Ibrahim Babangida, IBB: Mo gbìyànjú ipá mi kí June 12 má yọrí sí ogun ní 1993 ni- Badamosi Babangida

Babangida

Oríṣun àwòrán, @Babangida

Aarẹ ologun Naijiria nigba kan ri, Ibrahim Babangida ti sọ pe oun gbogun ti iwa jẹgudujẹra lasiko ijọba oun ju ti asiko ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari to wa lode lọ.

Babangida lo fi ọrọ naa lede lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise TV.

O ni eeyan mimọ ni awọn to ba oun ṣiṣẹ lasiko ijọba oun yatọ si irufẹ awọn eeyan ti Aarẹ to wa lori alefa bayii ko sọdi.

Babangida sọ pe oun gbogun gbaṣẹ lọwọ gomina kan lọdun naa lọhun lẹyin to ko ₦313,000 owo ilu sapo.

Sugbọn laye ode oni, ijọba ko ṣe ohunkohun nipa awọn eeyan to ti ko ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira jẹ.

Nigba ti wọn beere erongba Babangida lori akitiyan ijọba to wa lode lati gbogun ti iwa ajẹbanu; o sọrọ ilẹ kun.

Àkọlé fídíò, Taye Osinowo Olaosebikafi Iyabo Ojo, Mide Martins, Jaye Kuti, Afeez Owo àtàwọn míì dárà ap

Wo ohun tí Babangida sọ nípa àwọn ajìjàgbara Yoruba Nation

Àwọn èèyàn kówó ìjọba jẹ nínú ìjọba Buhari ju àsìkò tí mo wà lórí àléfà lọ

O ni: "Pẹlu awọn akọsilẹ atawọn iroyin ti a n fi oju ri, o ṣoro lati ṣafiwe bi awọn eeyan ṣe n lu owo ilu ni ponpo laye ọjọhun si asiko ijọba alagbada ti a wa yii."

"Mo da gomina to ko ₦313,000 jẹ duro lẹnu iṣẹ, ṣugbọn bayii, awọn to ko owo to le ni biliọnu naira jẹ n yan fanda laarin ilu."

Àkọlé fídíò, Olawale Dada: Igbá bárà kọ́ ló kàn, àwa náà n ṣoríire láyé pẹ̀lú ìpèníjà 'Cerebral Palsy'

"Nitori naa, ta lo n gbogun ti iwa ajẹbanu ninu ijọba ti a sẹ ati ijọba to wa lode lonii?"

Babangida ni ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin oun ati Aarẹ Muhammadu Buhari, amọ awọn akọroyin lo n da aarin awọn mejeji ru.

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Ni ti oun to waye lasiko June 12, ajagunfẹyinti naa ni o ṣeeṣe ki iditẹgbajọba waye to ba jẹ pe awọn kede esi idibo igba naa.

O ni "To ba jẹ pe a kede esi idibo June 12, 1993 ni, o ṣeeṣẹ ki iditẹgbajọba waye, eyii ti yoo ta ẹjẹ ọpọ eeyan silẹ."

Ibfahim babangida

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ti ọrọ Sunday Igboho ati Nnanmdi Kanu, Babangida sọ pe kii ṣe tuntun ki awọn araalu maa bere fun iyapa, ṣugbọn o da le ohun ti wọn n bere fun ni pato.

O pari ọrọ rẹ pe "O ti le ni aadọta ọdun ti a ti gba lati maa gbe papọ gẹgẹ bii ọmọ iya kan ni Naijiria, a si ti ṣe oniruru ijiroro bii 500 lori ibaṣepọ wa, ohun to yẹ ki a maa lepa bayii ni ibaṣepọ ọhun ko ṣe ni bajẹ."

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...