TB Joshua: Ìjọ Synagogue ní kò sí awuyewuye lórí ẹni tí yóò rọ́pò TB Joshua

Oríṣun àwòrán, TB Joshua MInistries
Ijọ The Synagogue Church of All Nations, SCOAN ti ṣalaye pe iroyin ofege ni iroyin kan to jade ninu iwe iroyin pe awuyewuye n ṣẹlẹ lori ẹni ti yoo gba ipo olori ijọ naa lẹyin ti Wolii TB Joshua ti papoda tan.
Iwe iroyin kan lo kọkọ sọ pe awuyewuye lori ẹni ti yoo rọpo TB Joshua ti bẹ silẹ laarin iyawo oloogbe, Evelyn TB Joshua atawọn ọmọlẹyin wolii to doloogbe naa kan.
Ṣugbọn awọn alaṣẹ ijọ SCOAN sọ ninu atẹjade kan ti wọn sita pe awọn alaparutu kan lo n gbe ayederu iroyin kiri nipa ijọ naa.
- Ìwọ́de tí apá ọlọ́páà ò ní ká ń bọ̀ l'Eko tí wọn bá kọ̀ láti fi àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Mọ̀ si nípa agbẹjọ́rò Yoruba Nation tó gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ àgbáyé ICC
- Ìwọ́de tí apá ọlapáà ò ní ká ń bọ̀ l'Eko tí wọn bá kọ̀ láti fi àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ sílẹ̀ - Ilana Omo Oodua
- Ṣé ìwọ mọ ìtàn Ọdẹ tó tẹ Ẹ̀pẹ́ dó láti ìgbà ìwásẹ̀?
- 'Restructuring' la fi ta Buhari fún ìran Yorùbá, ṣùgbọ́n ó dùn mi pé irọ́ ni Buhari pa- Olagunsoye Oyinlola
- Títí di bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, èmi gan an kò mọ irú ẹni tí Wole Soyinka jẹ́- Ojọ̀gbọ́n Wole Soyinka
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ẹ̀sùn tí Igboho, Akintoye àti Ilana Omo Oodua gbé wa síwájú wa- ICC
Ijọ SCOAN ṣalaye ninu atẹjade ọhun pe ''aya oloogbe Evelyn ṣi n ṣọfọ lọwọ lẹyin ti ọkọ rẹ wọ kaa ilẹ sun tan lọjọ kẹsan oṣu keje ọdun 2021.
Gẹgẹ bi iyawo gidi ati abiamọ, o yẹ kawọn eeyan yẹ ẹ si nipa bibu ọlu fun un ki wọn si maa sọrọ rẹ lasiko yii to si n kẹdun ọkọ rẹ lọwọ.
Evelyn ko ba ẹnikan ja, niṣe lo gbajumọ bi yoo ṣe tẹsiwaju pẹlu iṣẹ ti ọkọ rẹ fi silẹ lọ.
Ọkan ṣoṣo ni gbogbo awọn ọmọ ijọ SCOAN, aya oloogbe Evelyn ko si ni gbolohun asọ pẹlu ẹnikan kan.
A fẹ fi asiko yii sọ fun gbọgbọ eeyan pe, to ba to asiko, a o kede olori tuntun ti yoo rọpo Wolii TB Joshua.
Ẹmi mimọ ni yoo ṣe atọna wa lori ati yan ẹni ti yoo rọpo TB Joshua.
Ṣugbọn lọwọ yii, arabinrin Evelyn lo si n dari gbogbo eto ijọ SCOAN.''












