Ogun road accidents: Ìjàmbá ọkọ̀ ṣe gbẹ̀mí èèyàn 265 ní ìpínlẹ̀ Ogun

Oríṣun àwòrán, Facebook/FRSC Ogun
O kere tan, ọta le lugba le marun un 265 eeyan lo ti dero ọrun ninu ijamba ọkọ to waye laarin ọdun kan ati oṣu marun un ni ipinlẹ Ogun.
Esi iwadii ti ajọ ẹṣọ oju popo, Traffic Compliance and Enforcement Corps, TRACE ṣalaye pe eeyan 1,654 lo farapa ninu ijamba ọkọ 1,176 to ṣẹlẹ lati oṣu kinni ọdun 2020 si oṣu karun un ọdun 2021 nipinlẹ Ogun.
Iwadii naa fihan pe eeyan 176 lo gbẹmi mi ninu ijamba ọkọ laarin oṣu kinni si oṣu kejila ọdun 2020.
- Ọ̀pẹ́lọ̀pẹ́ Olorì Ladun aya Ooni Sijuwade ni mo fi gba òmìnira tí mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Olorun- Abobaku Ooni Sijuwade
- Àjọ̀dún odò Ẹ̀rìn, omi tí wọn kò gbọdọ̀ pa ẹja abàmì inú rẹ̀ wáyé nílùú Erinjiyan
- Ọmọ ìyá kan náà mẹ́ta kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ Àmàlà ní Ilorin
- Ẹ wo ibi ọ̀rọ̀ dé dúró lórí àwọn afurasí tó lọ́wọ́ nínú ikú Tolulope Arotile
- Buhari fẹ́ dá Naijiria padà sí ọdún 1984, ṣùgbọ́n a kò ní gbà fun- Femi Falana
- Fatomilola kò ní kí ẹ lọ gbé igba Yahoo, ẹ lọ tẹra mọ́ iṣẹ́ ọwọ́ yin ni- Oladosu Fatomilola
Eeyan mọkandinlaadọrun lo padanu ẹmi wọn nigba ti ọta le lẹgbẹta le mẹrin farapa ninu ijamba ọkọ laarin oṣu kinni si oṣu karun un ọdun 2021.
171 ọkọ ayọkẹlẹ, 153 bọọsi aladani nigba ti 168 bọọsi ero, 189 ọkọ ero, 101 alupupu, kẹkẹ ẹlẹsẹ mẹta 52, 1555 ọkọ nla ati 169 tirela ni ijamba ọkọ ṣẹlẹ si.
Agbẹnusọ fun ajọ TRACE, Babatunde Akinbiyi ṣalaye pe eeyan 3,021 lo ni ipin ninu awọn ijamba ọkọ ọhun.
Ninu ọdun 2021, ọkunrin mọkadinlọgọrin ati obinrin mẹwaa lo ku laarin oṣu marun un nigba ti ọkunrin 473 ati 191 obinrin lo farapa ninu ijamba ọkọ.
Ọkọ 285 ati 57 alupupu ni ijamba ṣẹlẹ si, ati pe laarin oṣu kinni si ekeji ni awọn eeyan ti ku julọ nigba ti awọn to farapa pọ lati oṣu keji si oṣu karun un.
Ajọ TRACE ati FRSC ni ere asaju lo ṣe okunfa ọpọlọpọ awọn ijamba ọkọ naa.
Wọn iwa kuwa, taya ti ko dara, awọn to n gba ''one way'' ati oju popo to ti bajẹ naa n ṣokunfa ọpọ ijamba ọkọ.
Ẹwẹ, ijọba ti ṣe agbekalẹ eto lati din ijamba ọkọ to n ṣẹlẹ ku loju popo.
Lara awọn ọna ti ijọba fẹ fi ṣe adinku ijamba oju popo ni bi wọn ṣe fi ofin de ọti tita fawọn awakọ.












