Super TV CEO Ataga: Chidinma ò gbudọ̀ kú o sátìmọ́lé Ọlọ́pàá o! Àwọn aṣòfin f'ọ̀rọ̀ ráńṣẹ́ sí Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Usifo Ataga
Ile igbimọ aṣojuṣofin ti fi ọrọ sita pe afurasi ti wọn ni o pa oludari ileeṣẹ Tẹlifisan Super TV, Usifo Ataga ko gbudọ ku si atimọle awọn ọlọpaa Naijiria.
Bakan naa, ile aṣojuṣofin tun ni ki wọn ṣe iwadii ati ayẹwo finifini lori ẹsun naa ki wọn si ma ṣafihan arabinrin Chidinma kiri mọ tabi ki wọn maa gbaa laye lati ba awọn oniroyin sọrọ lori ọrọ ti wọn ṣi n ṣewadii rẹ lọwọ.
Ile aṣofin ni ki Ọga agba awọn ọlọpaa, Usman Baba "pe gbogbo awọn ọlọpaa ko ki wọn nilọ pe ko si atunṣe iru iwa ipa yii lori ẹtọ ọmọniyan ati gbigba awọn ti wọn ba fi panpẹ ofin mu laaye lati ba awọn oniroyin sọrọ.
Wọn n sọ eyi gẹgẹ bi ọkan lara awọn afẹnuko wọn nibi ijoko ile to waye lọjọ Iṣegun lẹyin ti wọn jọ pa ohun pọ lori ọrọ ti wọn lo gba amojuto kiakia ti aṣoju Tolu Akande-Sadipe mu aba rẹ wa to pe akori rẹ ni "Bi Ọlọpaa ṣe n tẹle ofin ijọba apapọ ati iwadi kikun lori iku oloogbe Ọ̀gbẹ́ni Usifo Ataga.
- Ọkùnrin márùn-ún tí wọ́n bá lórí kerewà bọ́ sọ́wọ́ Ọlọ́pàá ẹ̀sìn Islam
- Hàà! Akẹ́kọ̀ọ́ UNILAG ẹni ọdún 21 kà bòrò-bòrò pé: Èmi ló pa olówó, ọ̀gá Super TV, Usifo Ataga
- A ti gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè agbẹjọ́rò tó dántọ́ kí Kanu lè rí ìdájọ́ òdodo gbà - Ohaneze Ndigbo
- Ìròyìn òfegè ni pé Alabi Yellow jáde láyé lánàá
- Àrá kọ ṣàràà! Ó sán pa èèyan 16 tó ń ya "Selfie" lórí ilé gogoro
- 'Surprise Cake' tí mo gbà lọ́jọ́ ìbí mi ní kò jẹ́ kí ń pa ara mi- Deborah Oyesanya
- Mo gbọ́ pé babaláwo mẹ́ta ló tẹ̀lé àwọn DSS lọ sí ilé Sunday Igboho- Gani Adams
Gẹgẹ bi awọn aṣofin ṣe sọọ, eyi jẹ lati rii daju pe wọn ṣiṣẹ lori awọn ẹsun mii lọjọ iwaju bi eleyii.
Lafikun, ile aṣojuṣofin ni ọga agba ọlọpaa gbudọ rii daju pe arabinrin Ojukwu ti wọn fẹsun kan ko ku si ahamọ tabi pa ara rẹ nigba to n duro de idajọ rẹ gẹgẹ bo ṣe ti ṣẹlẹ sẹyin lori awọn ẹsun kan to ti kọja.
Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹfa ọdun 2021 ni ileeṣẹ ọlọpaa Eko ṣafihan oju Chidinma nigba to jẹwọ pe oun lo n gun Ataga ẹni aadọta ọdun naa lọbẹ lọrun pa lẹyin gbọnmi sii omi o to.
Chidinma tun tun eyi sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ba awọn oniroyin kan sọ.
Ẹwẹ, ninu fidio kan to wa gba ori ayelujara kan lọjọ Aje ni arabinrin Chidinma Ojukwu ti bẹrẹ si ni sọ pe oun kọ loun pa ọga ileeṣẹ Super TV.
Nigba to da aba lọjọ Iṣegun, Aṣofin Akande-Sadipe muu wa si iranti ile pe lati igba ti ọlọpaa ti mu arabinrin Chidinma ni wọn ti n ṣafihan oju rẹ kiri ti wọn si n jẹ ko ba awọn oniroyin sọrọ lori ọrọ to wa di ohun ti wọn n gba bi ẹni n gba igba ọti lori ayelujara bayii ti awn oniroyin wa brẹ si ni pin ọrọ naa yẹlẹ yẹlẹ.
Gbogbo eleyi naa n ṣẹlẹ pẹlu pẹlu pe ọlọpaa ṣi n ṣe iwadii lọwọ.
"Ile aṣofin mọ wi pe ofin orilẹede Naijiria ko faaye gba ki ori ayelujara maa sọrọ nipa ẹsun kan nigba ti ile ẹjọ ko ba tii ṣe ipinu rẹ - ko yẹ ki awọn oniroyin maa sọrọ nipa rẹ".
O fi kun un wipe ni abala ikẹrindinlogoji ka ikarun ti iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 ti wọn ti tun ṣe fihan pe gbogbo ẹnikẹni ti ofin ba ti gbe ni wn yoo maa pe ni ko mọwọ ko mẹsẹ titi ti ile ẹjọ yoo fi sọ pe o jẹbi ẹ́un ọhun.
Tori naa wọn ni arabinrin Ojukwu ko tii jẹbi ẹsun to n jẹjọ rẹ lọwọ ko yẹ ki wọn maa foju ọdaran wo o tabi ṣafihan rẹ kiri titi di igba ti iwadii yoo gunrege tori naa ki wọn gba ileeṣẹ laye lati ṣe iṣ wọn.













