Kaduna Protest: Ìwọde ìfẹ̀hónúhàn gbérasọ ní Southern Kaduna

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ló ti bẹ̀rẹ̀ iwaọ́de ìfẹ̀họ́núhàn ni ìlú kadun láti fi ẹdun ọkàn wọn hàn sí ìjọba lórí ìjínigbé àti ìpànìyàn tó n péléke níbẹ̀.
Àwọn ọda láti ìhà Gúúsù Kaduna ló bẹ́rẹ̀ ìwọ́de lówùrọ̀ òní ọjọ́ sátide nítori ọ̀rọ̀ ààbò tó n buru jáì sí lábẹ́ gómínà Nasir El-Rufai.
Gẹ́gẹ́ bi àwọn ọdá náà ṣe sọ, lásìkò tí wọ́n péjọ sí agbègbè Unity Fountain nílùú Abuja lábẹ́ ẹgbẹ́ Southern Kaduna People's Union ni wọ́n ti ké gbàjarè pé ìṣekúpani tó n wáyé ni ìhà Ariwa- Iwọ-oorun Nàìjíría ti pọ̀ jù.
- Ènìyàn 80 ló ti d'òkú nítori òjò àrọ̀rọdá tó fa omí yalé agbara ya sọọbù
- A ò jà lórí ẹni tí yóò rọ́pò TB Joshua, ìyàwó rẹ Evelyn ló ń darí ètò báyìí- Ìjọ́ Synagogue
- Wọ́n ti sìnkú Ọ̀gágun àgbà Huseini Ahmed tí agbébọn pa, bó ṣe lọ rèé
- Ìjọba Naijiria kéde ọjọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú tó n bọ̀ fún ìsinmi ọdún Ileya
Àwọn ọ̀dọ́ náà ké sí àwọn alábojútó ètò ààbò, àti àwọn ìjọba ni gbogbo ipele láti láti jí giìrì sí ojúṣe wọn.
Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dá náà tó bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ Jane Thomas-Rogers sọ pé ó pọndandan ki gómìnà ìpińlẹ̀ Kaduna dìde si ojúṣe rẹ̀ láti dá ààbò bo ẹmi àti òhun ìní àwọn ará ìlú.
Láti fi èrò ọkàn wọn hàn lórí ètò ààbò tó mẹ́hẹ ni ìpińlẹ̀ Kaduna, onírúúrú àwọn àkọlé ni wọ́n kọ sórí àwọn pálí tí wọ́n gbé lé ọwọ́.
Pẹ̀lú ómijé lójú ni Thomas-Rogers fi n sọ̀rọ̀ pé, bi wọ́n se ń fi ipábánilòpọ̀ àwọn ọmọ kéékèké lòpọ̀ bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe fún àwọn àgbàlagbà, bákan náà ni wọ́n ń pa ènìyàn lójoojúmọ́.
" Gómìnà el-Rufai, o ni láti dide sí ojúse rẹ̀ ki ó dáabòbo àwọn ẹmi àti ohun ìní."
"Ìgbà wo gan ni a fẹ́ ṣe èyí dà, sáájú àsìkò yìí, òpópónà Kaduna sí Abuja ni ìjínigbé tí n wáyé, sùgbọ́n ní báyìí, ó ti wọ inú Southern Kaduna wá."
"Àwọn eǹìyàn kò le dijú sùn, ẹrù ń bà wá, ẹrù láti lọ sí ìlú Kaduna ń bà wá, láìpẹ́ yìí, ni wọ́n jí ẹbi mi kan gbé, a ní láti san owó ìtúsílẹ̀ kí wọ́n to fi sílẹ̀.
Thomas ké pé àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ la'ti ill ọba láti dikde rànwọ́, bákan náà lo ke si ìjọba apapọ láti dide i[rànwọ́ ní Kaduna.
"A rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti sọ̀rọ̀ lòdì sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, bi ó till jọ́ pé Southern Kaduna lo ti n ṣẹlẹ̀ báyìí, ó le pada de ẹnu ọ̀nà ti yin náà."
















