yìí ń ṣe agbega fún ìwà ìran.
"Ó pe mi kì ń wo ere àwọn ọmọdé, cartoon ju BBNAIJA lọ".
Pasito Gospel ni ẹnikẹni to bá pe ara rẹ ní ọmọ Ọlọ́run tó sì ń wo eto naa n pá ẹ̀mí ara rẹ ní.
Bó tilẹ̀ jẹ pe Pasito kò fi aridaju kankan hàn, ó ní òun wo ọkàn lára fídíò wọn tí obìnrin kan sì ń dá da omira fúnra rẹ pẹlu ìka ọwọ tó ń lọ lórí telifisan.
"Lórí amohunmaworan ojutaye, haaa, èyí sì ni ọpọlọpọ òbí ń fi àwọn ọmọ wọn silẹ kí wọn máa wò tí àwọn yóò wọlé lọ sún".
Ó ní "eto àgbéléwò lẹ̀ ń wo ẹ sì rọ pé kò ní ṣàkóbá fún ẹ̀mí yín? Kódà, yóò pá iná àdúrà rẹ ".
"Ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n Àgbà wo ló ju Jésù lọ? Ó béèrè.
Pasito Gospel tún tesiwaju pe oun ó ní kí èèyàn má ṣe owo rẹ o àmọ́ nkan tó ń ka òun lára ni ihuwasi láwùjọ.
Ó ní bí wọn ba fi ọwọ yẹpẹrẹ mú ihuwasi láwùjọ, tí yóò bá fi to ọdún marun, ohun tí gbogbo èèyàn máa ń da aṣọ bo ṣe kó ni jẹ àṣírí mọ.
"Kò tọ́ kí ọmọde máa hu iwakiwa ni gbangba pẹlu ìgboyà". Ó ní kii se ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí eto àgbéléwò yóò máa gba abuku lórí ọrọ iranu ṣiṣẹ́ àti àfihàn rẹ.
Ẹwẹ, àkọsílẹ̀ ti fihan pe eto yìí ni àwọn eeyan ń wo ju ni Naijiria ati bóyá gan ni Afirika.
Èyí ni apa kẹfà eto naa látìgbà to tí bẹ̀rẹ̀. Akopa mejilelogun lọ wà nínú ilé Ẹlẹ́gbọ̀n-ọ́n Àgbà tí ọ̀tẹ̀ yìí tí wọn sì jọ ń figagbaga lórí Mílíọ̀nù lọ́nà àádọ́rùn-ún náírà gẹgẹ bí wọn yóò ṣe jọ wa ninu ile kan ṣoṣo fún ọ̀sẹ̀ mẹwa gbáko atọkùnrin atobìnrin.
- Wo ohun tí Babangida sọ nípa àwọn ajìjàgbara Yoruba Nation
- Wàhálà àti ìkùnsínú láàrin ọmọ ẹgbẹ́ PDP, kí ni ọ̀nà àbáyọ?
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọ ààrẹ Naijiria tẹ́lẹ̀, Umar Musa Yar'Adua sí ẹ̀wọ̀n nítorí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- Olùwọ́de EndSars mìí tí oyún bàjẹ́ mọ́ lára ni ẹ̀wọ̀n Akure, Bukunmi Ayodele gba òmìnira
- "Ẹ yé fún àwọn ọkọ yín lọ́yàn mu mọ́, àwọn ọmọ ló lọyàn"
- Yéèpà, òfin ìtakété síra ẹni forí ṣánpọ́n lásìkò ọdún Osun Osogbo
Ní báyìí wọn tí lo ọjọ méjìlá ni ẹnu sì ti bẹ̀rẹ̀ si ni pọ lórí eto naa.
Laarin ọjọ méjìlá péré, mẹwa ti sẹlẹ:

Oríṣun àwòrán, BIG BROTHER NAIJA
Lára àwọn akopa yìí tó ṣe mọ ara wọn tí bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìṣe ìfẹ́ síra ẹni.
Àwọn ará ilé ń di ó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn láti jawe olubori bẹẹ naa si ni àwọn akopa ń dárúkọ ara wọn fún ẹni tí wọn yóò lè lọ ilé.
Bí wọn ṣe wá ń kó sínú agbami ifẹ fún ara wọn tó yìí, wọn yoo si le àwọn kan lọ ilé lópin ọ̀sẹ̀ yìí.
Lára àwọn tí orúkọ wọn tí mókè láti gbé baagi wọn ni - Yerins, Beatrice, Nìyí, Yousef àti Whitemoney.


















