Boko Haram: Ọdún 2017 ni ìjọba Naijiria bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ nǹkan bíi agbésùmọ̀mí 6,000

Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti tu ẹgbẹrun kan o le diẹ awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ Boko Haram silẹ lẹyin ti wọn sọ pe wọn ko ni nnkan ṣe pẹlu ẹgbẹ agbesumọmi naa.

Iroyin ni ibudo awọn ọmọ ogun kan to wa niluu Maiduguri ni wọn ko awọn eeyan naa pamọ si tẹlẹ ki wọn to fa wọn le ijọba Bornu lọwọ.

Gẹgẹ bii ohun ti a mọ, wọn yoo da awọn eeyan naa pada saarin ilu laipẹ lẹyin ti wọn ba ti ṣe idanilẹkọọ fun wọn tan.

Ninu atẹjada kan ti alukoro ileeṣẹ naa, Onyema Nwachukwu fi lede, o ni awọn afurasi naa ti iye wọn to 1,009 ti la awọn idanilẹkọọ kan kọja, awọn si ti fawọn le ijọba ipinlẹ naa lọwọ.

Ṣugbọn o fi kun pe awọn eeyan naa kii ṣe ara awọn ọmọ ogun Boko Haram.

Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹni to le sọ ni pato asiko ti awọn afurasi naa ti wa ni ahamọ awọn ọmọ ogun, ọdun 2017 ni ijọba apapọ bẹrẹ igbẹjọ nnkan bii ẹgbẹrun mẹfa eeyan ti wọn fura si pe wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ Boko Haram.

Àkọlé fídíò, E jẹ́ ká lọ sí ìlú mi BBC yìí dá lórí Epe ní bi tí eégún ti ń fi ẹgba dá bírà lára Oba

Lara wọn awọn eeyan naa si ti wa ni ahamọ fun ọpọlọpọ ọdun lai gbe wọn lọ sile ẹjọ.

Lootọ ni ijọba Naijiria ṣe ẹjọ awọn kan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram naa, ṣugbọn wọn tu awọn kan silẹ, ti wọn si da wọn pada saarin ilu lẹyin awọn idanilẹkọọ kan.

Ẹwẹ, ajọ iṣọkan agbaye, UN, ti sọ pe nnkan bii ẹgbẹrun un lọna ọọdunrun le aadọta eeyan lo ti dagbere faye lati igba ti wahala Boko Haram ti bẹrẹ ni Naijiria lati nnkan bii ọdun mẹwaa sẹyin.

Àkọlé fídíò, Silas Robotic Engineer: Kò sí ǹkan rere tí ọmọ Nàìjíríà kò lè ṣe