House plenary turns rowdy: Ìjókòó ilé aṣojúṣòfin tòní dàrú, ìjà bẹ́ sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, nigeria Senate
Ṣaadede ni ipade ti awọn aṣojuṣofin ile aṣofin Naijiria to waye lỌjọbọ tuka ti ija si bẹ silẹ laarin wọn gẹgẹ bi awn kan ṣe gba aba pe ki ẹrọ igbalode maa gbe esi idibo Naijiria jade ti awọn kan si ni laye, ko jọọ.
Eyi jẹ atunṣe ti wọn dabaa ki wọn ṣe si abala ikejilelaadọta ori kẹta iwe ofin Naijiria.
Atunṣe aba tuntun yii ni Sẹnetọ Sabi Abdullahi lati ipinlẹ Niger gbe silẹ ti Sẹnetọ Ali Ndume si kin in lẹyin lori r lo pese pe ki ajọ eleto idibo INEC gbe lilo imọ ẹrọ fun eto idibo Naijiria ki ajọ to n ri si eto ibanisọrọ naa si mojutoo niwọn igba ti ile aṣofin ba ti buwọ luu.
Ko tutu rara ti ẹni to mu aba fun atunṣe yii sọ ọ ni o t da aarin awọn aṣofin ru to si pin wọn niya ti gbogbo ẹ ariwo.
Aarẹ ile aṣofin gbiyanju titi ko ri alafia pe pada saarin awọn ọmọ ile eyi to si mu wọn ni dandan lati yọri ipade atilẹkun mọri ṣe.
Lẹyin ti wọn pari ipade idakọnkọ yii, oludari ẹgbẹ to kere julọ, Sẹnetọ Eyinaya Abaribe pe fun ipinya to si n pe Aarẹ wọn nija lori ọrọ naa.
O ni oun n fẹ ki awọn ọmọ Naijiria mọ taa ni ati kini wọn n dibo fun gan.
Abaribe ba ni ki wọn dibo. Ero gbogbo awọn asofin ba ṣe ọtọọtọ lori eyi. Igbakeji adari ile, Idris Wase duro lòdì sí kí wọn máa lo ẹrọ Igbalode fi gbe esi idibo jade.
Lẹyin ti wọn dibo ti onikaluku to si ibi to fẹ to si, aṣofin kan naa nile aṣojuṣofin tun yari ti ko sẹni to fẹrẹẹ rii ko ni ijanu afi igba ti adari ile aṣojuṣofin Femi Gbajabiamila paa laṣẹ ko pada sori ijoko rẹ to si ni ki wọn sun ijoko naa siwaju.
Pẹlu bi eeyan kan ṣe kin adari lẹyin lori eyi, wọn sun ijoko ile siwaju di ago mẹwa ọjọ Ẹti pẹlu ipe pe ki alaga ajọ INEC ati igbakeji ba wọn pe nibẹ.















