Funmi Martins‘ Tomb Renovation: Ashabi Olorisha ní òun kò le dúró de Mide Martins fún àríyá tó fẹ́ ṣe lọ́dún tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, ashabi_olorisha_official/Instagram
Yoruba ni ọrẹ kitikiti, iyekan katakata, lọjọ ti ọrẹ kitikiti ba ku, iyekan katakata ni yoo gbe sin.
Amọ eyi ko ri bẹẹ pẹlu ọrẹminu oloogbe Funmi Martins kan, to gba lati tun iboji rẹ se lẹyin ọdun mọkandinlogun ti oloogbe naa papoda.
Adedola Aderonke, ti ọpọ mọ si Ashabi Olorisha ninu ere tiata ni ọrẹ Funmi Martins naa, amọ orilẹede Amẹrika lo fi se ibujoko bayii, to si gba lati tun iboji ọrẹ rẹ se lẹyin iku rẹ.
- Bí àsìkò ikú òṣèré Funmi, ìyá Mide Funmi Martins ṣe roo lágbo òṣèré nígbà náà nìyìí
- Mo ń ṣe ẹ̀tọ́ mi fún Damilare lọ́dọ̀ màmá àgbà, àmọ́ ǹkan tí ẹ kò mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí ló pọ̀ - Mide-Funmi Martins
- Shina Peters dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn abiyamọ ayé lórí ọ̀rọ̀ ọmọ tí Funmi Martins bí kó tó papòdà
- Ǹjẹ́ o mọ àwọn òṣèré bí Oyin Adejọbi, Funmi Martins àtàwọn míì tó ti dágbére fáyé?
- Ó ti tó ọdún mẹ́fà, méje tí mo ti rí Àùntí Mide Funmi Martins gbẹ̀yìn, wọ́n tún ṣẹ̀ ń ṣèlérí - Damilare
- Kí ni ìtumọ̀ pé Mide Funmi Martins kò sí níbi tí Damilare àti Shina Peters ti parí ìjà?
Ashabi Olorisha lo gbe fidio kan soju opo Instagram rẹ lati salaye fun awọn eeyan to n sọrọ odi si pe o gbe fidio bo se tun iboji Funmi Martins se sori ayelujara.
O ni oju lo gba oun ti nipa ipo ti iboji Funmi Martins wa lasiko ti oun atawọn eeyan to sun mọ lọ si oju orori rẹ nigba ti wọn n se iranti rẹ laipẹ yii.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"Se ni omije n bọ loju mi nipa ipo ti ko dara ti iboji ọrẹ mi wa lasiko ta lọ se abẹwo si iboji rẹ, ko pẹ lẹyin igba naa ni mo pada si orilẹede Amẹrika.
Koda, ọmọ rẹ ọkunrin gan, Damilare gan bu sẹkun ni leti iboji iya rẹ, idi si ree ti mo se fi owo ransẹ sile lati se itọju iboji naa.
Lootọ ni Mide Martins, ọmọ Funmi Martins ti ni lero lati tun iboji naa se fun ariya iranti ogun ọdun ti mama rẹ jade laye, amọ n ko le duro di asiko yẹn to fẹ se pati, ni mo fi se.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- À kò ní le è máa káwọ́ gbera mọ́ nípa àwọn ìkọlù ìgbà gbogbo nílẹ̀ Yorùbá- Gani Adams
- Inú mi dún, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà fún nǹkan ti mo da- Mary Daniel
- Ẹ wo bí àwọn ajínígbé ṣe gbé ọmọ ọdún 12 sí inú pósí láàyè
- Àwọn aṣọ́bodè ní fàyàwọ́ làwọn lé wọ Igboọra, kìí ṣe agbébọn Fulani
- Ìpínlẹ̀ Eko fi oṣù mẹ́ta kún ìjọ̀kó àwọn tó ń gbẹ́sùn ìṣekúpani lásìkò ìwóde EndSARS
Awọn eeyan kan wa n sọ isọkusọ nipa fidio atunse boji naa ti mo gbe sori ayelujara, emi kii bu eeyan, n ko si fẹ ki ẹnikẹni sun mi kan ogiri."
Osere tiata naa ni nigba ti oun gbe oju ororri Funmi Martins sori ayelujara lasiko ti awọn lọ sibẹ fun iranti ọdun kọkandinlogun to papoda, ọpọ eeyan lo n yọ suti ete lori rẹ.

Oríṣun àwòrán, ashabi_olorisha_official/Instagram
Ashabi Olorisha ni o dun oun bi iboji Funmi Martns se ri yii nitori oun mọ pe lọjọ kan, oun naa yoo lọ sibi ti Funmi Martins lọ.
O wa salaye pe ẹnikẹni to ba nifẹ oloogbe naa, yoo nifẹ ọmọkunrin ti Funmi Martins fi silẹ ni ikoko, eyiun Damilare Isaac Akanbi Peters, ti ko gbọnju mọ iya rẹ.
Oserebinrin naa fikun pe ọmọ naa ko jẹ igbadun iya rara, ọjọ mọkanlelogoji pere ni Damilare fi mu ọmu laya iya rẹ, to si bu sẹkun nigba to de oju orori iya rẹ.


















