Yoruba Nation agitation: Sunday Igboho, Akintoye àtàwọn míràn fa Buhari, Malami àtàwọn míì lọ síwájú ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC

Oríṣun àwòrán, other
Adari ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua Ọjọgbọn Banji Akintoye, aṣiwaju ipe fun idasilẹ orilẹede Yoruba ti pe Buhari lẹjọ.
Akintoye, Sunday Igboho atawọn ẹgbẹ ajijagbara ilẹ Yoruba mọkandinlaadọta ti fọwọsi iwe ẹhonu oloju ewe mẹtadinlọgbọn kan ti wọn gbe tọ ile ẹjọ agbaye, ICC lọ.
Gẹgẹ bi ohun ti iwe iroyin ojoojumọ ilẹ wa ni awọn ri gba gẹgẹ bi iroyin, Amofin Aderẹmi Ọmọjọla lo fi iwe ẹhonu naa ranṣẹ lorukọ wọn.
Ninu iwe ẹhonu naa, wọn fi ẹsun pipa awọn ọmọ Yoruba ni ipinlẹ Ekiti, Ọṣun, Ondo, Ogun, ati ilẹ Okun ni ipinlẹ Kogi ati Kwara kan awọn adari Naijiria kan.
- A ti gba ẹ̀sùn tí ẹ fi kan Buhari, Malami, Buratai wọlé - Kóótù `ọdaràn l'ágbáyè, ICC
- Wọ́n ní Ìyá Esabod yẹn ma ń ṣépè, fi òṣèré wọ́lẹ̀, mò ń retí èsì yín sí ọ̀rọ̀ tí mo fi síta yìí - Mr Portable
- Oríire ńlá ló jẹ́ fún àwọn ọmọ Naijiria pé orílẹ̀-èdè yìí ṣì wà ní ọ̀kan ṣoṣo- Buhari
- Mo gbọ́ pé babaláwo mẹ́ta ló tẹ̀lé àwọn DSS lọ sí ilé Sunday Igboho- Gani Adams
- Aya Aarẹ Ghana ati aya ìgbákejì Aarẹ Ghana ti dá gbogbo owó oṣù tí wọ́n gbà láti 2017 padà sápò ìjọba
- Gbẹgẹdẹ gbiná, ṣọ́jà àtàwọn jàǹdùkú fìjà pẹẹ́ta lọ́jà Ladipo l'Eko
- Àfinra! Ẹ wá máa lọ ilé ẹ̀yin akẹ́kọ̀ọ́ títí di ọjọ́ wájú, a ti ti ìbugbé ilé ẹkọ́ pa torí Covid-19 - Fásitì Unilag
Lara awọn ti wọn pe lẹjọ ni Aarẹ Muhammadu Buhari, minisita feto idajọ Abubakar Malami, olori ileeṣẹ ọmọ ogun oriilẹ tẹlẹ, Tukur Buratai atamọ ọga agba ọlọpaa tẹlẹ bii Ibrahim idris ati Muhammed Adamu.
Awon miran ni: Olori ileeṣẹ aṣọbode Hammid Alli, Ọga ọlọpaa Alkali Baba, olori ileeṣẹ ọmọogun ilẹ Farouk Yahaya, olori ileeṣẹ ọmọogun ofurufu tẹlẹ, Sadiq Abubakar,

Oríṣun àwòrán, others
Awon mii ni: olori ajọ sifu difẹnsi tẹlẹ Ahmed Audi, ọgaagba ileeṣẹ wọle wọde Naijiria, Mohammed Babandede pẹlu olori ajọ sifu difẹnsi bayii, Abdullahi gana Muhammadu.
Iwe ẹhonu naa fi ẹsun kan awọn eeyan naa pe wọn lọwọ si pipa awọn ọmọ ẹgbẹ ajijagbara to pẹjọ naa, wọn si ṣe wọn leṣe.
Nibayii ileẹjọ agbaye ICC ni awọn ti tẹwọ gba iwe ẹhonu naa.
- Ààrẹ Buhari ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn sẹ́nétọ̀ 109 lálẹ́ ọjọ́ Iṣẹ́gun
- Èèyàn 2,371 ni wọ́n jí gbé, N10biliọnu owó ìtúsílẹ̀ làwọn ajínigbé gbà lóṣù mẹ́fà àkọ́kọ́ ọdún 2021
- Aya Aarẹ Ghana ati aya ìgbákejì Aarẹ Ghana ti dá gbogbo owó oṣù tí wọ́n gbà láti 2017 padà sápò ìjọba
- Gbàgbé ẹ! Ìjọba kò lè yọwọ nínú fifi ọba jẹ láéláé- Oba Tejuosho
- Ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n bá lórí kerewà bọ́ sọ́wọ́ Ọlọ́pàá ẹ̀sìn Islam
- Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f'ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá



















