Lagos Magistrate Court: Iléẹjoọ́ feẹ̀sùn kan ìyá 'deacon' pé ó lu ọ̀gá reẹ̀ ní jìbìtì

Ohun elo iṣedajọ oolu ati iwe

Oríṣun àwòrán, other

Iya deacon, Olaide Olukanni ti yọju si ileẹjọ lori ẹsun pe o lu jibiti pẹlu orukọ ọga rẹ lati fi lu awọn ara ilu ni jibiti.

Olukanni wa lara awọn mẹfa ti wọn fi ẹsun kan pe o lu jibiti pẹlu ẹsun yiyi iwe ati pipa irọ gba owo, eleyii to le e da alaafia ilu ru.

Amọ, wọn ni wọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ninu ọrọ ti agbẹjọro Bisi Ogunleye sọ, iya deacon ati awọn to ku lo orukọ ọga rẹ Ẹsan lọna aitọ, lati fi ṣe ayẹwo ile fun ọpọlọpọ awọn eniyan laarin Oṣu Karun, ọdun 2019 si Oṣu Kọkanla, ọdun 2020.

Ogunleye ni iwa jibiti yii lu ofin ipinlẹ Eko, iyẹn section 411, 365 (1), 380 (11) 168 (1) 314 (1) ti ọdun 2015 to koju oro si iwa ọdanran.

Ninu idajọ rẹ, adajọ gba beeli iya deacon ati awọn afurasi bi tirẹ ni iye owo ẹgbẹrun lọna igba ati oniduro wọn.

Àkọlé fídíò, Iyalaje Oodua: Toyin Kolade ṣàlàyé ìdí tí Ooni Ogunwusi ṣe fi jẹ Ìyálájé Oodua

Bakan naa lo sun igbẹjọ di Ọjọ Kẹrin, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2021.