Yoruba Nation: Àwọn olùwọ́de kìí ṣe ọ̀daràn nítori wọn kò ṣẹ̀ sí òfin - Ilana Omo Oodua

Yoruba Nation

Oríṣun àwòrán, Ìlànà Ọmọ Oòduà International

Ẹgbẹ to n ṣe onigbọnwọ iwọde Yoruba Nation kaakiri Naijiria, Ilana Omo Oodua ti sọ pe awọn yoo gunlẹ ifẹhonuhan ti yoo milẹ titi laipẹ ti ijọba ba kọ lati tu awọn eeyan ti awọn ọlọpaa fi ṣikun ofin mu niluu Eko lọjọ kẹta, oṣu yii silẹ.

Akukoro ẹgbẹ naa, George Akinola, lo sọ bẹẹ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Bo tilẹ jẹ pe ko sọ akoko ti iwọde naa yoo waye ni pato, ṣugbọn o ni ifẹhonuhan ọhun yoo waye laipẹ, ayafi ti wọn ba tu awọ eeyan naa silẹ.

Akinola sọ pe "Ti wọn ko ba fi awọn eeyan wa silẹ, iwọde ti ọwọ wọn ko ni ka ni a oo ṣe."

Ṣaaju ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti kọkọ fi ṣikun ofin mu awọn eeyan mọkandinlaadọta kan lọjọ kẹta, oṣu yii lagbegbe Abiola Garden to wa ni Ojota niluu Eko lasiko iwọde Yoruba Nation.

Yoruba Nation

Awọn ọlọpaa fẹsun kan awọn oluwọde naa pe wọn tapa si aṣẹ ileeṣẹ naa, eyii to dẹkun awọn eeyan ọhun lati ṣe iwọde naa ni pato.

Àkọlé fídíò, E jẹ́ ká lọ sí ìlú mi BBC yìí dá lórí Epe ní bi tí eégún ti ń fi ẹgba dá bírà lára Oba

Akinola sọ pe awọn agbẹjọro Ilana Omo Oodua ti n ṣiṣẹ takun-takun lati tu awọn eeyan naa silẹ.

O fi kun pe "Iwa ti awọn ọlọpaa wu yẹn ko ba ofin mu nitori ẹtọ araalu labẹ ofin ni lati ṣe iwọde tabi ifẹhonuhan."

O ni "Iwọde wọọrọwọ ni awọn eeyan wa n ṣe, wọn ko si ko ohun ija ogun wa sibi iwọde naa, ṣugbọn o jẹ ohun iyalẹnu fun wa pe wọn fi ṣikun ofin mu awọn eeyan wa."

Akinola ṣalaye siwaju si pe iwọde kii ṣe ẹṣẹ gẹghẹ bii alakalẹ ajọ iṣokan agbaye, UN, ati ti ilẹ Afrika, AU, eyii ti Naijiria buwọlu.

O pari ọrọ rẹ pe ki ijọba tu awọn eeyan wọn silẹ ni kankan bi bẹẹ kọ, ki wọn maa reti iwọde miran laipẹ.

Lara awọn ilu nla ti iwọde naa ti waye ṣaaju ji ilu Ibadan, Osogbo ati Akure lai si wahala kankan.

Àkọlé fídíò, Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe