Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó yẹ lórí ọ̀dọ́ ni- Oladosu Fatomilola

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola kìí ṣe agbódegbà Yahoo, Ó ń fẹ́ kí ìjọba, Òbí àti ilé ìjọsìn ṣe ohun tó y

Nitori pe ijọba ati Obi ti kuna lori iṣẹ rẹ lori ọdọ ni wọn ṣe n ronu lọ si idi ṣiṣe Yahoo- Oladosu Fatomilola.

Oladosu Fatomilola Ọmọ gbajugbaja oṣere ni, Peter Fatomilola ti ṣalaye siwaju sii lori ọrọ baba rẹ pé Mo fẹ́ kí a dá Yorùbá Nations sílẹ̀ kí a lè máa mójútó àwọn adarí tó bá kọsẹ́ fúnra wa- Peter Fatomilola.

O ni awujọ wa ti kuna, ijọba ti kuna, Obbi ti kuna, ile ijọsin ti kuna, koda, alagbatọ ti kuna lati tọ awọn ewe ati ọdọ wa bi o ti yẹ.

Oladosu Fatomilola ṣalaye pe bi awa kan se fara mọ ọrọ naa ni awọn mii ni o dara ki awọn ọm Yoruba maa gba owo ti iran oyinbo jẹ babanla Yoruba.

O mẹnuba bi ijọba se kuna ni eyi ti o fi di isoro airi iṣẹ ṣe fun awọn ọdọ.

Oladosu gba awọn ọdọ ilẹ Yoruba niyanju lati tubọ tẹpa mọ iṣẹ ọwọ wọn nitori pe atẹlẹ ẹni kii tan ẹni jẹ ati pe ọjọ ti a ba gun kọ ni a n kan ọrun.

Bakan naa lo gba awọn Obi ati Alagbatọ lati tọ awọn ọdọ iwoyi sii nipa iwa ọmọluwabi eyi ti ṣiṣe gbajuẹ ati Yahooyahoo ko si nibẹ rara.