Igangan attacks: Gani Adams ní ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí OPC ti ń pariwo pé àwọn agbébọn kan ńgbèrò àti kọlu Ibarapa, àwọn agbófinro kò dáhùn ni

Oríṣun àwòrán, other
Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti sọrọ lori iṣẹlẹ to waye ni ilu Iganagan, Igboọra ati agbegbe rẹ eyi to mu ẹmi awọn eeyan ilu naa kan lọ.
Iba Gani Adams ni awọn ọmọ Yoruba ko ni lee kawọgbera mọ maa woran awọn iṣẹlẹ ipaniyan gbogbo to n waye nibẹ yala latọwọ awọn agbebọn tabi awọn oṣiṣẹ agbofinro ilu.
- Ẹ wo bí àwọn ajínígbé ṣe gbé ọmọ ọdún 12 sí inú pósí láàyè
- Ìpínlẹ̀ Eko fi oṣù mẹ́ta kún ìjọ̀kó àwọn tó ń gbẹ́sùn ìṣekúpani lásìkò ìwóde EndSARS
- Àwọn aṣọ́bodè ní fàyàwọ́ làwọn lé wọ Igboọra, kìí ṣe agbébọn Fulani
- Inú mi dún, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà fún nǹkan ti mo da- Mary Daniel
- Iléẹjoọ́ feẹ̀sùn kan ìyá 'deacon' pé ó lu ọ̀gá reẹ̀ ní jìbìtì
Ninu atẹjade kan eyi to fi sita latọwọ amigbalẹgbẹ rẹ lori ọrọ iroyin, ọgbẹni Kẹhinde Aderẹmi, Iba ni ṣaaju iṣẹlẹ ọjọ Ẹti ni ẹgbẹ OPC ni ipinlẹ Ọyọ ti n ke gbajare pe awọn ti wuu gbọ o pe awọn eeyan kan yoo kọlu awọn agbegbe kan ni Ibarapa ṣugbọn ti awọn ko tii ri igbesẹ to loorin latọdọ ijọba tabi awọn to jẹ agbofinro ni ipinlẹ Ọyọ.
Amọṣa ileeṣẹ aṣọbode (Customs) ti sọ pe ohun to ṣẹlẹ ni ọjọ Ẹti ni ilu Igboọra kii ṣe ikslu awọn agbebọn bi ko ṣe itaporogan laarin awọn oṣiṣẹ aṣọbode atawọn fayawọ to n gbiyanju ati sa mọ ofin lọwọ.









