INEC on Anambra election: Wo ìdí tí àjọ INEC fi yọ orúkọ gómìnà báńkì àpapọ̀ tẹ́lẹ̀, Chukwuma Soludo kúrò nínú àwọn olùdíje gómìnà Anambra

Oríṣun àwòrán, Inec
Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti gbe ẹkunrẹrẹ orukọ awọn oludije fun idibo gomina nipinlẹ Anambra.
Ẹgbẹ Oṣelu mẹrindinlogoji ni ajọ INEC gbe oruks wọn sita pe wọn ṣetan fun eto idibo naa.
Amọṣa, ohun to ṣe ọpọ ni kayefi ninu iwe oruks ti ajọ naa gbe sita ni bi wọn ko ṣe fi orukọ oludije ẹgbẹ oṣelu PDP sinu iwe orukọ naa.
Ohun miran to mu ki awọn onwoye o gboju soke ni bi orukọ gomina banki apapọ orilẹede Naijiria nigbakan ri, Charles Chukwuma Soludo gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ oṣelu APGA.

Oríṣun àwòrán, InEC

Oríṣun àwòrán, Inec

Oríṣun àwòrán, Inec
Ajọ INEC ni idajọ ile ẹjọ lo mu ki awọn fi ọgbẹni Chukwuma Micheal Umeoji rọpo Soludo gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina ipinlẹ Anambra labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APGA.
Bakan naa lo kede pe idajọ ile ẹjọ lo jẹ ki wọn o gbe orukọ ẹgbẹ oṣelu PDP jade laisi oludije kankan.
Ni ọjọ kẹfa oṣu kọkanla ọdun 2021 ni eto idibo sipo gomina yoo waye ni ipinlẹ Anambra.








